FEBRUARY 21, 2022
RỌ́ṢÍÀ
Ìṣírí Táwọn Ará Fún Wọn Mú Kí Ìgbàgbọ́ Wọn Lágbára
Ilé Ẹjọ́ Petrozavodsk ti Republic of Karelia máa tó kéde ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn arákùnrin wa mẹ́rin, ìyẹn Maksim Amosov, Mikhail Gordeev, Nikolay Leshchenko àti Dmitriy Ravnushkin. Agbẹjọ́rò tó ń ta kò wọ́n ò tíì sọ ìyà tó fẹ́ kí ìjọba fi jẹ wọ́n.
Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀
July 31, 2019
Àwọn ọlọ́pàá tú ilé àti ibi iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìndínlógún (16)
August 2, 2019
Ẹni tó ń ṣèwádìí ò gbà kí Maksim fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀. Àwọn aláṣẹ fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Nikolay, wọ́n sì pàṣẹ fún un pé kò gbọ́dọ̀ fi àdúgbò ẹ̀ sílẹ̀
August 6, 2019
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Maksim àti Nikolay ni pé wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
September 5, 2019
Àwọn ọlọ́pàá mú Mikhail níbi tó ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n sì gba kọ̀ǹpútà rẹ̀. Ẹni tó ń ṣèwádìí wá fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan Mikhail
September 20, 2019
Àwọn ọlọ́pàá wá tú ibi tí Dmitriy ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n sì gba fóònù rẹ̀. Ẹni tó ń ṣèwádìí fọ̀rọ̀ wá Dmitriy lẹ́nu wò fún wákàtí mẹ́rin. Lẹ́yìn náà, ó fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kàn án, ó sì pàṣẹ pé kò gbọ́dọ̀ kúrò ní àdúgbò ẹ̀
October 18, 2021
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ wọn
Ìsọfúnni Ṣókí
Inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí i pé àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà ń rìn nínú òtítọ́ láìka àtakò sí.—3 Jòhánù 4.