Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin àti Arábìnrin Polyakov (lápá òsì) Arábìnrin Bektemirova (òkè lápá ọ̀tún) àti Arábìnrin Dyusekeyeva (ìsàlẹ̀ lápá ọ̀tún)

SEPTEMBER 25, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Dẹ́bi fún Tọkọtaya Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Fi Sátìmọ́lé ní Rọ́ṣíà Pẹ̀lú Àwọn Arábìnrin Méjì Míì

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Dẹ́bi fún Tọkọtaya Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Fi Sátìmọ́lé ní Rọ́ṣíà Pẹ̀lú Àwọn Arábìnrin Méjì Míì

Ìdájọ́

Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Pervomayskiy nílùú Omsk ti pinnu láti kéde ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Sergey Polyakov, Anastasia ìyàwó ẹ̀, Arábìnrin Gaukhar Bektemirova àti Arábìnrin Dinara Dyusekeyeva ní October 21, 2020. * Ohun táwọn alátakò ń fẹ́ ni pé kílé ẹjọ́ fi Arákùnrin Polyakov sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà àtààbọ̀. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ní káwọn arábìnrin mẹ́ta tó kù wà nílé fún ọdún méjì, kí àwọn agbófinró sì máa ṣọ́ wọn.

Ìsọfúnni Ṣókí

Sergey Polyakov

  • Wọ́n Bí I Ní: 1972 (ní Agbègbè Murmansk)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ó lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, ó sì di onímọ̀ nípa ìtànṣán (radiophysicist). Ó fẹ́ Anastasia lọ́dún 2003

Anastasia Polyakova

  • Wọ́n Bí I Ní: 1984 (ní Agbègbè Murmansk)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ó kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin nílé ẹ̀kọ́ gíga. Òun àti Sergey gbádùn kí wọ́n máa kọ́ èdè tuntun, bí àpẹẹrẹ wọ́n kọ́ Chinese, Kazakh, Serbian àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Rọ́ṣíà

Gaukhar Bektemirova

  • Wọ́n Bí I Ní: 1976 (ní Uryl, lórílẹ̀-èdè Kazakhstan)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Òun ni àbígbẹ̀yìn nínú ọmọ mẹ́fà. Apá ibi tí òkè wà ní Kazakhstan ló gbé dàgbà, ó sì fẹ́ràn kó máa wo àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá. Ọjọ́ pẹ́ tó ti fẹ́ mọ ohun tó mú kí Ọlọ́run dá àwa èèyàn. Nígbà tó yá, ó rí ìdáhùn tó mọ́gbọ́n dání, tó sì tẹ́ ẹ lọ́rùn látinú Bíbélì. Ní báyìí tó ń kojú inúnibíni, ohun tó ń fún un lókun, tó sì ń tù ú nínú ni pé ó ti kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ látinú Bíbélì

Dinara Dyusekeyeva

  • Wọ́n Bí I Ní: 1982 (ní Leningradskove, lórílẹ̀-èdè Kazakhstan)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Àtikékeré ló ti ń ronú nípa ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn sáyé. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó mọyì ohun tó kọ́, inú ẹ̀ sì dùn gan-an nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run àti pé òun ni Òǹṣèwé Bíbélì. Ó fẹ́ràn kó máa sáré, kó máa wa kẹ̀kẹ́, kó máa gbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ àti bọ́ọ̀lù ọlọ́wọ́

Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ sí Wọn Tẹ́lẹ̀

Lálẹ́ July 4, 2018, ṣe ni Arákùnrin Polyakov àti Anastasia ìyàwó ẹ̀ ń sùn nígbà táwọn agbófinró tó di ìhámọ́ra, tí wọ́n sì fi nǹkan bojú já wọ ilé wọn. Wọ́n lu Arákùnrin Polyakov bí ẹní máa kú, wọ́n wá fi òun àtìyàwó ẹ̀ sátìmọ́lé títí dìgbà tí wọ́n fi gbọ́ ẹjọ́ wọn. Àwọn ni tọkọtaya tí wọ́n kọ́kọ́ fi sátìmọ́lé lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 2017. Oṣù márùn-ún gbáko làwọn méjèèjì ò fi ríra wọn sójú. Lẹ́yìn náà, wọ́n ní kí wọ́n lọ lo oṣù mẹ́ta nílé, àwọn agbófinró sì ń ṣọ́ wọn ní gbogbo àsìkò yẹn.

Ní May 2019, àwọn agbófinró tún ya wọ ilé àwọn ará lọ́nà tí ò bófin mu ní Agbègbè Omsk. Wọ́n mú Arábìnrin Bektemirova àti Arábìnrin Dyusekeyeva. Wọ́n fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n, wọ́n sì pinnu láti gbọ́ ẹjọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ Arákùnrin àti Arábìnrin Polyakov. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ náà ní April 1, 2020.

Ó dájú pé Jèhófà máa fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní okun tí wọ́n nílò kí wọ́n lè fara da inúnibíni yìí.​—Éfésù 3:20.

^ ìpínrọ̀ 3 Ó ṣeé ṣe kó yí pa dà