Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Arákùnrin Konstantin Bazhenov, Snezhana ìyàwó ẹ̀ àti Arábìnrin Vera Zolotova

SEPTEMBER 21, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Dẹ́bi fún Arákùnrin Konstantin Bazhenov, Ìyàwó Ẹ̀ àti Arábìnrin Kan Tó Jẹ́ Ẹni Ọdún Mẹ́tàléláàádọ́rin Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Dẹ́bi fún Arákùnrin Konstantin Bazhenov, Ìyàwó Ẹ̀ àti Arábìnrin Kan Tó Jẹ́ Ẹni Ọdún Mẹ́tàléláàádọ́rin Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Ìdájọ́

Ní September 25, 2020, * Ilé Ẹjọ́ Yelizovsky tó wà lágbègbè Kamchatka pinnu láti kéde ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Konstantin Bazhenov, Snezhana ìyàwó ẹ̀, àti Arábìnrin Vera Zolotova. Àwọn alátakò ní kílé ẹjọ́ gba owó ìtanràn tó ju mílíọ̀nù mẹ́ta náírà lọ́wọ́ Arákùnrin Bazhenov àti ìyàwó ẹ̀, wọ́n sì ní kí Arábìnrin Zolotova san nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì náírà.

Ìsọfúnni Ṣókí

Konstantin Bazhenov

  • Wọ́n Bí I Ní: 1977 (ní ìlú Petropavlovsk-Kamchatsky, lágbègbè Kamchatka)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Òun ni àkọ́bí nínú ọmọ márùn-ún. Ó ti ṣiṣẹ́ mẹkáníìkì rí, ó sì ti ṣiṣẹ́ olùkọ́ nígbà kan rí níléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́. Ó gbádùn kó máa pẹja

  • Lọ́dún 2001, ó fẹ́ Snezhana tóun náà jẹ́ olùkọ́ nígbà yẹn. Wọ́n ní ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Elizabeth. Gbogbo wọn jọ ń sin Jèhófà

Snezhana Bazhenova

  • Wọ́n Bí I Ní: 1977 (ní ìlú Shikotan Island tó wà ní Sakhalin Oblast)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Òbí tó ń dá tọ́mọ ló tọ́ ọ dàgbà. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé, torí náà ó fẹ́ràn láti máa kọ́ àwọn ọmọ iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án ò jẹ́ kó lè máa ṣiṣẹ́ yìí mọ́

  • Ìyá ẹ̀ àgbà ló kọ́ ọ nípa Ọlọ́run àti bá ṣe máa gbàdúrà. Ìyẹn ló sì jẹ́ kó wù ú láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kó sì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Vera Zolotova

  • Wọ́n Bí I Ní: 1946 (ní ìlú Yelizovo, lágbègbè Kamchatka)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ìdílé tó tóbi gan-an ló ti wá. Òun àti Yuri Zolotov fẹ́ra lọ́dún 1966, wọ́n sì bí ọmọ méjì. Iṣẹ́ ìṣirò owó ló ń ṣe, ó sì ti fẹ̀yìn tì báyìí. Ó fẹ́ràn kó máa gbafẹ́ lọ sáwọn òkè àtàwọn ibi tó rẹwà, kó sì máa ṣeré lórí yìnyín

  • Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi lọ sí oríṣiríṣi ilé ìjọsìn, torí ó ń wá bó ṣe máa túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Àmọ́ inú ẹ̀ dùn gan-an nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé onídàájọ́ òdodo ni Ọlọ́run àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ọkọ ẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ ó mọyì bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ń mú kíyàwó ẹ̀ túbọ̀ níwà tó dáa

Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ sí Wọn Tẹ́lẹ̀

Ní August 19, 2018, àwọn ọlọ́pàá ya wọ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta nílùú Yelizovo. Wọ́n sì mú àwọn arákùnrin àti arábìnrin mọ́kànlá (11). Ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n fi fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Nígbà tó yá, wọ́n tú mẹ́jọ lára wọn sílẹ̀. Àmọ́ àwọn agbófinró fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Arákùnrin Bazhenov, Arábìnrin Bazhenov àti Arábìnrin Zolotova. Wọ́n pinnu láti fi wọ́n sátìmọ́lé fún ọjọ́ mélòó kan. Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ méjì, wọ́n tú àwọn arábìnrin yẹn sílẹ̀. Adájọ́ kan pàṣẹ pé kí wọ́n ṣì fi Arákùnrin Bazhenov sílẹ̀ sátìmọ́lé. Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ, wọ́n tú òun náà sílẹ̀.

Bá a ṣe ń dúró dìgbà tí wọ́n máa dá ẹjọ́ Arákùnrin Bazhenov, Arábìnrin Bazhenov àti Arábìnrin Zolotova, àdúrà wa ni pé kí wọ́n túbọ̀ gbára lé Jèhófà pátápátá, kí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún àwọn adúróṣinṣin ní ayọ̀ àti àlàáfíà, á sì jẹ́ kí ìrètí wọn “túbọ̀ dájú nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́.”​—Róòmù 15:13.

^ ìpínrọ̀ 3 Ó ṣeé ṣe kó yí pa dà