Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Méjì lára ilé ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé ní St. Petersburg; ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tẹ́lẹ̀ ní Solnechnoye (apá òsì) àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ tá a ń lò tẹ́lẹ̀ ní Kolomyazhskiy (apá ọ̀tún)

JULY 4, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ìjọba Rọ́ṣíà Gbẹ́sẹ̀ Lé Dúkìá Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Iye Rẹ̀ Ju Mílíọ̀nù Mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) Owó Dọ́là Lọ

Ìjọba Rọ́ṣíà Gbẹ́sẹ̀ Lé Dúkìá Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Iye Rẹ̀ Ju Mílíọ̀nù Mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) Owó Dọ́là Lọ

Látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní April 20, 2017, ni wọ́n ti ń ṣenúnibíni sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, tí wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Àtìgbà náà làwọn aláṣẹ ti gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye rẹ̀ tó mọ́kànléláàádóje (131). Wọ́n sì tún ń sapá láti gbẹ́sẹ̀ lé ọgọ́ta (60) dúkìá míì. Àròpọ̀ gbogbo dúkìá náà ju mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) owó dọ́là lọ.

Ọ̀kan lára ohun ìní tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ni ilé Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania tó wà ní Solnechnoye, ìyẹn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Rọ́ṣíà tẹ́lẹ̀. (wo àwòrán tó wà lókè lápá òsì.) Tá a bá ṣírò iye tí ilé yìí nìkan jẹ́, ó tó ọgbọ̀n (30) mílíọ̀nù owó dọ́là. Dúkìá mẹ́tàlélógójì (43) míì tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé jẹ́ ti àjọ ilẹ̀ òkèèrè tá a gbé kalẹ̀ lábẹ́ òfin tó wà ní Austria, Denmark, Finland, Netherlands, Nọ́wè, Pọ́túgà, Sípéènì, Sweden, àti Amẹ́ríkà. Òótọ́ ni pé Ilé Ẹjọ́ Gíga ti fòfin dé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ìyẹn ò fún ìjọba láṣẹ láti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun ìní wa tó jẹ́ ti ilẹ̀ òkèèrè, torí náà bí wọ́n ṣe gba àwọn dúkìá náà kò bófin mu.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) lórí bí ìjọba ṣe gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì tá à ń lò ní Rọ́ṣíà tẹ́lẹ̀. Ìpinnu yòówù kí ECHR ṣe, Jèhófà la fọkàn tán, òun la sì gbára lé. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fún àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà lókun kí wọ́n lè máa fìgboyà sin Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” láìka bí ìjọba ṣe ń dà wọ́n láàmù, tí wọ́n ń mú wọ́n, tí wọ́n sì ń gbẹ́sẹ̀ lé àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa.​—Jòhánù 4:23.