Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arábìnrin Olga Ganusha

JUNE 23, 2021
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Àdúrà Tó Ṣe Pàtó tí Arábìnrin Olga Ganusha Gbà Fún Un Lókun Bó Ṣe Ń Fara Da Inúnibíni

Àwọn Àdúrà Tó Ṣe Pàtó tí Arábìnrin Olga Ganusha Gbà Fún Un Lókun Bó Ṣe Ń Fara Da Inúnibíni

OHUN TÓ TÚN ṢẸLẸ̀ | Ilé Ẹjọ́ ní Rọ́ṣíà Wọ́gi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Ní September 30, 2021, ilé ẹjọ́ Rostov Regional Court wọ́gi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Arábìnrin Ganusha pè. Ẹjọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ dá fún un kò yí pa dà. Wọn ò tíì ní kó lọ sẹ́wọ̀n báyìí.

Ní July 13, 2021, ilé ẹjọ́ Voroshilovskiy District Court of Rostov-on-Don rán Arábìnrin Olga Ganusha lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì, ilé ló ti máa ṣe ẹ̀wọ̀n náà, wọ́n á sì máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀.

Ìsọfúnni Nípa

Olga Ganusha

  • Wọ́n Bí I Ní: 1961 (ní Rostov-on-Don, Agbègbè Rostov)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Òṣìṣẹ́ ìjọba tó ti fẹ̀yìn tì ni, ó sì jẹ́ òbí tó ń dá tọ́ ọmọkùnrin kan. Ó fẹ́ràn kó máa ṣiṣẹ́ ọwọ́, ó máa ń gbọ́ orin, ó sì máa ń ka oríṣiríṣi ìwé

  • Ó pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó mọ̀ pé Ọlọ́run máa jí àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ti kú dìde sínú Párádísè, tí gbogbo wọn á sì jọ máa gbé pọ̀. Ọdún 1995 ló ṣèrìbọmi, tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ìsọfúnni Nípa Ẹjọ́ Yìí

Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2019, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà dọ́gbọ́n lọ fi kámẹ́rà tó ń gba ohùn àtàwòrán sínú ilé Arábìnrin Olga Ganusha. Ìyẹn ni wọ́n fi ṣe ẹ̀rí láti lọ yẹ inú ilé Olga wò ní June 2019. Wọ́n tú àwọn ìwé tó ń kọ nǹkan sí, àwọn lẹ́tà àtàwọn ìwé míì nínú ilé rẹ̀. Wọ́n wá fẹ̀sùn kan Olga lábẹ́ òfin ní August 17, 2020, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀ ní March 4, 2021. Lára ẹ̀sùn “ìwà ọ̀daràn” tí wọ́n fi kàn án ni pé wọ́n ń ṣe ìpàdé ẹ̀sìn nílé ẹ̀, ó ń kópa nínú ìpàdé náà, ó sì tún ń báwọn míì sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́. Wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ Arábìnrin Lyudmila Ponomarenko àti Galina Parkova àti ti Arábìnrin Olga pa pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, àmọ́ ní báyìí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ wọn.

Ní gbogbo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjì tí wọ́n fi ṣèwádìí, tí wọ́n sì fi gbẹ́jọ́ yìí, àwọn àdúrà tó ṣe pàtó tí Olga gbà fún un lókun gan-an. Olga sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mò ń gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ lọ́nà tí ò ṣẹlẹ̀ rí. Mo máa ń gbàdúrà fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n fi sátìmọ́lé, àwọn tó wà lẹ́wọ̀n àtàwọn tí wọ́n sé mọ́lé, kí wọ́n lè máa sọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì nígboyà. Mo máa ń gbàdúrà pé kí ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà má yẹ̀, kó sì máa dá wọn lójú pé Ọlọ́run ò ní fi wọ́n sílẹ̀ nígbà ìṣòro.” Nígbà tí Olga ronú nípa ipò tó wà, ó sọ pé: “Mo bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù, kí n máa gbẹ́kẹ̀ lé e, kó sì sọ mí di òpó irin àti ògiri bàbà bíi ti Jeremáyà. Yàtọ̀ síyẹn, mo fẹ́ fìgoyà kojú inúnibíni tó gbóná yìí bíi tàwọn Hébérù mẹ́ta náà. Mo sì fẹ́ máa hùwà lọ́nà tó fi ọ̀wọ̀ hàn bí Jésù ti ṣe níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú Olga àtàwọn míì tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí torí ìgbàgbọ́ wọn, á sì fi “ọwọ́ ọ̀tún òdodo” rẹ̀ dì wọ́n mú.​—Àìsáyà 41:10.