Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Oleg Postnikov àti Agnessa ìyàwó rẹ̀

DECEMBER 23, 2021
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Ohun Tí Jèhófà Pèsè Fi Ìdílé Postnikov Lọ́kàn Balẹ̀

Àwọn Ohun Tí Jèhófà Pèsè Fi Ìdílé Postnikov Lọ́kàn Balẹ̀

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

  1. Ilé ẹjọ́ Birobidzhan District ti Jewish Autonomous Region máa tó kéde ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Oleg Postnikov àti Arábìnrin Agnessa Postnikova. Agbẹjọ́rò ìjọba tó fẹ̀sùn kàn wọ́n ò tíì sọ ìyà tó fẹ́ kí wọ́n fi jẹ wọ́n

  2. February 12, 2021

    Àwọn ọlọ́pàá fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Agnessa. Wọ́n fẹ̀sùn kan ìdílé Postnikovs pé wọ́n ń dá ẹgbẹ́ “ọ̀daràn” sílẹ̀, wọ́n sì ń rọ àwọn míì pé kí wọ́n di “agbawèrèmẹ́sìn.” Wọ́n wá pàṣẹ fún Oleg àti Agnessa pé wọn ò gbọ́dọ̀ fi àdúgbò yẹn sílẹ̀, wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n rí owó tí wọ́n tọ́jú sílé ìfowópamọ́ gbà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n fi orúkọ wọn kún orúkọ àwọn afẹ̀míṣòfò tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

  3. February 12, 2020

    Àwọn ọlọ́pàá fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Oleg

Ìsọfúnni Ṣókí

Irú àwọn ìrírí báyìí ń jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ń ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí i láìka àdánwò yòówù kí wọ́n kojú sí. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa túbọ̀ máa gbára lé ‘ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀.’—Sáàmù 115:1.