JUNE 11, 2019
RỌ́ṢÍÀ
Àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ tí Dennis Christensen Sọ Níwájú Ilé Ẹjọ́ ní May 23
Ní Thursday, May 23, 2019, tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Dennis pè, ó sọ àsọkágbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ níwájú ilé ẹjọ́. Àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ tó sọ (tá a túmọ̀ láti èdè Rọ́ṣíà) rèé:
Ní báyìí mò ń dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ ràn mí lọ́wọ́ pé ẹ kú àdúrótì láti ọdún méjì sẹ́yìn tí wọ́n ti ń bá mi ṣẹjọ́ ọ̀daràn.
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, màá fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó mi, Irina, torí pé látìgbà tí ẹjọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ ló ti ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè ràn mí lọ́wọ́ kó sì tì mí lẹ́yìn. Ó tọ́jú mi, ó bá mi kó aṣọ, oúnjẹ, egbòogi àtàwọn nǹkan míì tí mo nílò ní àtìmọ́lé wá. Ó máa ń bẹ̀ mí wò, mo sì máa ń rí àwọn lẹ́tà rẹ̀ gbà lójoojúmọ́. Ó tipa bẹ́ẹ̀ tù mí nínú ó sì mú kí n túbọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin.
Aya mi ọ̀wọ́n, ìgbàgbọ́ rẹ tó dúró sán-ún, sùúrù rẹ ìgbà gbogbo, bí o ò ṣe jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ kó ìpayà bá ẹ, bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ mi tó o sì nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, tó ò sì sọ̀rètí nù, ti jẹ́ àpẹẹrẹ ńláǹlà fún mi. Mo fẹ́ kó o mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, ẹni àmúyangàn sì ni ẹ́!
Mo tún fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìdílé mi ní orílẹ̀-èdè Denmark, ní pàtàkì bàbá mi àgbà àti arábìnrin mi. Mo ṣàárò yín gan-an ni o. Mo nífẹ̀ẹ́ yín mo sì mọrírì gbogbo nǹkan tẹ́ ẹ ti ṣe fún mi. Nígbà tí mo wà ní àtìmọ́lé, ẹ fi ọ̀pọ̀ lẹ́tà tẹ́ ẹ kọ àti ìpè orí fóònù gbé mi ró. Ó dá mi lójú pé ẹ ò ní jẹ́ kó rẹ̀ yín, ẹ ò sì ní gbàgbé láé pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tá ó tún pa dà wà pa pọ̀ bí ìdílé kan.
Màá tún fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi kárí ayé. Àwọn lẹ́tà tẹ́ ẹ kọ, ọ̀rọ̀ ìṣírí, àwòrán tó fani mọ́ra àti onírúurú ẹ̀bùn tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ gbé mi ró gan-an. Gbogbo rẹ̀ mú kí n rí i pé mi ò dá wà àti pé mo jẹ́ ara ìdílé kan tó wà kárí ayé.
Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé gbogbo lẹ́tà tẹ́ ẹ kọ, àtèyí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ pọ̀ àtèyí tó ṣe ṣókí, fún mi ní ìṣírí ó sì gbé mi ró. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ máà bínú bí mi ò bá lè fèsì lẹ́tà yín. Mọ ṣèlérí pé lọ́jọ́ iwájú, màá wá yín kàn, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, màá sì gbá yín mọ́ra!
Màá tún fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ́fíìsì Aṣojú Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Denmark tó wà nílùú Moscow àti gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ wọn. Ẹ wà níbẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ wáyé, ọ̀pọ̀ ìgbà lẹ sì wá wò mí ní àtìmọ́lé. Kòṣeémáàní ni ìmọ̀ràn rere, ìtọ́sọ́nà àti ọ̀rọ̀ ìyànjú yín jẹ́ fún mi. Mo mọrírì ìtìlẹ́yìn àti ìrànlọ́wọ́ tẹ́ ẹ ṣe fún mi.
Màá sì tún fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó jẹ́ kí n wà síbi ìgbẹ́jọ́ yìí lónìí. Láwọn ibi ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn yòókù tí wọ́n ti gbẹ́jọ́ mi, ẹ̀rọ àtagbà onífídíò tó wà ní ọgbà àtìmọ́lé ni mo lò, kò sì rọrùn fún mi láti gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n sọ. Bí ìdajì lára ohun tí wọ́n sọ ni mì o gbọ́, mo kàn ń méfò lásán ni. Ìyẹn ò jẹ́ kí n lè gbèjà ara mi dáadáa. Àti pé yàtọ̀ síyẹn, téèyàn bá ń lo àtagbà onífídíò tó wà ní ọgbà àtìmọ́lé, ẹ̀yìn irin lèèyàn á jókòó sí bí ẹran tó wà ní ọgbà ẹranko. Mi ò rí ìyẹn bí ohun tó yẹ, ìwà àìfinipeni ló sì jẹ́ nírú àkókò tá a wa yìí.
Ní báyìí, mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún méjì ní àtìmọ́lé, ọdún kan àti oṣù mẹ́ta sì nìyí tá a ti wà lẹ́nu ìgbẹ́jọ́ yìí. Ẹni tó bá bára ẹ̀ nípò tí mo wà yìí gbọ́dọ̀ lókun nínú dáadáa kó lè fara da gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kó má sì rẹ̀wẹ̀sì. Nínú Bíbélì, Fílípì orí kẹrin, ẹsẹ ìkẹtàlá (4:13), sọ pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.” * Àìsáyà orí kejìlá, ẹsẹ ìkejì (12:2), sọ pé: “Wò ó! Ọlọ́run ni ìgbàlà mi. Màá gbẹ́kẹ̀ lé e, ẹ̀rù ò sì ní bà mí; torí Jáà Jèhófà ni okun mi àti agbára mi, ó sì ti wá di ìgbàlà mi.”
Látìgbà tí mo ti wà ní àtìmọ́lé ni mo ti ń nímọ̀lára pé Jèhófà Ọlọ́run mi wà nítòsí mi, tó ń fún mi lágbára kí n lè fara da gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí; ó fún mi lókun kí n lè fara dà á, kí n máa bàa rẹ̀wẹ̀sì, kí n lè máa láyọ̀, kí n má sì banú jẹ́. Mo dúpẹ́ látọkànwá fún ohun tó ṣe yìí, inú mi sì dùn pé mo wà lára àwọn tó ń sìn ín, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí.
Ọ̀pọ̀ ti bi mí pé báwo ní ọ̀rọ̀ ẹjọ́ yìí ṣe rí lára mi. Ká sòótọ́, kò rọrùn láti wà ní ọgbà àtìmọ́lé fún àkókò gígùn, kí ìyàwó wà lọ́tọ̀, kéèyàn má sì lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìdílé ẹni àtàwọn ọ̀rẹ́. Láti ọdún méjì sẹ́yìn, èmi nìkan ni mò ń dá wà. Bíi ká ṣáà sọ pé mo wà bí aláìsí. Nínú wákàtí mẹ́rìnlélógún tó máa ń wà nínú ọjọ́ kan, mẹ́tàlélógún nínú ẹ̀ ni mo máa ń lò nínú yàrá ọgbà ẹ̀wọ̀n tó jẹ́ nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́wàá ní fífẹ̀ àti bí ogún ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn. Wákàtí kan lóòjọ́ ni mo fi máa ń rìn kiri nínú ọgbà eré ìdárayá, tóun náà jẹ́ nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́wàá ní fífẹ̀ àti bí ogún ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn, ó kéré tán, màá fìyẹn rí ohun tó ń lọ níta. Ní gbogbo ọdún méjì yìí, mo bá onírúurú èèyàn pàdé a sì jọ sọ̀rọ̀ tó lárinrin. Mo sì kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ lára wọn ń fẹ́ kí wọ́n ṣe ìwádìí ẹjọ́ àwọn lọ́nà tó tọ́ kí wọ́n sì rí ìdájọ́ òdodo gbà. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn gbà pé wọn ò jẹ́ káwọn sọ tẹnu àwọn, bọ́rọ̀ sì ṣe rí lára èmi náà nìyẹn láti ọdún méjì sẹ́yìn. Mo ti gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ débi tí mo lè ṣe é dé, torí ó dá mi lójú pé ohun tí Jésù Kristi náà máa ṣe nìyẹn.
Mo ti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Díẹ̀ lára wọ́n wà níbi ìgbẹ́jọ́ mi; àwọn míì kọ lẹ́tà sí mi. Mo ti bá àwọn kan lára wọn pàdé rí, ṣùgbọ́n mi ò tíì mọ àwọn yòókù. Ẹ̀sìn kan náà ni èmi àti àwọn kan lára wọn ń ṣe; àwọn míì ń ṣe ẹ̀sìn tó yàtọ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n tì mí lẹ́yìn, torí wọ́n gbà pé ìwà tí kò tọ́ ni wọ́n ń hù sí mi. Ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà níbí, àwọn kan sọ pé ọ̀daràn ní àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Ìyẹn ò bọ́gbọ́n mu kò sì ṣeé gbọ́ sétí, torí pé ẹni àlàáfíà ni wọ́n jẹ́ nílùú wọ́n sì fẹ́ràn àwọn aládùúgbò wọn bí ara wọn. Ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní kàyéfì pé irú nǹkan bí èyí ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà mọ́kànlélógún yìí.
Àwọn kan ti bi mí pé ipa wo ni ẹjọ́ ọ̀daràn tí wọ́n ń bá mi ṣe yìí ti ní lórí ìgbàgbọ́ mi. Ẹjọ́ ìwà ọ̀daràn tí wọ́n ń bá mi ṣe yìí ti wá mú kí ìgbàgbọ́ mi lágbára sí i, ọ̀rọ̀ mi sì ti wá dà bí ohun tí Bíbélì sọ nínú Jémíìsì orí kìíní, ẹsẹ ìkejì sí ìkẹrin (1:2-4): “Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ yín ti a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà. Àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun gbogbo, láìkù síbì kan.”
Ó dájú pé mi kì í ṣe ẹni pípé, ṣùgbọ́n mo tí kọ́ láti ní ìfaradà kí n sì máa láyọ̀ bí mo bá ń la àdánwò kọjá. Ohun tó sì ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ó ti mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run mi. Ṣe ló túbọ̀ ń wù mí gidigidi láti sọ fáwọn ẹlòmíì nípa rẹ̀ àtàwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe; ó túbọ̀ ń wù mí gidigidi láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tó jẹ́ ìjọba kan ṣoṣo tó máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé; ó túbọ̀ ń wù mí gidigidi láti jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere Bíbélì pé a máa gbádùn àlàáfíà àti ìyè ayérayé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé, kí n ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Ẹlẹ́dàá kí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú rẹ̀ àti nínú àwọn ìlérí tó ṣe.
Nílé ẹjọ́, “Ọ̀rọ̀ àsọkágbá” ni wọ́n pe ọ̀rọ̀ tí mo fi gbèjà ara mi yìí, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ ò ní gbọ́rọ̀ míì lẹ́nu mi mọ́ lẹ́yìn tòní. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbẹ́jọ́ tó máa wáyé kẹ́yìn rèé nínú ẹjọ́ ọ̀daràn tí wọ́n ń bá mi ṣe táá sì fi òpin sí ọdún méjì tí wọ́n ti fi mí sí àtìmọ́lé. Ṣùgbọ́n, mo fẹ́ fi dá yín lójú pé èyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ tí màá sọ kẹ́yìn nínú ẹjọ́ yìí àti nípa ìwà ìrẹ́jẹ tí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń hù sí àwọn ẹni àlàáfíà tí kò sí ìwà búburú kankan lọ́wọ́ wọn. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà tí màá sọ fáráyé. Mi ò jẹ̀bi ohunkóhun, mi o sì ṣe ohun máà-jẹ́-á-gbọ́, torí náà mi ò ní panu mọ́. Mi ò hùwà àìdáa kankan, mi ò rú èyíkéyìí lára òfin orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, torí náà ẹ̀rí ọkàn mi mọ́, kò sì sí ohun tó máa mú kójú tì mí.
Àwọn tó ń hùwà tí ò tọ́ sí èmi àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yòókù lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà níbí lo yẹ kójú tì. Wọ́n ń fi ẹ̀sùn èké kàn wá pé a jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò, wọ́n ń mú wa, wọ́n ń yẹ ilé wa wò, wọ́n ń gba ohun ìní wa, wọ́n ń wádìí nípa wa, wọ́n ń halẹ̀ mọ́ wa, àti ní báyìí wọ́n ń dá wa lóró. Ìwà àbùkù ni wọ́n ń hù yẹn. Òtítọ́ ló máa lékè, òdodo sì máa fara hàn bópẹ́ bóyá. Nínú Gálátíà orí kẹfà ẹsẹ̀ ìkeje (6:7), Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ: Ọlọ́run kò ṣeé tàn. Nítorí ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.”
Ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ mi dá ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà fún mi, ṣùgbọ́n torí kí ni? Kò sí ìdí kan pàtó! Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé mo ṣe ohun tí kò tọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí pelemọ wà pé ní ìbámu pẹ̀lú Abala Kejìdínlọ́gbọ̀n (28) nínú Òfin Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà, mo ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ohun tí mo ṣe. Mo pa òfin ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà mọ́, mo sì jẹ́ olóòótọ́ èèyàn. Kristẹni ni mí, mo jẹ́ onígbàgbọ́, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Torí kí ni wọ́n ṣe ń fìyà jẹ mí? Kí nìdí tí wọ́n fi jù mí sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà? Kò sí ìdí kan pàtó. Ìwà àìṣòdodo nìyẹn.
Mo nírètí tó dájú pé ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn máa ṣe ohun tí òfin sọ lónìí á sì rí i dájú pé òdodo lékè. Mo nírètí pé ilé ẹjọ́ yìí ló máa fòpin sí inúnibíni torí ẹ̀sìn èyí tó ń wáyé lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà níbí. Mo nírètí tó dájú pé ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yìí máa jẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ pé lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà níbí, òmìnira ẹ̀sìn wà fún gbogbo èèyàn.
Láìpẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ inú Míkà orí kẹrin ẹsẹ ìkẹta àti ìkẹrin (4:3, 4) máa ní ìmúṣẹ. Bíbélì sọ pé: “Ó máa ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn . . . Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀, wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́. Kálukú wọn máa jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”
Ọlọ́run kì í ṣègbè nínú ìdájọ́, tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, ẹjọ́, ìwà ipá àti ogun kò ní sí mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn máa wà. Lédè míì, gbogbo èèyàn máa ní ojúlówó ayọ̀.
Olúwa Mi, tẹ́ ẹ bá ṣe ìpinnu tó tọ́ lónìí, ẹ lé mú ipò iwájú nínú ṣíṣe ohun táá mú káa máa gbé nínú ayé kan tí kò sí ìbẹ̀rù, ìbànújẹ́ àti àìṣòdodo. Mo sì nírètí pé ohun tẹ́ ẹ máa ṣe nìyẹn. Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀!
^ ìpínrọ̀ 11 Dennis fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìtumọ̀ ti ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe. Ṣùgbọ́n, nínú àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ yìí, gbogbo ìwé mímọ́ tá a lò wá látinú ẹ̀dà Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe.