TẸLIFÍṢỌ̀N JW
Fi Ètò Ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW Sórí Roku
Kó o tó lè wo Tẹlifíṣọ̀n JW lórí Roku, àfi kó o kọ́kọ́ ṣètò ẹ̀, kó o sì fi ètò ìṣiṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n JW sórí ẹ̀rọ Roku rẹ. Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè bẹ̀rẹ̀:
Ṣèto Ẹ̀rọ Roku Rẹ
Ìtọ́ni máa bá ẹ̀rọ Roku rẹ wá kó o lè ṣètò ẹ̀, kó o sì lè lò ó lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Tí ẹ̀rọ Roku rẹ bá ti wọ orí íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹ̀ lé ìtọní tó bá gbé wá sójú tẹlifíṣọ̀n ẹ kó o lè parí iṣẹ́ lórí ẹ̀.
Àkíyèsí: Àfi kó o lo íńtánẹ́ẹ̀tì látorí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù kan kó o tó lè parí iṣẹ́ lórí ẹ̀rọ Roku rẹ.
Tó o bá ń ṣe é lọ, ó máa ní kó o fi ẹ̀rọ Roku ẹ sí i. Kó o lè ṣe é, lọ sí www.roku.com/link kó o sì tẹ nóńbà tó hàn lójú tẹlifíṣọ̀n rẹ. Kó o wá tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà lójú kọ̀ǹpútà tàbí fóònù ẹ kó o lè ṣí àkáǹtì sórí Roku.
Tí ẹ̀rọ Roku ẹ bá ti rí àkáǹtì tó o ṣí, ó máa gbé ohun tó wà lójú tẹlifíṣọ̀n kúrò.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè ṣètò ẹ̀rọ Roku rẹ, wo Support section lórí ìkànnì Roku.
Fi Tẹlifíṣọ̀n JW sí I Látorí Kọ̀ǹpútà
Ẹ̀rọ Roku ní ètò ìṣiṣẹ́ téèyàn lè fi máa wo fídíò. Wàá ní láti fi àwọn fídíò tó o fẹ́ sórí ẹ̀. Ọ̀nà kan tó o lè gbà fi ètò tuntun sórí ẹ̀ ni látorí kọ̀ǹpútà ẹ.
Látorí browser èyíkéyìí, lọ sí abala Tẹlifíṣọ̀n JW nínú Roku Channel Store.
Wọlé sórí àkáǹtì Roku rẹ tó bá jẹ́ pé o ò tíì wọlé tẹ́lẹ̀.
Tẹ Add Channel. Tó bá ti fi ètò tó o yàn kún un, bọ́tìnì Add Channel tó kùn ní àwọ̀ ewé máa yí pa dà di ọ̀rọ̀ náà Installed.
Tó o bá fi ètò kan sórí ẹ̀rọ Roku rẹ látorí browser, kò ní gbé ètò yẹn sórí ẹ̀rọ Roku rẹ. Àfi kó o gbé e sórí ẹ̀rọ Roku fúnra ẹ.
Tẹ bọ́tìnì Home lórí rìmóòtù Roku rẹ.
Tẹ Up tàbí Down kó o lè dé Settings.
Wá tẹ OK.
Ní abala Settings, lọ sórí System Update kó o wá tẹ OK. Abala System Update á wá máa yí bírí. Ó yẹ kó kun Check Now ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún tẹlifíṣọ̀n rẹ.
Tẹ OK.
Lẹ́yìn náà, ẹ̀rọ Roku máa wá ètò tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ fi sórí ẹ̀, á sì gbé e sí i.
Pa dà sí ìbẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀rọ Roku kó o wá yan My Channels níbi ìbẹ̀rẹ̀. Wàá rí gbogbo ètò tẹlifíṣọ̀n tó o ti gbé sórí ẹ̀rọ Roku rẹ, tó fi mọ́ Tẹlifíṣọ̀n JW.
Lọ síbi àmì jw.org kó o sì tẹ OK kó o lè bẹ̀rẹ̀ sí í wo Tẹlifíṣọ̀n JW.
Fi Tẹlifíṣọ̀n JW sí I Látorí Roku
O tún lè fi Tẹlifíṣọ̀n JW sórí ẹ̀rọ Roku rẹ ní tààràtà.
Lọ sí ìbẹ̀rẹ̀ Roku.
Tẹ Up tàbí Down lórí rìmóòtù Roku rẹ, kó o wá lọ sí Search.
Tẹ OK.
Àpótí Search tó wà lórí Roku máa ń rí àwọn fíìmù, ètò tẹlifíṣọ̀n, àwọn òṣèré, olùdarí fíìmù, àwọn géèmù àtàwọn ètò tó bá ohun tó o tẹ̀ mu. Ètò tẹlifíṣọ̀n kan ni Tẹlifíṣọ̀n JW, tó o bá ti tẹ̀ ẹ́ sínú àpótí náà, tẹ àmì Channel tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ. Tẹ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí kó o lè rí Tẹlifíṣọ̀n JW:
jw broadcasting
jw.org
jwtv
Jehovah
Tó bá ti gbé JW Broadcasting wá, tẹ àmì > kó lè gbé e síbẹ̀, kó o wá tẹ OK. Ó yẹ kó ti kun bọ́tìnì Add channel báyìí.
Tún tẹ OK kó o lè gbé Tẹlifíṣọ̀n JW sórí ẹ̀.
Tó o bá fẹ́ wo Tẹlifíṣọ̀n JW, tẹ Go to channel, tàbí kó o pa dà sí ìbèrẹ̀ Roku, wàá rí JW Broadcasting lábẹ́ My Channels.