JW LIBRARY
Bó O Ṣe Lè Wa Bíbélì Jáde Kó O sì Máa Lò Ó—Windows
Ọ̀kan lára ohun pàtàkì tó o lè ṣe lórí JW Library ni kó o ka Bíbélì, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.
Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè wa Bíbélì jáde, kó o sì máa lò ó:
Wa Bíbélì Jáde
O lè wa oríṣiríṣi Bíbélì jáde kó o lè máa kà á, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.
Nínú àpótí tó wà lókè lójú fóònù ẹ, tẹ apá tá a pè ní Bible, kó o wá tẹ Books kó o lè rí àwọn ìwé inú Bíbélì.
Ṣí àpótí App Commands bar, kó o wá tẹ Languages kó o lè rí gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì tó wà. Àwọn Bíbélì tó wà ní èdè tó ò ń lò jù ló sábà máa ń wà lókè pátápátá. O tún lè wá Bíbélì míì jáde tó o bá fi orúkọ èdè tàbí orúkọ Bíbélì náà wá a. Bí àpẹẹrẹ, o lè tẹ “int” tó o bá fẹ́ wá Bíbélì Kingdom Interlinear lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí kó o tẹ “port” kó o lè rí gbogbo Bíbélì tó wà lẹ́dè Portuguese.
Wàá rí àmì òfúrufú lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Bíbélì tó ò tíì wà jáde. Tó o bá tẹ irú Bíbélì bẹ́ẹ̀, o máa lè wà á jáde. Tó o bá ti wa Bíbélì kan jáde sórí fóònù ẹ, o ò ní rí àmì òfúrufú yẹn mọ́. Tún tẹ Bíbélì náà kó o lè kà á.
Tó ò bá rí ìtumọ̀ Bíbélì tó o fẹ́, jọ̀ọ́ pa dà wá wò ó tó bá yá. Tí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tuntun bá ti wà, a máa gbé e síbẹ̀.
Yọ Bíbélì Kúrò
O lè yọ ìtumọ̀ Bíbélì kan kúrò tó ò bá fẹ́ mọ́ tàbí tí fóònù ẹ bá ti kún, tó o sì fẹ́ kí àyè wà lórí ẹ̀.
Nínú àpótí tó wà lókè lójú fóònù ẹ, tẹ Bible, kó o wá tẹ Languages kó o lè rí ibi táwọn Bíbélì wà. Wá tẹ bọ́tìnì More tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bíbélì tó o fẹ́ yọ kúrò, kó o wá tẹ Delete.
Wa Bíbélì Tá A Ṣàtúnṣe sí Jáde
Látìgbà dégbà, a lè máa ṣe àwọn àtúnṣe kan lórí àwọn Bíbélì tó o ti wà jáde tẹ́lẹ̀.
Tí àtúnṣe bá ti wà lórí Bíbélì kan, wàá rí àmì róbóróbó kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tó o bá ti tẹ Bíbélì yẹn, o máa rí ìsọfúnni pé àtúnṣe ti wà. Kó o wá tẹ Download kó o lè tún un wà jáde, tàbí kó o tẹ Later kó o lè máa ka èyí tó o ti ní lọ́wọ́ lọ.
March 2015 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.4 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí Windows 8.1 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library—Lórí Windows,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.