AUGUST 11, 2020
RỌ́ṢÍÀ
Àwọn Aláṣẹ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti Yúróòpù Dẹ́bi fún Ìjọba Rọ́ṣíà Torí Bí Wọ́n Ṣe Ń Dìídì Ṣenúnibíni Sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àtàwọn ìjọba orílẹ̀-èdè míì tó tó ọgbọ̀n (30) nílẹ̀ Yúróòpù dẹ́bi fún ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà lọ́nà tó lágbára, torí bí wọ́n ṣe ń dìídì ṣenúnibíni sáwọn ará wa, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n. Ibi ìpàdé kan tó wáyé ní July 23, 2020, ni àjọ Ètò Ààbò àti Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ní Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn OSCE) * ti bẹnu àtẹ́ lu ohun tí ìjọba Rọ́ṣíà ń ṣe.
Ìyáàfin Lane Darnell Bahl, tó jẹ́ adelé agbani-nímọ̀ràn fún àjọ OSCE, ẹ̀ka ti Amẹ́ríkà, sọ fáwọn tó wà nípàdé náà pé: “Àwa aṣojú ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ọ̀pọ̀ àwọn míì tó wà níbí lónìí ò ní fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, a ò sì ní yéé dẹ́bi fún ìjọba Rọ́ṣíà torí ìròyìn tá à ń gbọ́ nípa bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń túlé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìtọ́, bí wọ́n ṣe ń tì wọ́n mọ́lé láìyẹ, tí wọ́n ń rán wọn lọ sí ẹ̀wọ̀n tó tó ọdún mẹ́fà, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n láìnídìí.”
Ọ̀kan lára ohun tó ká àwọn aláṣẹ tó wà nípàdé yẹn lára jù ni ti ìròyìn tí wọ́n gbọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa bí àwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà ṣe lọ tú ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) lágbègbè Voronezh. Ìyáàfin Bahl sọ pé: “Inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn kọjá àfẹnusọ, bẹ́ẹ̀ èèyàn àlàáfíà ni wọ́n, iye wọn ò sì tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹlẹ́sìn yòókù.”
Ìyáàfin Nicola Murray, tó jẹ́ igbákejì aṣíwájú Ẹ̀ka ti United Kingdom (UK), náà sọ pé ó ká òun lára bóun ṣe ń gbọ́ tí “iye ilé táwọn ọlọ́pàá ń tú lẹ́ẹ̀kan náà ṣe ń pọ̀ sí i, ṣe nìyẹn sì fi hàn pé wọ́n dìídì dájú sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.” Ìyáàfin Murray tún sọ pé: “Ohun tó pọn dandan kí àwọn ẹlẹ́sìn máa ṣe déédéé ni àwọn aláṣẹ sọ di ẹ̀sùn sí ẹlẹ́sìn yìí lọ́rùn, tí wọ́n fi ń pè wọ́n lẹ́jọ́.”
Yàtọ̀ síyẹn, Ìyáàfin Bahl sọ pé irọ́ lẹ̀sùn táwọn aláṣẹ Voronezh fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé “ọlọ̀tẹ̀” ni wọ́n, tí wọ́n sì tìtorí ẹ̀ fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Àwọn ìsọfúnni àtàwọn ìròyìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tọ́jú sórí ẹ̀rọ, àti bí wọ́n ṣe ń ṣètò àwọn ará wọn, tí wọ́n sì ń fi fídíò orí íńtánẹ́ẹ̀tì ṣèpàdé ni àwọn aláṣẹ rí tí wọ́n fi ń pè wọ́n ní ọlọ̀tẹ̀. Ìyáàfin Bahl sọ pé ẹ̀sùn táwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí “ṣàjèjì,” àti pé “àwọn aláṣẹ yẹn ò nítìjú.” Ó sọ pé: “Gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀sùn ẹ̀ kàn wọ́n yìí, lèmi náà máa ń ṣe lójoojúmọ́.” Ó tún sọ pé, tí àwọn Aṣojú Ìjọba Rọ́síà bá lè fi fídíò orí íńtánẹ́ẹ̀tì dara pọ̀ mọ́ ìpàdé àjọ OSCE láti orílẹ̀-èdè wọn, a jẹ́ pé “àwọn náà jẹ̀bi ẹ̀sùn” tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn.
Nínú ìròyìn kan, * àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) tó wà nínú Àjọ Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn EU) sọ pé: “Kì í ṣẹ̀ẹ̀kan, kì í ṣẹ̀ẹ̀mejì tá a ti gbọ́ tí àwọn Aṣojú Ìjọba Rọ́ṣíà ti sọ nípàdé àjọ yìí pé àwọn fọwọ́ sí i káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe ẹ̀sìn wọn fàlàlà, àti pé òfin ilẹ̀ Rọ́ṣíà fọwọ́ sí i káwọn aráàlú lómìnira ẹ̀sìn. Àmọ́ a ṣì ń gbọ́ oríṣiríṣi ìròyìn nípa àwọn ọlọ́pàá tó ń túlé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ń fi wọ́n sátìmọ́lé, tí wọ́n sì ń fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n. Ṣe làwọn Aṣojú Ìjọba Rọ́ṣíà ń kó ọ̀rọ̀ ara wọn jẹ pẹ̀lú ohun tí wọ́n ń ṣe yìí.”
Àjọ Ilẹ̀ Yúróòpù tún sọ pé: “Gbogbo èèyàn, tó fi mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló gbọ́dọ̀ láǹfààní láti gbádùn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, bí ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀sìn, òmìnira láti kóra jọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Ìjọba ò gbọ́dọ̀ ṣẹ̀tanú ẹnikẹ́ni, torí ohun tí Òfin Ilẹ̀ Rọ́síà sọ náà nìyẹn, bó sì ṣe wà nínú àdéhùn tí ìjọba ilẹ̀ náà tọwọ́ bọ̀ lábẹ́ àjọ OSCE nìyẹn, tó fi mọ́ àdéhùn míì nínú òfin ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé.”
Ìyáàfin Murray tó ń ṣojú fún United Kingdom wá fi àkókò náà sọ fún ìjọba Rọ́síà pé kí wọ́n fòpin sí inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ìyáàfin Bahl rọ àwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà pé: (1) kí wọ́n yéé fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, (2) kí wọ́n dá oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé pa dà fún wọn, kí wọ́n sì (3) dá gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí táwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè míì máa bẹnu àtẹ́ lu ohun tí ìjọba Rọ́ṣíà ń ṣe fáwọn ará wa. Kódà ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ itú táwọn aláṣẹ Rọ́ṣíà ń pa, torí gbogbo ayé ló mọ̀ pé wọ́n ń fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbolẹ̀. Àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, Jèhófà mọ ohun táwọn ará wa ní Rọ́ṣíà ń dojú kọ. (Sáàmù 37:18) Ó dájú pé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ á máa bù kún wọn torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́, wọ́n nígboyà, wọ́n sì nífaradà.—Sáàmù 37:5, 28, 34.
^ ìpínrọ̀ 2 Ọ̀kan lára iṣẹ́ àjọ OSCE ni láti gbèjà ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn aráàlú. Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ààbò ló máa ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú ìpinnu tí àjọ OSCE ń ṣe.
^ ìpínrọ̀ 7 Àkọsílẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ò tíì dórí ìkànnì. Tó bá ti débẹ̀, a máa fi ìlujá rẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú àpilẹ̀kọ yìí.