OCTOBER 14, 2019
RỌ́ṢÍÀ
Ọ̀rọ̀ Àsọkágbá Arákùnrin Valeriy Moskalenko
Ní Friday, August 30, 2019, Arákùnrin Valeriy Moskalenko sọ ọ̀rọ̀ àsọkágbá rẹ̀ fún ilé ẹjọ́. Díẹ̀ rèé (tá a túmọ̀ láti èdè Rọ́ṣíà) lára ọ̀rọ̀ tó sọ níwájú ilé ẹjọ́:
Ọ̀gá Àgbà àti gbogbo ẹ̀yin ọlọ́lá tó wà níkàlẹ̀, ọmọ ọdún méjìléláàádọ́ta (52) ni mí, ọdún tó kọjá yìí ni wọ́n fi mí sí àtìmọ́lé. Tàbí kí n kúkú sọ ní tààràtà pé ó ti lé ní ọdún kan báyìí.
Nínú ọ̀rọ̀ àsọkágbá mi fún ilé ẹjọ́ yìí, mo fẹ́ ṣàlàyé ṣókí fún yín nípa ara mi, ojú tí mo fi wo ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn mí àti ọwọ́ tí mo fi mú ìwàláàyè. Ọ̀gá Àgbà, mo nírètí pé ẹ máa lóye ìdí ti mi ò fi ní sẹ́ ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú Ọlọ́run àti ìdí tí kò fi sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú kéèyàn gba Ọlọ́run gbọ́.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ni mí látilẹ̀ wá. Èèyàn rere làwọn òbí mi wọ́n sì kọ́ mi dáadáa, síbẹ̀ látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ló ti máa ń dùn mí pé ìwà ìrẹ́jẹ kún ibi gbogbo. Mo máa ń ronú pé, ‘Kì í ṣe bó ṣe yẹ kí nǹkan rí nìyí. Àwọn ẹni ibi àtàwọn ẹlẹ́tàn ń gbèrú, àwọn olóòótọ́ àti ẹni rere sì ń jìyà.’
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlélógún (24), mo ṣèwádìí gan-an nínú Bíbélì fún ọ̀pọ̀ oṣù, mo sì rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi.
Àtìgbà yẹn ló ti jẹ́ pé kí n tó ṣe ìpinnu, mo kọ́kọ́ máa ń ronú nípa ojú tí Ọlọ́run á fi wo ohun tí mo fẹ́ ṣe, màá sì tún ronú nípa àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀. [Bíbélì] ṣàlàyé àwọn òfin àti ìlànà náà ní kíkún, èèyàn sì lè mọ púpọ̀ sí i nípa wọn téèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn tó sin Ọlọ́run nígbà àtijọ́.
Inú ilé kan náà ni èmi àti màmá mi ń gbé. Wọ́n ti dàgbà, ó sì yẹ kí n máa tọ́jú wọn. Ní August 1, 2018, nígbà tí màmá mi nìkan wà nínú ilé, Àwọn Òṣìṣẹ́ Aláàbò ti Ìjọba (FSB) tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí sọ fún Àwọn Ọlọ́pàá Àkànṣe pé kí wọ́n fi ayùn rẹ́ ilẹ̀kùn iwájú ìta ilé wa kúrò lára férémù. Ọ̀nà tí ẹni tó wá ṣèwádìí náà yàn láti gbà wọnú ilé mí nìyẹn o.
Ẹ̀rù ba màmá mi gan-an. Lẹ́yìn tí Àwọn Ọlọ́pàá Àkànṣe tó da aṣọ bojú náà já wọnú ilé wa, àyà màmá mi jà débi pé wọ́n ní àrùn ọkàn, wọ́n sì ní láti pe áńbúláǹsì kó wá gbé wọn. Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yìn tí mo gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá ti lọ sí ilé wa ni mo pa dà délé. Nígbà tí mo rí ipò tí màmá mi wà, ìfúnpá tèmi náà ga sí i. Láìka gbogbo èyí sí, mi ò fi ṣèbínú, ṣe ni mo fọwọ́ wọ́nú. Mò ń fi ìfẹ́ hùwà, bó ṣe yẹ kí Kristẹni ṣe. Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run mi fi kọ́ mi nìyẹn, mi ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa mú un bínú.
Ẹ forí jì mí, Ọ̀gá Àgbà, èmi kì í sọ̀rọ̀ nípa ara mi tó báyìí. Kì í ṣe ìwà mi, àmọ́ ó di dandan kí n sọ̀rọ̀ báyìí.
Ó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ̀sìn tí mo fi èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé mi ṣe nìyẹn. Látìgbà tí mo sì ti ń ṣe ẹ̀sìn náà, kò sẹ́ni tó kà mí sí agbawèrèmẹ́sìn rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, aládùúgbò rere làwọn èèyàn mọ̀ mí sí, ẹni tó ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ àti ọmọ tó ń tọ́jú òbí ẹ̀.
Ṣàdédé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pè mí ní agbawèrèmẹ́sìn láti April 20, 2017. Torí kí ni? Ìwà búburú wo ní wọ́n bá lọ́wọ́ mi? Ṣé mo ti ń hùwà àìdáa ni? Rárá o. Ṣé mo ti di oníwà ipá ni àbí mo ti di ẹni tó ń fi ìyà jẹ àwọn míì tó sì ń fa ìrora fún wọn? Rárá o. Ṣé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti jàǹfààní ohun tí Abala Kejìdínlọ́gbọ̀n nínú Òfin Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà sọ ni? Rárá nìyẹn náà. Orúkọ mi ò sí lára àwọn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbọ́ ẹjọ́ wọn. Kò sẹ́ni tó gba ẹ̀tọ́ àtilo Òfin Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà lọ́wọ́ mi, pàápàá jù lọ Abala Kejìdínlọ́gbọ̀n. Kí ló wá sọ mí di ẹni tó ń jẹ́jọ́ nílé ẹjọ́?
Nínú ọ̀rọ̀ tí èmi àti olùṣèwádìí jọ sọ, ó túbọ̀ ṣe kedere pé torí pé mo gba Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè gbọ́ mo sì ń lo orúkọ rẹ̀ nínú àdúrà àti ọ̀rọ̀ mi ni wọ́n ṣe mú mi tí wọ́n sì fi mí sí àtìmọ́lé. Àmọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ò sí nínú ìyẹn. Ọlọ́run ló sọ ara rẹ̀ lórúkọ, tó sì rí i dájú pé orúkọ náà wà nínú Bíbélì.
Mò ń sọ ọ́ léraléra pé mi ò ní ta ko ohun tí Ọlọ́run bá pa láṣẹ lọ́nà tó ṣe kedere nínú Bíbélì. Bó sì ti wù kéèyàn yọ mí lẹ́nu tàbí kó jẹ mí níyà tó, kódà tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún mi, mo fẹ́ kó di mímọ̀ pé mi ò ní fi Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run sílẹ̀ láé.
Ọ̀gá Àgbà, ibi gbogbo kárí ayé ni wọ́n ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ẹni tó dùn ún bá rìn àti ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kárí ayé, wọ́n kì í fi ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti gba Ọlọ́run gbọ́ dù wọ́n. Ó máa wù mí pé ká má ṣe fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dù wọ́n ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà náà, kò sì ní yẹ kí ilé ẹjọ́ yìí fi ẹ̀tọ́ tí mo ní láti gba Ọlọ́run gbọ́ dù mí.
Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí, mo sì rọ ilé ẹjọ́ yìí láti má ṣe dá mi lẹ́bi!
Ẹ ṣeun!