JW LIBRARY
Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library—Lórí iOS
Káàbọ̀ sórí JW Library. A ṣe ètò ìṣiṣẹ́ yìí láti máa fi ka Bíbélì, ká sì máa fi kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Tó o bá fẹ́ rí àwọn ohun pàtàkì tó wà lórí rẹ̀, tẹ àwọn bọ́tìnì tó wà nísàlẹ̀ abala ìbẹ̀rẹ̀.
Bible
Apá tá a pè ní Bible máa jẹ́ kó o lè ka Bíbélì, kó o sì wa àwọn ìtumọ̀ Bíbélì jáde. Tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, tẹ ìwé Bíbélì kan, kó o wá tẹ orí tó o fẹ́ kà. Bó o ṣe ń kà á, wàá tún máa rí àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, atọ́ka àtàwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì ní abala Ìkẹ́kọ̀ọ́ lápá ọ̀tún.
Tó o bá fẹ́ wo ẹsẹ Bíbélì míì, pa dà sí Bible kó o lè pa dà rí ibi tá a to àwọn ìwé Bíbélì sí.
Publications
Apá tá a pè ní Publications máa jẹ́ kó o rí àwọn ìwé, àtẹ́tísí àti fídíò. Tó o bá fẹ́ kàwé, tẹ ìwé kan, kó o sì tẹ àpilẹ̀kọ kan níbẹ̀. Bó o ṣe ń kàwé, o tún lè máa wo àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. Tó o bá tẹ ẹsẹ Bíbélì tó o fẹ́ kà, wàá rí i ní abala Ìkẹ́kọ̀ọ́. Tẹ ìlujá ẹsẹ Bíbélì kan ní abala Ìkẹ́kọ̀ọ́, ó máa gbé ẹ lọ sínú Bíbélì gangan.
Tó o bá fẹ́ ṣí ìtẹ̀jáde míì, tẹ Publications kó o lè pa dà sí ibi táwọn ìtẹ̀jáde wà.
Daily Text
Tẹ apá tá a pè ní Daily Text kó o lè rí ẹsẹ ojúmọ́ tòní.
Meetings
Tẹ apá tá a pè ní Meetings kó o lè rí ìwé tá a máa lò nípàdé ọ̀sẹ̀ yẹn.
Online
Tẹ apá tá a pè ní Online kó o lè rí ìlujá tó máa gbé ẹ lọ sórí àwọn ìkànnì wa.
Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé
Máa rí i pé ètò ìṣiṣẹ́ iOS tó dé kẹ́yìn ló wà lórí fóònù ẹ kó o lè máa rí ohun tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sórí JW Library.
Ó dáa kó jẹ́ pé ètò ìṣiṣẹ́ iOS tó dé kẹ́yìn lò ń lò lórí fóònù ẹ. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, tẹ ìlujá yìí: https://support.apple.com/en-us/HT204204.
Kó lè rọrùn fún ẹ, o lè ṣeé kí fóònù ẹ máa wa ètò ìṣiṣẹ́ tó dé kẹ́yìn jáde fúnra ẹ. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, tẹ ìlujá yìí: https://support.apple.com/en-us/HT202180.