JW LIBRARY
Ohun Tó Wà Lórí JW Library
Lílo Bíbélì
Yan ọ̀kan nínú oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì tó wà níbẹ̀.
Tó o bá tẹ nọ́ńbà tó wà níwájú ẹsẹ Bíbélì kan, wàá lè fi gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì tó wà wéra.
Tó o bá tẹ àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tàbí atọ́ka tó wà lórí ẹsẹ Bíbélì kan, wàá rí àwọn ìsọfúnni tó bá a rìn.
Bí Wàá Ṣe Máa Lò Ó
Tó o bá ṣí ìwé kan, fi ìka fa ojú fóònù ẹ sápá ọ̀tún tàbí sápá òsì bí ẹni ṣí ìwé, kó o lè rí ojú ìwé tó kàn tàbí èyí tó ṣáájú.
Sàmì sí ẹsẹ Bíbélì tàbí orí Bíbélì tó o bá ń kà lọ́wọ́, kó o lè pa dà bẹ̀rẹ̀ níbi tó o dé.
Lọ sí apá tá a pè ní history kó o lè rí àwọn ìwé tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán.
Fi apá tá a pè ní Search wá ọ̀rọ̀ nínú ìwé tó ò ń kà lọ́wọ́.
Wo àwọn ìwé tí wàá lò nípàdé.