TẸLIFÍṢỌ̀N JW
Tẹ́tí sí Ohùn Tá A Gbà Sílẹ̀ Lórí Roku
Ní apá Audio wàá rí oríṣiríṣi àtẹ́tísí, bí orin, àwòkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà bí ẹni ń ṣeré ìtàn.
(Àkíyèsí: Rìmóòtù Roku tìẹ lè yàtọ̀ sí tinú àwòrán tó wà ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí.)
Yan Audio níbi ìbẹ̀rẹ̀ kó o lè rí gbogbo àtẹ́tísí tó wà. Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o lè wá àwọn àtẹ́tísí, kó o sì gbọ́ wọn:
Tẹ́tí sí Ohùn Tá A Gbà Sílẹ̀
Ní ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan, wàá rí àwọn àtẹ́tísí tá a kó jọ sábẹ́ ìsọ̀rí kan. O máa rí orúkọ ìsọ̀rí náà lọ́wọ́ òkè.
Up àti Down: Lọ sí ìsọ̀rí tó wù ẹ́.
Left àti Right: Lọ sí àtẹ́tísí tó wù ẹ́ lábẹ́ ìsọ̀rí kan.
Tẹ OK kó o lè yan àtẹ́tísí tó o fẹ́, kó o sì tẹ Audio Program Details.
Yan ọ̀kan nínú àwọn àbá yìí:
Pa Dà Bẹ̀rẹ̀: Ìgbà tó o máa rí eléyìí ni tó o bá ti ń gbọ́ àtẹ́tísí kan lọ tẹ́lẹ̀ àmọ́ tó o wá dá a dúró. Tó o bá tẹ̀ ẹ́, ó máa pa dà bẹ̀rẹ̀ àtẹ́tísí náà níbi tó o gbọ́ ọ dé.
Gbádùn Ẹ̀ tàbí Gbádùn Ẹ̀ Látìbẹ̀rẹ̀: Àtẹ́tísí náà máa bẹ̀rẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀.
Gbádùn Gbogbo Ẹ̀: Wàá lè gbọ́ gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn, bẹ̀rẹ̀ látorí ètò tó wà lójú tẹlifíṣọ̀n lọ́wọ́lọ́wọ́. Tó o bá ti gbádùn gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn tán, ó máa dáwọ́ dúró.
Ọ̀wọ́ àwọn àtẹ́tísí tó wà nísàlẹ̀ Audio Program Details ni àwọn àtẹ́tísí míì tó wà ní ìsọ̀rí yẹn. Tẹ Down kó o lè lọ síbẹ̀, tẹ Up kó o lè pa dà síbi Audio Program Details.
Tẹ́tí sí Àwọn Èyí Tó Wà Lábẹ́ Ìsọ̀rí Kan
Yàtọ̀ sí pé kó o gbọ́ àwọn àtẹ́tísí níkọ̀ọ̀kan, o tún lè tẹ́tí sí gbogbo èyí tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kan. Lọ síbi ìsọ̀rí tó o fẹ́ tẹ́tí sí, kó o wá yan ọ̀kan nínú àwọn àbá yìí:
Gbádùn Gbogbo Ẹ̀: Wàá lè gbọ́ gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn, bẹ̀rẹ̀ látorí àkọ́kọ́.
Lọ́kan-ò-jọ̀kan: Wàá lè gbọ́ gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn láìtò ó tẹ̀ léra bó ṣe wà lójú tẹlifíṣọ̀n.
Tó o bá ti gbádùn gbogbo àtẹ́tísí tó wà ní ìsọ̀rí yẹn tán, ó máa dáwọ́ dúró.
Ṣe Àtẹ́tísí Bó O Ṣe Fẹ́
Tí àtẹ́tísí bá ń lọ lọ́wọ́, o lè fi rìmóòtù ṣe é bó o ṣe fẹ́:
Gbádùn Ẹ̀/Dúró Ná tàbí OK: Wàá lè dá àtẹ́tísí dúró. Tó o bá tún tẹ bọ́tìnì yẹn kan náà, ó máa bẹ̀rẹ̀ pa dà.
Èyí Tó Kàn: Ó máa sún àtẹ́tísí náà síwájú díẹ̀. Àmọ́ tó o bá tẹ bọ́tìnì yẹn mọ́lẹ̀, ó máa sáré sún un síwájú dáadáa. Gbọ́wọ́ kúrò lórí bọ́tìnì náà kí àtẹ́tísí lè pa dà bẹ̀rẹ̀.
Èyí Tó Ṣáájú: Ó máa sún àtẹ́tísí náà sẹ́yìn díẹ̀. Àmọ́ tó o bá tẹ bọ́tìnì yẹn mọ́lẹ̀, ó máa sáré sún un sẹ́yìn dáadáa. Gbọ́wọ́ kúrò lórí bọ́tìnì náà kí àtẹ́tísí lè pa dà bẹ̀rẹ̀.
Back: Ó máa pa dà sí abala Àtẹ́tísí.