Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mẹ́wàá yìí, pẹ̀lú àwọn mẹ́jọ míì ni wọ́n fi sátìmọ́lé láìtọ́ ní Rọ́ṣíà, bí àwùjọ tó ń rí sí ẹ̀tọ̀ ọmọnìyàn lábẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ṣe sọ, àwọn ni: Andrey Magliv, Igor Egozaryan, Ruslan Korolev, Vladimir Kulyasov, àti Valeriy Rogozin (lápá òkè, láti apá òsì sápá ọ̀tún); Valeriy Shalev, Tatyana Shamsheva, Olga Silayeva, Aleksandr Solovyev, and Denis Timoshin (lápá ìsàlẹ̀, láti apá òsì sápá ọ̀tún)

MAY 18, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Àwùjọ Àwọn Onímọ̀ Ìjìnlẹ̀ Tó Wà Lábẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé Sọ Pé Ìjọba Rọ́ṣíà Ti Tẹ Òfin Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lójú, Bí Wọ́n Ṣe Fi Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjìdínlógún Sátìmọ́lé

Àwùjọ Àwọn Onímọ̀ Ìjìnlẹ̀ Tó Wà Lábẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé Sọ Pé Ìjọba Rọ́ṣíà Ti Tẹ Òfin Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lójú, Bí Wọ́n Ṣe Fi Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjìdínlógún Sátìmọ́lé

Àwùjọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lábẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé kọ ìwé kan tó ní ojú ìwé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15). Nínú ìwé náà, wọ́n sọ pé ìjọba Rọ́ṣíà ti tẹ òfin àwọn orílẹ̀-èdè lójú, bí wọ́n ṣe fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlógún (18) sátìmọ́lé láwọn ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, láti May 2018 sí July 2019. Wọ́n ní kí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́síà dá àwọn ará wa tó wà látìmọ́lé sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí wọ́n sì máa lọ lómìnira.

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà gbé ìpinnu tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe jáde ní May 15, 2020. Wọ́n máa tó gbé ibi tí wọ́n parí ọ̀rọ̀ náà sí jáde lórí ìkànnì Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé.

Ìgbà kẹta rèé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, tí àwùjọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n fi sátìmọ́lé lọ́nà àìtọ́ máa gbèjà àwọn ará wa. Nínú ìwé tí wọ́n kọ kẹ́yìn, wọ́n bẹnu àtẹ́ lu oríṣiríṣi ìwà ìkà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń hù sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

Àwùjọ náà sọ pé, kò sí ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó fi yẹ káwọn ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fipá mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n tún sọ pé, “kò sí ìkankan nínú [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] tó yẹ kí wọ́n fi sátìmọ́lé, kò sì yẹ kí wọ́n gbé ìkankan nínú wọn lọ sí ilé ẹjọ́.”

Àwùjọ náà bẹnu àtẹ́ lu ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Wọ́n ní ohun táwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń ṣe ò ju pé “wọ́n ń lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti máa jọ́sìn láìdí ẹnikẹ́ni lọ́wọ́.”

Nínú ìwé tí wọ́n kọ, wọ́n tún jẹ́ kó ṣe kedere pé bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ẹjọ́ àwọn ará wa nílé ẹjọ̀ kò tọ́ rárá. Bí apẹẹrẹ, inú àhámọ́ ni wọ́n fi àwọn arábìnrin wa méjì sí nílé ẹjọ́ nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ wọn. Nínú àlàyé táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ṣe, wọ́n ní òfin àwọn orílẹ̀-èdè jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀tọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ni “pé kí wọ́n fojú aláìmọwọ́mẹsẹ̀ wò ó, títí wọ́n á fi rí i dájú pé onítọ̀hún jẹ̀bi ẹsùn tí wọ́n fi kàn án.” Torí náà, kò yẹ kí wọ́n fi “ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí àwọn arábìnrin wa lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n fi wọ́n sínú àhámọ́ nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ wọn, torí ìyẹn á jẹ́ káwọn èèyàn máa fi ojú ọ̀daràn paraku wò wọ́n.”

Àwùjọ náà tún sọ pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà wọ́gi lé àkọ́sílẹ̀ ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlógún (18) náà, kí wọ́n sì tún san owó gbà-má-bínú fún wọn, bí òfin àwọn orílẹ̀-èdè ṣe sọ. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ní kí ìjọba orílẹ̀-èdè náà “ṣèwádìí fínnífínní nípa ohun tó mú káwọn aláṣẹ hùwà àìtọ́ yìí,” kí wọ́n sì “gbé ìgbẹ́sẹ̀ lórí àwọn tó ń fi ẹ̀tọ́ [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] dù wọ́n.”

Wọ́n tún sọ nínú ìwé náà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlógún (18) tí wọ́n mú wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ “lára ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Rọ́ṣíà, tí wọ́n fi sátìmọ́lé, tí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ ọ̀daràn, torí pé wọ́n ń lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti máa ṣe ìsìn wọn.” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà wà lára àwọn tó fọwọ́ sí ẹ̀tọ́ yìí nínú àdéhùn táwọn orílẹ̀-èdè ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹjọ́ àwọn ará wa méjìdínlógún (18) ni ìwé tí àwùjọ náà kọ dá lé, wọ́n tún jẹ́ kó ṣe kedere pé ohun tí wọ́n sọ “kan gbogbo àwọn míì tó wà nírú ipò yẹn.”

Kò sí ẹ̀rí tó dájú pé ìwé táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí kọ máa mú kí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dá àwọn ará wa sílẹ̀, àmọ́ a gbà pé ó ṣeé ṣe kó mú kí ọ̀rọ̀ náà yanjú déwọ̀n àyè kan. À ń retí ohun táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà máa ṣe sọ́rọ̀ yìí. Ní báyìí ná, a mọ̀ pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà ní Rọ́ṣíà á máa fara da inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wọn, a sì mọ̀ pé Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́, á jẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀, kí ọkàn wọn sì balẹ̀, torí pé òun ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.​—Róòmù 15:13.