Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 18, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Aṣòfin Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Dábàá Ojútùú Lórí Ọ̀rọ̀ Arákùnrin Dennis Christensen, Wọ́n Ní Kí Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Dá A Sílẹ̀ Lómìnira

Àwọn Aṣòfin Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Dábàá Ojútùú Lórí Ọ̀rọ̀ Arákùnrin Dennis Christensen, Wọ́n Ní Kí Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Dá A Sílẹ̀ Lómìnira

Méjì lára àwọn ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ṣètò House Resolution 958àwọn ìwé òfin tó dẹ́bi fún orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fún bí wọ́n ṣe fi Arákùnrin wa Dennis Christensen sẹ́wọ̀n láìtọ́. Èyí ni ìwé òfin tó dé gbẹ̀yìn látọ̀dọ̀ àwọn aṣojú ìjọba, tí wọ́n fi dẹ́bi fún orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fún bí wọn ṣe ń gbógun ti àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nítorí ìgbàgbọ́ wọn.

Wọ́n mú Arákùnrin Christensen ní May 2017 torí pé ó lọ sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n. Ní May 8, 2020 Eliot L. Engel àti Michael T. McCaul ṣojú fún Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láti rọ ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pé kí wọn fi Arákùnrin Christensen sílẹ̀ ní kíákíá.

Wọ́n sọ nínú ìwé tí wọ́n kọ pé: “Ní February 6, 2019, wọ́n fi Dennis Christensen ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Denmark sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Òmìnira Ìsìn Lágbàáyé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà bu ẹnu àtẹ́ lu ìdájọ́ yìí,” wọ́n gbà pé ìdájọ́ tí wọ́n ṣe yẹn “jẹ́ ẹ̀rí pé, ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń tẹ ‘ẹ̀tọ́ tàbí òmìnira táwọn èèyàn ní láti jọ́sìn lójú.’”

May 25, 2020, ló máa pé ọdún mẹ́ta tí Arákùnrin Christensen ti wà lẹ́wọ̀n. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin méjìlélọ́gbọ̀n (32) tó wà lẹ́wọ̀n ní Rọ́ṣíà. Mẹ́sàn-án nínú wọn ni wọ́n ti dájọ́ ẹ̀wọ̀n fún, nígbà tí mẹ́tàlélógún (23) wà ní àhámọ́, wọ́n ṣì ń retí ìdájọ́. Láfikún, àwọn méjìdínlógún onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ni wọ́n ṣé mọ́ ilé wọn. Láti 2017, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti gbọn ilé àwọn arákùnrin tó sún mọ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Látàrí èyí, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n (331) àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìjọba Rọ́ṣíà ti fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn.

Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ti Yúróòpù ti bu ẹnu àtẹ́ lu orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fún bí wọ́n ṣe ń gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ìjọsìn.

Bóyá àbá tí àwọn ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin yẹn mú wá méso jáde tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, a mọ̀ pé Jèhófà á máa bá a lọ láti ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kí wọ́n lè fara dàá pẹ̀lú ayọ̀. À ń fojú sọ́nà fún àkókò tí Jèhófà máa mú gbogbo àwọn tó ń “fi òfin bojú láti dáná ìjàngbọ̀n” kúrò.​—Sáàmù 94:20-23.