Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn ọlọ́pàá àtàwọn Federal Security Service (FSB) fẹ́ wọ ilé ọ̀kan lára àwọn ará wa ní Nizhny Novgorod lọ́dún 2019

JULY 15, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Aláṣẹ Tú Ilé Tó Tíì Pọ̀ Jù Tó Jẹ́ Tàwọn Ará Wa Lọ́jọ́ Kan Ṣoṣo ní Rọ́ṣíà

Àwọn Aláṣẹ Tú Ilé Tó Tíì Pọ̀ Jù Tó Jẹ́ Tàwọn Ará Wa Lọ́jọ́ Kan Ṣoṣo ní Rọ́ṣíà

A gbọ́ ìròyìn pé ní July 13, 2020, àwọn ọlọ́pàá tó gbé ìbọn dání lọ tú ilé àwọn ará wa tí iye wọn jẹ́ àádọ́fà (110) tó ń gbé lágbègbè Voronezh. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí látọdún 2017 tí iye ilé táwọn ọlọ́pàá máa tú lọ́jọ́ kan máa pọ̀ tó yìí. Wọ́n lu Arákùnrin Aleksandr Bokov àti Arákùnrin Dmitrii Katyrov, wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n gan-an torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣí fóònù wọn fún àwọn ọlọ́pàá.

Ilé Ejọ́ Leninsky ní Voronezh ló ní káwọn ọlọ́pàá yẹn lọ tú ilé àwọn ará wa. Ó kéré tán, ìlú méje, títí kan àwọn abúlé tí àwọn ará wa ń gbé lágbègbè náà làwọn ọlọ́pàá náà dé. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni wọ́n mú lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ tó ń ṣèwádìí kí wọ́n lè wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn.

Lọ́jọ́ kejì, ìyẹn ní July 14, 2020, Ilé Ẹjọ́ Leninsky sọ pé kí wọ́n fi àwọn arákùnrin mẹ́wàá sátìmọ́lé kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ wọn ní September 3, 2020. Àwọn arákùnrin náà ni: Aleksei Antiukhin, ẹni ọdún 44, Sergey Bayev, ẹni ọdún 47, Iurii Galka, ẹni ọdún 44, Valeriy Gurskiy, ẹni ọdún 56, Vitalii Nerush, ẹni ọdún 41, Stepan Pankratov, ẹni ọdún 24, Igor Popov, ẹni ọdún 54, Evgenii Sokolov, ẹni ọdún 44, Mikhail Veselov, ẹni ọdún 51 àti Anatoliy Yagupov, ẹni ọdún 51.

Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ìròyìn tá a gbọ́ ni pé àádọ́fà (110) ni iye ilé àwọn ará wa táwọn ọlọ́pàá lọ tú, àmọ́ títí di báyìí, ọgọ́rùn-ún (100) ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣì rí àrídájú pé wọ́n tú ilé wọn. Iye yẹn ṣì lè pọ̀ sí i tó bá yá. Kò rọrùn láti kàn sí gbogbo àwọn ará tọ́rọ̀ kàn torí pé àwọn ọlọ́pàá ti gba fóònù àti kọ̀ǹpútà wọn.

Ṣáájú àkókò yìí, February 10, 2020 ni iye ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táwọn aláṣẹ tú tíì pọ̀ jù. Lọ́jọ́ yẹn, àádọ́ta (50) ilé ni wọ́n tú ní agbègbè Transbaikal. Látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti fòfin de iṣẹ́ wa ní 2017, ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ilé àwọn ará tí wọ́n ti tú palẹ̀.

Inúnibíni tó le gan-an táwọn ará wa ń kojú ní Rọ́ṣíà àtàwọn ilẹ̀ míì ò yà wá lẹ́nu, torí a mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ń ṣẹ. A ò ní yéé gbàdúrà fáwọn ará wa, ó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́.—1 Pétérù 4:12-14, 19.