AUGUST 20, 2019
PARAGUAY
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Lédè Guarani
Ní August 16 2019, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Guarani níbi àpéjọ agbègbè tí wọ́n ta àtagbà rẹ̀ látinú gbọ̀ngàn Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Capiatá, lórílẹ̀-èdè Paraguay. Arákùnrin Daniel González, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Paraguay ló mú Bíbélì yìí jáde lọ́jọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ agbègbè náà. Wọ́n sì wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bó ṣe ń lọ lọ́wọ́ láwọn ibi mẹ́tàlá (13) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ míì, àròpọ̀ gbogbo àwọn péjọ nígbà tá a mú Bíbélì náà jáde sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n (5,631).
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èdè Sípáníìṣì làwọn èèyàn ń sọ lórílẹ̀-èdè Paraguay, àmọ́ ó kéré tán, èèyàn mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá ló ń sọ èdè Guarani tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ ibẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ní gbogbo Latin America, orílẹ̀-èdè Paraguay nìkan ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń sọ èdè ìbílẹ̀ kan náà.
Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè tó ṣiṣẹ́ lórí ìtúmọ̀ Bíbélì yìí sọ pé kí wọ́n tó mú Bíbélì yìí jáde, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló jẹ́ pé èdè Guarani tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ wọn ni wọ́n fi máa ń gbàdúrà sí Jèhófà.. Ó sọ pé: “Ní báyìí, Jèhófà náà á máa bá wa sọ̀rọ̀ lédè Guarani. A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì mọyì wa. Ó ti túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà ni Bàbá mi.”
Ó dá wa lójú pé Bíbélì èdè Guarani yìí máa ṣèrànwọ́ fún àwọn akéde ẹgbẹ̀rún mẹ́rin, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (4,934) tó ń sọ èdè Guarani lórílẹ̀-èdè Paraguay, ó sì máa jẹ́ kí ìfẹ́ àti ìmọrírì tí wọ́n ní fún Jèhófà àti ètò rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i. Ó dá wa lójú pé Bíbélì yìí máa jẹ́ káwọn tó ń kà á mọ òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa.—Sáàmù 139:17.