Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n ń mú Arákùnrin Dennis Christensen lọ sí ilé ẹjọ́ agbègbè Zheleznodorozhniy nílùú Oryol

JULY 31, 2019
RỌ́ṢÍÀ

ÌRÒYÌN LỌ́Ọ́LỌ́Ọ́—Wọ́n Ti Gbé Dennis Christensen Lọ Sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Tó Wà Ní Àdádó, Síbẹ̀ Ó Ṣì Jẹ́ Olóòótọ́

ÌRÒYÌN LỌ́Ọ́LỌ́Ọ́—Wọ́n Ti Gbé Dennis Christensen Lọ Sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Tó Wà Ní Àdádó, Síbẹ̀ Ó Ṣì Jẹ́ Olóòótọ́

Ní June 6, 2019, ìyẹn ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí Arákùnrin Dennis Christensen pàdánù ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó pè, àwọn alákòóso Rọ́ṣíà gbé e láti yàrá ìtìmọ́lé tó wà ṣáájú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ní Oryol, lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní àdádó, ìyẹn Penal Colony No. 3 nílùú Lgov. Ìlú Lgov jìn tó igba (200) kìlómítà sí ibi tí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Dennis ń gbé ní Oryol.

Nígbà tí Dennis kọ́kọ́ dé ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, wọ́n fi àbùkù kàn án, wọ́n sì gbìyànjú láti mú kó sẹ́ ìgbàgbọ́ ẹ̀. Àmọ́, ṣe ni Dennis gbára lé Jèhófà pátápátá, ó sì fi hàn pé òun jẹ́ alágbára àti onígboyà.​—⁠1 Pétérù 5:⁠10.

Ní Finland (láti apá òsì sí apá ọ̀tún): Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, Irina Christensen, àti Tommi Kauko láti Finland

Látìgbà tí wọ́n ti ti Dennis mọ́lé ni àwọn ara ti ń ti ìyàwó ẹ̀, Irina, lẹ́yìn tí wọ́n sì ń fi ìfẹ́ bójú tó o.  Ní June, Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti àwọn arákùnrin míì tó ń mú ipò iwájú ṣètò bí wọ́n ṣe pàdé Irina ní Finland ki wọ́n lè fún un níṣìírí.

Ó ti tó oṣù kan báyìí tí Dennis tí wà lẹ́wọ̀n yìí. Láìpẹ́ yìí ni wọ́n gba Irina láàyè láti máa bá Dennis sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ lórí fóònù. Wọ́n tún ti fọwọ́ sí i pé kó máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Dennis ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Irina ń tún àwọn lẹ́tà tó ń fúnni níṣìírí tí Dennis kọ sí i kà

Pẹ̀lú gbogbo ohun tí Dennis àti Irina ti fara dà fún ọdún méjì sẹ́yìn, ìyẹn láti igba tí wọ́n ti mú u tí wọn sì tì í mọ́lé, síbẹ̀ wọ́n dúró láìyẹsẹ̀, wọ́n sì ń láyọ̀. Irina sọ pé àwọn lẹ́tà tí Dennis ń kọ sí òun lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ máa ń gbé òun ro gan an ni. Ọ̀kan wà lára àwọn lẹ́tà yẹn ti Irina fẹ́ràn gan an. Dennis kọ̀wé pé: “A máa ṣàṣeyọrí tá a bá ń fi ojú tó tọ́ wo nǹkan, bẹ́ẹ̀ sì rèé àìmọye nǹkan tó ń fún wa láyọ̀ la ní.” Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí: “Torí ká lè fi hàn pé Jèhófà la fara mọ́ pé kó jẹ́ Ọba Aláṣẹ la ṣe wà láyé. Mo mọ̀ pé ọnà wa ṣì jìn, a ò sì tíì ṣẹ́gun. Àmọ́, mo mọ̀ pé bó pẹ́ bóyá, à máa ṣẹ́gun. Ìyẹn dá mi lójú hán-ún hán-ún.”

Ní July 21, ní àpéjọ àgbáyé tí wọ́n ṣe ní Denmark, Arákùnrin Lett tó jẹ́ ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ka lẹ́tà kan tí Dennis kọ. Apá kan nínú lẹ́tà náà sọ pé: “Ó wù mí kí n wà pẹ̀lú yín ní àpéjọ yìí, ṣùgbọ́n ìyẹn ò ṣeéṣe báyìí torí pé mi ò tíì parí iṣẹ́ tí a yàn fún mi. Àmọ́, ó máa ṣeéṣe lọ́jọ́ iwájú, mo sì ń wọ̀nà fún un.”

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní àtìmọ́lé ní Róòmù, ó kọ̀wé pé: “Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín nínú gbogbo ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi lórí gbogbo yín. Inú mi máa ń dùn ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀,. . .  ọ̀rọ̀ yín ń jẹ mí lọ́kàn, ẹ sì jẹ́ alájọpín pẹ̀lú mi nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi àti nínú bí a ṣe ń gbèjà ìhìn rere, tí a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.”​—Fílípì 1:​3, 4, 7.