JUNE 11, 2019
RỌ́ṢÍÀ
Àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ tí Dennis Christensen Sọ Níwájú Ilé Ẹjọ́ ní May 16
Nígbà tí ilé ẹjọ́ ń gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Dennis pè ní Thursday, May 16, 2019, ó tó wákàtí kan tí Dennis fi gbèjà ara rẹ̀. Gbankọgbì ọ̀rọ̀ tó sọ níwájú ilé ẹjọ́ (tá a túmọ̀ láti èdè Rọ́ṣíà) rèé:
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ọkùnrin burúkú kan sọ pé: ‘Bí irọ́ bá pẹ́ nílẹ̀, ṣe ló máa ń di òótọ́’—lédè míì, bó bá ti tó ẹgbẹ̀rún ìgbà téèyàn ti ń parọ́, òótọ́ ló máa pa dà já sí. Irọ́ tí ọkùnrin yẹn pa, èyí táwọn kan fẹ́ ká rí bí òótọ́, pa ọ̀pọ̀ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ lára.
Gbogbo ìpalára yẹn ti dìtàn báyìí, ìyẹn ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé ojú àwọn èèyàn ti là ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlélógún tá a wà yí kọjá kí wọ́n tún pa dà ṣe irú àṣìṣe tó wáyé nígbà yẹn.
Àmọ́ ó jọ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Irọ́ pípa yìí kan náà ni wọ́n pa dà lò nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ mi àti tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yòókù lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Irọ́ tí wọ́n pa tún ti dá ọ̀pọ̀ ìṣòro sílẹ̀, ó sì pa ọ̀pọ̀ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ lára.
Irọ́ tí wọ́n pa mọ́ mi ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí pé mo ṣì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ètò ẹ̀sìn tí ilé ẹjọ́ ti fòfin dè, tí ilé ẹjọ́ sọ pé ó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, àti pé mo ṣì ń ṣiṣẹ́ fún wọn ní bòókẹ́lẹ́, ìyẹn Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol.
Gbọnmọgbọnmọ ni wọ́n ń mẹ́nu kan ẹ̀sùn yìí nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń lọ lọ́wọ́ láì fi ẹ̀rí kankan gbè é lẹ́yìn. Lọ́nà yìí, àwọn tó fẹ̀sùn kàn mí mú kí irọ́ tí wọ́n pa dà bí òótọ́.
Ohun tó jẹ́ òótọ́ ni pé mi ò fìgbà kankan rí jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol.
Ó dájú pé mo ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ni mí. Èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń lọ sí ìpàdé tí àwùjọ ẹ̀sìn kan máa ń ṣe láwọn ilé ìpàdé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìpàdé náà ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol, àwọn ìpàdé náà sì bá Abala Kejìdínlọ́gbọ̀n [28] mu nínú Òfin Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà.
Mi ò bá wọn lọ́wọ́ sí ìgbòkègbodò Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol tí ilé ẹjọ́ ti fòfin dè, torí náà mi ò tẹ èyíkéyìí lára òfin orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lójú. Mi ò ṣe ohunkóhun tó jẹ́ ìgbawèrèmẹ́sìn rí.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ti bi mí pé: “Kí ló dé tí wọ́n fi ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ èèyàn àlàáfíà ní agbawèrèmẹ́sìn, kí ni wọ́n kà sí ìgbawèrèmẹ́sìn nínú ohun tí wọ́n ń ṣe?” Ìdáhùn tí mo máa ń fún wọn ni pé: “Mi ò mọ̀!”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ràn ọmọnìkejì wọn bí ara wọn. Wọ́n máa ń ṣe ohun tó dáa láwùjọ (láti ṣe àwùjọ láǹfààní). Olóòótọ́ èèyàn ni wọ́n, wọ́n máa ń pa àwọn òfin ìjọba mọ́, wọ́n sì máa ń sanwó orí. Kí ni wọ́n ṣe tó jẹ́ “ìgbawèrèmẹ́sìn”? Èmi alára ò mọ̀ ọ́n, mi ò sì tíì rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà látìgbà tí ìgbẹ́jọ́ yìí ti bẹ̀rẹ̀.
Wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé àwùjọ kékeré kan ti wọ́n fi òfin dá sílẹ̀ tí àwọn tó wà níbẹ̀ ò ju bíi mẹ́wàá lọ àmọ́ tí ilé ẹjọ́ kà sí agbawèrèmẹ́sìn ni mò ń bá kẹ́gbẹ́. Ìgbà wo lọ̀rọ̀ da èmi àti àwùjọ kékeré yìí pọ̀, báwo ni mo sì ṣe ń bá wọn kẹ́gbẹ́? Kí lohun tí mo ṣe gangan tó jẹ́ ìgbawèrèmẹ́sìn?
Mi ò rí ìdáhùn kankan sáwọn ìbéèrè yìí nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń lọ lọ́wọ́. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn tó fẹ̀sùn kàn mí fẹ́ kí irọ́ tí wọ́n ń pa léraléra di òótọ́!
Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà níbí, ẹnì kan ń fi gbogbo ara gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ẹni àlàáfíà bí agbawèrèmẹ́sìn, ìyẹn ò sì dáa, torí irọ́ tó jìnnà sóòótọ́ ni. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe agbawèrèmẹ́sìn. Ṣé ẹ mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
Lákọ̀ọ́kọ́ náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbébọn, wọn kì í sì í lọ́wọ́ sí rúkèrúdò. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n pa wọn lórílẹ̀-èdè Jámánì torí pé wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, ìyẹn Wehrmacht, lórílẹ̀-èdè Jámánì. Wọn ò bá wọn lọ sójú ìjà láti lọ pa àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Rọ́ṣíà.
Ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtijọ́, wọn ṣe inúnibíni rírorò sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọn sì sọ pé ọ̀tá aráàlú ni wọ́n torí pé wọ́n ní wọ́n lòdì sí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ṣùgbọ́n wọn ò torí ìyẹn kórìíra àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wọn.
Onírúurú èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ́ ará tó wà ní ìṣọ̀kan kárí ayé. Wọ́n ń gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan. Èyí fi hàn pé, bí a tiẹ̀ yàtọ̀ síra, a lè bára wa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan.
Ìkejì, yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, kò tún sí ibòmíì láyé tí wọ́n ti fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sin Ọlọ́run ní fàlàlà àti ní àlàáfíà ní ilẹ̀ tó ju igba (200) lọ kárí ayé. Àwọn èèyàn mọ̀ wọ́n sí ẹni àlàáfíà tí kì í ṣe agbawèrèmẹ́sìn lọ́nà èyíkéyìí.
Ohun kan náà ni gbogbo wọn gbà gbọ́, ìgbàgbọ́ wọn bá Bíbélì mu, ó sì ń mú kí wọ́n fi àwọn ànímọ́ tó dáa ṣèwà hù, irú bí ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, [ìwà tútù], àti ìkóra-ẹni-níjàánu.
Bíbélì pé àwọn ànímọ́ yìí ní “èso ti ẹ̀mí,” irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ kì í sì í dá rògbòdìyàn sílẹ̀ láwùjọ. Àwọn ànímọ́ yìí ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìgbawèrèmẹ́sìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo èèyàn ni wọ́n ń ṣe láǹfààní.
Ìkẹta, àwọn tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn sọ pé kò dáa bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe fi òfin tí wọ́n fi ń Gbéjà Ko Ìgbawèrèmẹ́sìn mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti sọ lọ́nà tó ṣe kedere pé ohun tí wọ́n ṣe yìí tàbùkù sí orúkọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tó jẹ́ ìlú tó lófin tí ìjọba tiwa-n-tiwa ti ń ṣàkóso. Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn táyé ń wárí fún yìí ì bá tí sọ pé kò dáa bí wọ́n ṣe fi òfin náà mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá jẹ́ pé wọ́n rí ohunkóhun tó jọ ìgbawèrèmẹ́sìn nínú ìjọsìn wọn.
Ìkẹrin, àwọn orílẹ̀-èdè míì ti sọ pé kò dáa bí wọ́n ṣe fi òfin tí wọ́n fi ń Gbéjà Ko Ìgbawèrèmẹ́sìn mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Yúróòpù rọ àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pé kí wọ́n dẹ́kun àtimáa fi òfin yìí mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbìmọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti sọ léraléra pé kò dáa bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe fi òfin tó ń gbéjà ko ìgbawèrèmẹ́sìn mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣe ló ń mú kí wọ́n máa ṣe inúnibíni sí àwọn èèyàn àlàáfíà tí kì í hùwàkiwà.
Jésù Kristi kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Tí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n máa ṣe inúnibíni sí ẹ̀yin náà.” (Jòhánù 15:20) * Níkẹyìn, wọ́n dá Jésù lẹ́bi, wọ́n sì pà á lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn èké kàn án pé ó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Irọ́ ni wọ́n pa mọ́ ọn, ìwà tí kó bófin mu pátápátá gbáà ni wọ́n sì hù yẹn.
Ṣùgbọ́n àwa ò gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, bẹ́ẹ̀ la ò sì gbé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́yìn. Ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà mọ́kànlélógún la wà yìí, àkókò tí oníkálùkù ní ẹ̀tọ́ tiẹ̀ tí òmìnira sì wà láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wuni—ẹ̀tọ́ náà sì gbọ́dọ̀ wà lọ́gbọọgba.
Ṣó tiẹ̀ ṣeé ṣe ká sọ fún ẹnì kan pé kó máà ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ká sì wá jù ú sẹ́wọ̀n torí pé ó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run? Mo gbà pé ìyẹn ò bójú mu. Àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ apàṣẹwàá nìkan nìyẹn ti lè ṣẹlẹ̀, kì í ṣe láwọn orílẹ̀-èdè tó lófin tí ìjọba tiwa-n-tiwa ti ń ṣàkóso, èyí tí mo lérò pé orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà jẹ́, tàbí tó ń gbìyànjú láti jẹ́.
Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń lọ lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, mo gbọ́ pé ìgbawèrèmẹ́sìn làwọn kan kà á sí bí ẹnì kan bá gbà pé ẹ̀sìn tòótọ́ lẹ̀sìn òun tó sì ń sọ fáwọn èèyàn nípa ẹ̀sìn náà. Èyí ò bọ́gbọ́n mu rárá torí pé gbogbo ẹlẹ́sìn ló gbà pé ẹ̀sìn tòótọ́ lẹ̀sìn àwọn. Kí nìdí tí wọ́n á fi máa ṣe ẹ̀sìn náà nìṣó bí wọn ò bá gbà pé ẹ̀sìn tòótọ́ ni?
Bí a bá fẹ́ torí èyí sọ pé ẹnì kan jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, a jẹ́ pé agbawèrèmẹ́sìn ni Jésù Kristi nìyẹn. Ó sọ fún Pọ́ńtíù Pílátù pé: “Torí èyí la ṣe bí mi, torí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tó bá fara mọ́ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.”—Jòhánù 18:37.
Ohun tí Jésù sọ yìí fi hàn pé a lè rí òtítọ́ nínú [Bíbélì]. Jésù wàásù nípa òtítọ́ yìí ó si fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kì í ṣe òtítọ́ tó jẹ́ òdìkejì irọ́ ni Jésù ń sọ o. Òtítọ́ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe ló fi kọ́ni. Ní ṣókí, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ni pé kí Jésù, “ọmọ Dáfídì” (àtọmọdọ́mọ rẹ̀), jẹ́ Àlùfáà Àgbà àti Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run.
Jésù ṣàlàyé pé ìdí pàtàkì tóun fi wá sí ayé àti ohun tí ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun lórí ilẹ̀ ayé dá lé lórí ni láti polongo òtítọ́ nípa Ìjọba yẹn. Ṣé àwọn èèyàn tó ń gbé láyé lóde òní kà Jésù sí agbawèrèmẹ́sìn torí pé ó wàásù nípa òtítọ́?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, wọ́n sì ń wàásù nípa òtítọ́, tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì, pé Ìjọba Ọlọ́run ni ojútùú kan ṣoṣo sí gbogbo ìṣòro tó ń bá àwa èèyàn fínra. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì, ni wọ́n fi ń kọ́ gbogbo èèyàn.
Jésù sọ nígbà kan tó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Torí náà, ó ṣe pàtàkì fún gbogbo èèyàn pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ó máa ṣe wọ́n láǹfààní kò sì ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìgbawèrèmẹ́sìn.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan kọ́ ló mọyì Bíbélì. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, Mikhail Lomonosov sọ pé: “Ìwé méjì ni Ẹlẹ́dàá fún ìran èèyàn. Ìkan sọ nípa ìtóbilọ́lá Rẹ̀, ìkejì sì sọ nípa ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. Ìwé àkọ́kọ́ ni ayé àtọ̀run tí Ọlọ́run dá . . . Ìwé kejì ni Bíbélì Mímọ́.”
Kò sí iyè méjì pé Lomonosov fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òótọ́ sì lọ̀rọ̀ tó sọ. Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ nípa Ọlọ́run tá a bá fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tó dá. A sì lè mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run tá a bá ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tá a sì ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.
A rí i kà nínú Bíbélì pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì wúlò fún kíkọ́ni, . . . fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo, kí èèyàn Ọlọ́run lè kúnjú ìwọ̀n dáadáa, kó sì lè gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.” (2 Tímótì 3:16, 17) Fún gbogbo iṣẹ́ rere!
Ní àwọn ìpàdé ìjọ, tí mo lọ, tí mo sì kópa nínú rẹ̀, tí àwùjọ ẹ̀sìn kan tí kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol darí rẹ̀, bá a ṣe lè máa ṣe ohun tó dáa fáwọn èèyàn la jíròrò níbẹ̀.
Nínú àwọn fọ́nrán fídíò ìpàdé méjì tá a ṣe ní February 19 àti 26, 2017, tá a wò nílé ẹjọ́, ó ṣe kedere pé a ò rí ohunkóhun tó jọ ìgbawèrèmẹ́sìn níbẹ̀, a ò sì gbọ́ ohun tó jọ ọ́. Ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní gan-an la jíròrò níbẹ̀. Ìpàdé náà tuni lára ó sì múni láyọ̀ bó ṣe máa ń rí ní gbogbo ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Kò sí ohun tó lè pa àwùjọ lára nínú ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a jíròrò. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ gan-an, wọ́n á sì tù wọ́n nínú. Ní ti àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó ti kú, ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì ni pé: “Ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn ni a ó sọ di asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:26.
Gbogbo èèyàn ló ń bẹ̀rù ikú torí pé wọ́n rí i bí ọ̀tá kan tó lágbára, àmọ́ Ọlọ́run ò bẹ̀rù ikú. Bíbélì ṣèlérí nínú Àìsáyà 25:8 pé: “Ó máa gbé ikú mì títí láé, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì máa nu omijé kúrò ní ojú gbogbo èèyàn.”
Ìdùnnú á mà ṣubú layọ̀ nígbà yẹn o! Kò ní sí ìsìnkú tàbí àwọn itẹ́ òkú mọ́. Ẹkún ayọ̀ á dípò ẹkún ìbànújẹ́ nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìlérí àgbàyanu rẹ̀ ṣẹ tó sì jí àwọn òkú dìde. Níkẹyìn, gbogbo ìrora àti ìbànújẹ́ tí ikú ti dá sílẹ̀ kò ní sí mọ́.
Ìrètí yìí tù mí nínú gan-an ni torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún mi ti kú. Nígbà tí mo wà ní àtìmọ́lé, ẹni kan tó sún mọ́ mi, tó ṣe pàtàkì sí mi gan-an kú, ìyẹn màmá màmá mi, Helga Margrethe Christensen.
Òun ló kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìdílé wa tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn tó kọ́ bàbá mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló wá kọ́ èmi náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó mọ̀ ọ́n, ní àdúgbò, níbi iṣẹ́ àti nínú ìdílé fẹ́ràn rẹ̀ wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un.
Òun náà bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn, láìka ẹ̀sìn, orílẹ̀-èdè, tàbí àwọ̀ wọn sí. Ó gbìyànjú láti ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́, ó sì ṣe dáadáa sáwọn aládùúgbò rẹ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn kan á fẹ́ láti pè é ní agbawèrèmẹ́sìn. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ẹni tórí ẹ̀ pé ò ní bá wọn pè é bẹ́ẹ̀.
Mò ń dúró dé ọjọ́ náà tí Ọlọ́run máa jí i dìde, tá ó sì tún pa dà ríra. Ó dùn mí ṣáá pé mi ò lè lọ síbi ìsìnkú rẹ̀. Mi ò sí níbẹ̀ láti tu ìdílé mi nínú nígbà ìṣòro yẹn, torí pé mo wà ní àtìmọ́lé torí ẹ̀sùn ìgbawèrèmẹ́sìn tí ò mọ́gbọ́n dání tí wọ́n fi kàn mí yìí.
Ìlérí tí Bíbélì ṣe pé àwọn òkú máa jíǹde tù mí nínú ó sì mú kó dá mi lójú pé mi ò pàdánù rẹ̀ títí ayé, àti pé a ṣì máa pa dà ríra nínú ayé tí a ti sọ dọ̀tun lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. Bí ìlérí yìí bá lè ràn mí lọ́wọ́ kó sì tù mí nínú, ó dá mi lójú pé ó lè ran àwọn míì náà lọ́wọ́ kó sì tù wọ́n nínú.
Ohun míì tí Bíbélì sọ táa tún máa ń jíròrò láwọn ìpàdé wa ni párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó máa wà lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí oúnjẹ tó pọ̀ tó á ti wà fún gbogbo èèyàn tí àlàáfíà á sì jọba; níbi tí ẹnikẹ́ni ò ti ní ṣàìsàn, bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà 33:24, tó sọ pé: “Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’ A ti máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn tó ń gbé ilẹ̀ náà jì wọ́n.”
Béèyàn bá ń sọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí fáwọn èèyàn láwùjọ ṣó lè pa wọ́n lára? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe làwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí máa mú káwọn èèyàn nírètí ó sì máa fún wọn láyọ̀. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pá a mọ́!”—Lúùkù 11:28.
Oníkálùkù ló máa yàn bóyá òun máa gba èyí gbọ́ tàbí òun ò ní gbà á gbọ́. Ọlọ́run kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti sin òun. Ohun tó sọ nínú Jeremáyà 29:11 ni pé: “ ‘Nítorí mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’ ”
Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo wa gbé ìgbé ayé tó dáa jù lọ—ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ké sí gbogbo èèyàn pé kí wọ́n yan ìgbésí ayé tó dára jù lọ yìí, òun ni ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run táá sì mú kí wọ́n jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Kò sí ohun tó jọ ìgbawèrèmẹ́sìn nínú gbogbo èyí. Kí wá ni “ìgbawèrèmẹ́sìn nínú ohun tí mo ṣe,” kí sì ni wọ́n torí ẹ̀ fẹ́ fi mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà?
Mi ò hùwà ọ̀daràn tàbí ti agbawèrèmẹ́sìn. Àwọn aládùúgbò mi, ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ mi àtàwọn òṣìṣẹ́ ọgbà àtìmọ́lé ń sọ̀rọ̀ mi ní rere. Torí náà, mo tún fẹ́ béèrè lẹ́ẹ̀kan sí i pé: Kí ni “ìgbawèrèmẹ́sìn nínú ohun tí mo ṣe,” kí sì ni wọ́n torí ẹ̀ fẹ́ fi mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà?”
Kò yé mi, kò sì tíì yé mi láti ọdún méjì sẹ́yìn. Bóyá Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn á le dáhùn àwọn ìbéèrè mi ní pàtó, torí ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ mi ò dáhùn àwọn ìbéèrè náà fún mi.
Bí mo ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlélógún la wà yìí, kì í ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́yìn. Ojú àwọn èèyàn ti là ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n ó bani nínú jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tún ń ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn torí ẹ̀sìn wọn, ó sì tún ń fìyà jẹ wọ́n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.
Ní February 15, 2019, nígbà tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méje, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣèwádìí Ọ̀rọ̀ nílùú Surgut dá wọn lóró kí ìgbìmọ̀ náà lè mú wọn sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́. Wọn ò jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí lo Abala Kọkànléláàádọ́ta [51] nínú Òfin Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà èyí tí ò ní jẹ́ kí wọ́n jẹ́rìí lòdì sí ara wọn tàbí lòdì sí àwọn èèyàn wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ní òfin náà wà fún.
Wọ́n fi tipátipá mú kí wọ́n kúnlẹ̀ kí wọ́n sì ká ọwọ́ wọn sókè, wọ́n gbá nǹkan mọ́ wọn lórí, wọ́n sì lù wọ́n bí ẹní lu bàrà, wọ́n fi wọ́n ṣẹ̀sín torí ibi tí wọ́n ti wá àti torí ẹ̀sìn wọn; wọ́n gbé àpò lé wọn lórí wọ́n sì fi téèpù lẹ̀ ẹ́ yíká ọrùn wọn kó lè ṣòro fún wọn láti mí, wọ́n dè wọ́n lọ́wọ́ sẹ́yìn, wọ́n sì tún de ẹsẹ̀ wọn. Wọ́n jágbe mọ́ wọn, kí wọ́n lè fipá mú wọn sọ̀rọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀mí fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ lẹ́nu díẹ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà wọ́n sì dákú torí pé wọn ò lè mí dáadáa. Wọ́n á wá da omi lé wọn lórí, wọ́n á sì ti iná ẹ̀lẹ́tíríìkì bọ̀ wọ́n lára.
Gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wà nínú àkọsílẹ̀ àwọn tó fara balẹ̀ ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tó tíì fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn èyíkéyìí kan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣèwádìí Ọ̀rọ̀ náà. Ṣe ni àwọn aláṣẹ wulẹ̀ kọtí ikún sí ohun tó ṣẹlẹ̀ tàbí kí wọ́n sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà ló para wọn lára. Etí wo ló ń báni gbọ́rú ẹ̀! Irọ́ tó jìnnà sóòótọ́!
Ṣe ni gbogbo ìwà ìkà yìí tàbùkù sí ìtàn orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà òde òní, mo sì lérò pé gbogbo àwọn tó bá lọ́wọ́ sí ìwà búburú náà máa jẹ́jọ́ wọ́n á sì jẹ wọ́n níyà. Kí ló mú wọn hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ sáwọn èèyàn? Kí ló mú kí wọ́n hu irú ìwà ìdánilóró tó burú jáì irú èyí Hitler àti Stalin hù? Ì bá dáa ká ní wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Mo nírètí pé àṣìṣe ni, wọ́n sì máa tó wá nǹkan ṣe sí i!
Adájọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ náà sọ nínú ìdájọ́ rẹ̀ pé: “Kò bófin mu fún ẹnì kan pé kó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ètò ẹ̀sìn kan tí ilé ẹjọ́ ti fòfin dè torí pé irú ètò ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ gba wèrè mẹ́sìn, ìwà ìgbawèrèmẹ́sìn téèyàn lè torí ẹ̀ jìyà ìwà ọ̀daràn ni.” Kò sírọ́ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n báwo nìyẹn ṣe kàn mí?
Kò sí ohun tó kàn mí nínú gbogbo ìyẹn! Ohunkóhun ò da èmi àti Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol pọ̀ rí. Kò sí bí mo ṣe lè máa bá a nìṣó láti ṣiṣẹ́ fún wọn.
Gbogbo ohun tí mò ń ṣe ba ìgbé ayé mi mu gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó ń dara pọ̀ mọ́ àwùjọ ẹ̀sìn kan tí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwùjọ ẹ̀sìn ti wọ́n fi òfin dá sílẹ̀ náà, ìyẹn Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol. Kò sí ohun tó lòdì sófin nínú gbogbo nǹkan tí mò ń ṣe, gbogbo ẹ sì bá Abala Kejìdínlọ́gbọ̀n [28] mu nínú Òfin Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà.
Mi ò rò ó rí pé Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol tí ìjọba ti fòfin dè ni mò ń ṣiṣẹ́ fún. Nínú ọ̀rọ̀ tí mo bá ẹnì kan sọ lórí fóònù, èyí tá a gbọ́ nílé ẹjọ́ yìí, mo sọ fún ọ̀rẹ́ mi pé: “Àwùjọ ẹ̀sìn kan ni wá. A ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol tàbí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wọn.”
Ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ mi ò ka ọ̀rọ̀ náà sí, dípò ìyẹn ó lo ẹ̀rí èké tí A. P. Yermolov, tó jẹ́ aṣojú FSB, mú wá ní bòókẹ́lẹ́. Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lè ṣèwádìí kí wọ́n lè rí i pé Oleg Gennadyevich Kurdyumov lẹni tó pera ẹ̀ ní A. P. Yermolov.
Oleg Kurdyumov ti kọ́kọ́ sọ fáwọn tó ń ṣèwádìí pé ohun ò mọ́ nǹkan kan, ó sì lo Abala Kọkànléláàádọ́ta [51] nínú Òfin Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà kó máa bàa jẹ́rìí lódì síra ẹ̀. Ní ọjọ́ kejì, ọ̀tọ̀ ni ẹ̀rí tó jẹ́ níwájú ilé ẹjọ́, orúkọ míì, ìyẹn A. P. Yermolov ló sì fi bojú nígbà tó ń jẹ́jọ́ náà. Ó tún fi orúkọ náà bójú láti jẹ́rìí púpọ̀ sí i níwájú ilé ẹjọ́.
Nílé ẹjọ́, nígbà tá a wo fọ́nrán fídíò àwọn ìpàdé wa méjì tá a ṣe ní February 19 àti 26, 2017, èyí tí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Ètò Ẹ̀sìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ìbílẹ̀ Oryol, ó ṣe kedere pé Oleg Kurdyumov lo dọ́gbọ́n yàwòrán ìpàdé náà tó sì gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Ó pani lẹ́rìn-ín láti rí bó ti ṣe kedere tó pé ọwọ́ rẹ̀ ni kámẹ́rà wà. Ibi tó bá yí sí ni kámẹ́rà náà máa ń dojú kọ, nígbà tí ẹnì kan sì lọ bá a, kedere lèèyàn á gbọ́ tó sọ pé, Báwo ni, Oleg lorúkọ mi.”
Èyí fi hàn pé ó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ fún àjọ FSB, ó ń bá wọn yàwòrán ìpàdé náà ó sì ń gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, tó bá lo orúkọ tó ń jẹ́ gangan, á ní ohun ò mọ nǹkan kan. Lọ́jọ́ kejì, ó fi orúkọ míì bojú, ó parọ́ fáwọn tó ń ṣèwádìí, ó sì tún irọ́ náà pá nílé ẹjọ́. Ṣó wá dáa bẹ́ẹ̀?
Òfin ò gbà káwọn aṣojú FSB máa fi orúkọ míì bojú láti wá ṣe ẹlẹ́rìí nílé ẹjọ́. Ṣùgbọ́n ṣe ni olùpẹ̀jọ́, agbẹjọ́rò ìjọba, àti adájọ́ ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ mi mọ̀ọ́mọ̀ dijú sí ohun tí òfin sọ tí wọ́n sì jẹ́ kó jẹ́rìí èké níwájú ilé ẹjọ́. Ẹ̀rí èké yẹn ni wọ́n fi ń bá mi ṣẹjọ́ báyìí. Kò yé mi bí ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ mi ṣe lè gba irú èyí láyè.
Èyí tó tiẹ̀ wá rú mi lójú jù lọ ni bí olùpẹ̀jọ́—agbẹjọ́rò ìjọba tó yẹ kó gbógun ti ìwà tí ò dáa—ṣe lè gba gbogbo ìyẹn láyè. Àwọn ló yẹ kó rí sí i pé ohunkóhun tó lódì sófin orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ò wáyé. Ṣùgbọ́n torí pé wọ́n fi rírí ṣe aláìrí ni ọ̀rọ̀ fi rí bó ṣe rí yìí.
Mo bẹ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn pé kí wọ́n lóye ọ̀rọ̀ mi dáadáa. Mi ò kórìíra àwọn èèyàn yìí o. Ó dá mi lójú pé ẹni rere àti ọmọlúwàbí ni wọ́n, a sì lè jọ jókòó mu ife kọfí lọ́jọ́ iwájú, tí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí á sì wá dọ̀rọ̀ ẹ̀rín. Ṣùgbọ́n inú mi ò dùn bí wọn ò ṣe ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, ohun tí wọ́n ṣe burú, ó bògìrì.
Mo mọ̀ pé ó rọrùn fún ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ mi láti jẹ́ kí aṣojú FSB fi orúkọ míì bojú láti wá jẹ́rìí èké lòdì sí mi, torí pé ẹlẹ́rìí náà ò sì ní ẹ̀rí ọkàn, ó rọrùn fún un láti parọ́ kó pe ajá lọ́bọ, kó sì sọ ohunkóhun tó bá máa mú kí ilé ẹjọ́ jù mí sẹ́wọ̀n.
Irú ẹlẹ́rìí bẹ́ẹ̀ ò ṣeé fọkàn tán, ohun tó bá sọ ò sì ṣeé gbára lé. Kò dáa láti máa lo irú àwọn ẹlẹ́rìí bẹ́ẹ̀ láti ran àwọn èèyàn lọ sẹ́wọ̀n.
Ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn, tí ọ̀pọ̀ ìgbẹ́jọ́ wáyé lórí bóyá wọ́n a fi kún iye ọjọ́ tí màá fi wà ní àhámọ́, ìgbà kan wà tí mo sọ fún ilé ẹjọ́ pé, “Mo bẹ̀ yín pé kẹ́ ẹ tú mi sílẹ̀ kí n máa relé!” Ẹ̀bẹ̀ tí mo ṣì ń bẹ́ yín náà nìyẹn o.
Ní ti àhámọ́ tí wọ́n fi mí sí, mo lérò pé kì í wulẹ̀ ṣe pé wọ́n fẹ́ mú mi kúrò láwùjọ kí wọ́n sì fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn mí nìkan ni. Ṣe ni wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn rí mi mọ́, kí wọ́n lè gbàgbé bí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ yìí ṣe ń lọ sí.
Lójú tèmi, ìwà ìkà àti ìwà tí kò bófin mu ló jẹ́ pé wọ́n tì mí mọ́lé kí wọ́n tó gbẹ́jọ́ mi, wọn ò sì tú mi sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gbẹ́jọ́ mi tán. Torí kí n má bàa ní àǹfààní láti gbèjà ara mi bó ṣe tọ́ kí n má sì lè sọ ojú tí mo fi wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fáwọn oníròyìn ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, mo ṣì máa làǹfààní láti sọ tẹnu mi!
Mo fẹ́ kẹ́ ẹ tú mi sílẹ̀ kí èmi àti ìyàwó mi, Irina, tún lè jọ máa gbé ní àlàáfíà àti ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ nínú ìlú wa tó rẹwà yìí. Fún nǹkan bí ọdún méjì báyìí, mi ò lè pinnu ohun tí mo fẹ́. Ohun táwọn mi là kalẹ̀ fún mi ni mò ń ṣe.
Àwọn FSB parọ́ mọ́ mi, wọ́n sì bà mí lórúkọ jẹ́. Wọ́n yíwèé, wọ́n parọ́ nípa ohun táwọn tó fara balẹ̀ wádìí ọ̀rọ̀ sọ, wọ́n sì lo àwọn ẹlẹ́rìí èké tó fi orúkọ míì bojú láti wá parọ́ mọ́ mi nílé ẹjọ́.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni àlàáfíà ni mi, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ṣe yẹn kí wọ́n lè mú káwọn èèyàn rò pé agbawèrèmẹ́sìn àti eléwu ni mo jẹ́ fáwọn èèyàn àti fún ààbò orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ó ṣe kedere pé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí yìí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, kàyéfì gbáà ló sì jẹ́.
Ó bani nínú jẹ́ pé ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ mi gba gbogbo ẹ̀sùn yìí gbọ́ ó sì kọtí ikún sí bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gangan. Adájọ́ Àtàtà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ paná àìṣòdodo yìí kẹ́ ẹ sì fìdí òtítọ́ múlẹ̀. Ẹ̀bẹ̀ ni mo bẹ̀ yín, “Ẹ tù mí sílẹ̀ kí n máa relé!”
Bí mo ṣe sọ ní oṣù mẹ́tà sẹ́yìn nílé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ mi: Àbájáde kan ṣoṣo tí màá fara mọ́ nínú ìgbẹ́jọ́ yìí ni pé kẹ́ ẹ dá mi láre, kẹ́ ẹ tú mi sílẹ̀, kẹ́ ẹ tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ mi, kẹ́ ẹ sì sanwó ìtanràn fún mi. Kó sóhun tó lè rọ̀ mí lọ́kàn jù ìyẹn lọ!” Orí ohun tí mo sọ yẹn náà ni mo ṣì dúró lé.
Ìrẹ́jẹ ni màá ka ìpinnu ìdájọ́ tó bá yàtọ̀ síyẹn sí, màá sì pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù tó wà ní ìlú Strasbourg. Ó dá mi lójú pé màá jàre ẹjọ́ yìí níbẹ̀.
Tí mo bá jàre ẹjọ́ náà tán, á ya Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, gbogbo èèyàn kárí ayé, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn olóyè kàǹkà-kàǹkà kan lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, títí kan Ààrẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, Vladimir Vladimirovich Putin, lẹ́nu, á sì ṣe wọ́n ní kàyéfì pé ilé ẹjọ́ ìbílẹ̀ Oryol kùnà láti rí ohun tó ṣe kedere sí gbogbo aráyé, ìyẹn ni pé orí irọ́ tí wọ́n pa ní àpatúnpa kó lè fara hàn bí òótọ́ ni wọ́n gbé ẹjọ́ tí wọ́n bá mi ṣe kà.
Ṣó wá pọn dandan kí gbogbo èyí wáyé kẹ́ ẹ tó dá mi láre? Bí ilé ẹ̀jọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà bá wá ní kí n fò kí n nìṣó, mo fẹ́ fi da yín lójú àti gbogbo ẹni tó ń gbọ́rọ̀ mi lónìí yìí títí kan gbogbo àwọn tó ti ń gbọ́rọ̀ ìgbẹ́jọ́ yìí látìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀, pé, “Mo ti ṣe tán!”
Mi ò ní jáwọ́ torí mo mọ̀ pé mi ò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí, òótọ́ ni mo sì ń sọ. Mi ò bẹ̀rù pé kí wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpinnu tí ò dáa nìyẹn máa jẹ́.
Ẹ̀rù ò bà mí, mi ò sì fòyà. Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, ara sì tù mí. Jèhófà, Ọlọ́run mi, ò ní fi mí sílẹ̀ láé, mo sì nímọ̀lára pé àwọn ọ̀rọ̀ tó lárinrin yìí ti ń ṣẹ sí mi lára:
Olóòótọ́ ni Jèhófà,
Kò ní gbàgbé iṣẹ́ ìsìn mi.
Yóò sì máa wà pẹ̀lú mi,
Kò ní fi mí sílẹ̀ láéláé.
Jèhófà l’aláàbò mi,
aláàánú àti olùpèsè.
Bàbá mi ni, Ọ̀rẹ́ mi ni,
Ọlọ́run mi.
Ọ̀rọ̀ mi parí síbí. Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ tẹ́tí gbọ́ mi!
^ ìpínrọ̀ 24 Dennis fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìtumọ̀ ti ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe. Ṣùgbọ́n, nínú àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ yìí, gbogbo ìwé mímọ́ tá a lò wá látinú ẹ̀dà Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe.