Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arábìnrin Yelena Barmakina àti Dmitriy ọkọ ẹ̀

SEPTEMBER 28, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fẹ̀sùn Ọ̀daràn Kan Arábìnrin Yelena Barmakina Torí Pé Ó Ń Gbàdúrà Tó sì Ń Ka Bíbélì

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fẹ̀sùn Ọ̀daràn Kan Arábìnrin Yelena Barmakina Torí Pé Ó Ń Gbàdúrà Tó sì Ń Ka Bíbélì

Ọjọ́ Tí Wọ́n Máa Ṣèdájọ́

Ní September 29, 2020, * Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Pervorechensky tó wà ní Vladivostok pinnu láti kéde ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arábìnrin Yelena Barmakina. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní kó lo ọdún mẹ́ta nílé, káwọn agbófinró sì máa ṣọ́ ọ. Bí Arábìnrin Barmakina ṣe ń dúró de ìgbà tí wọ́n máa dá ẹjọ́ ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ń gbọ́ ẹjọ́ Dmitriy ọkọ ẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.

Ìsọfúnni Ṣókí

Yelena Barmakina

  • Wọ́n Bíi Ní: 1967 (ní Cherepanovo, lágbègbè Novosibirsk)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Òun ló ń tọ́jú ìyá ẹ̀ àgbà àtàwọn òbí ẹ̀ tó ti dàgbà. Ó fẹ́ràn kó máa ya fọ́tò, ó wá kúkú sọ ọ́ diṣẹ́ nígbà tó yá. Ó gbádùn kó máa lúwẹ̀ẹ́, kó sì máa gbafẹ́ lọ sáwọn òkè àtàwọn ibi tó rẹwà

  • Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń rí báwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń ṣẹ, ìyẹn mú kó dá a lójú pé agbára Ọlọ́run pọ̀ gan-an. Bó sì ṣe ń rí i tí Jèhófà ń dáhùn àdúrà rẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ ń lágbára. Òun àti Dmitriy fẹ́ra lọ́dún 2006

Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ sí Wọn Tẹ́lẹ̀

Ní July 28, 2018, láago méje àárọ̀, àwọn agbófinró tó di ìhámọ́ra, tí wọ́n sì fi nǹkan bojú já wọ ilé ìyá àgbà Arábìnrin Barmakina tó jẹ́ ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90). Ibẹ̀ ni Arákùnrin àti Arábìnrin Barmakin ń gbé kí wọ́n lè tọ́jú wọn. Wọ́n mú Arákùnrin Barmakin, wọ́n sì fi sátìmọ́lé títí dìgbà tí wọ́n fi máa gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀. Àwọn agbófinró náà halẹ̀ mọ́ Arábìnrin Barmakina, wọ́n sọ fún un pé, “A máa tó wá mú ìwọ náà!”

Ọdún kan lẹ́yìn náà, àwọn agbófinró gbẹ́sẹ̀ lé owó tí Arábìnrin Barmakina tọ́jú sí báǹkì. Ní August 6, 2019, wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Arábìnrin Barmakina torí pé ó máa ń gbàdúrà, ó ń ka Bíbélì, ó sì ń wo fídíò tí wọ́n ti ń ṣàlàyé Bíbélì. Agbẹjọ́rò ẹ̀ sọ pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ torí kò sẹ́ṣẹ̀ nínú kéèyàn máa sin Ọlọ́run lọ́nà bẹ́ẹ̀, torí náà ó ní kílé ẹjọ́ fagi lé ẹ̀sùn yẹn. Àmọ́, adájọ́ fara mọ́ ohun táwọn alátakò sọ, ó ní Arábìnrin Barmakina jẹ̀bi ẹ̀sùn “agbawèrèmẹ́sìn,” ó sì ti tàpá sí òfin ilẹ̀ Rọ́ṣíà.

Nǹkan ò rọrùn fún Arábìnrin Barmakina látìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n fi ọkọ ẹ̀ sátìmọ́lé, wọn ò ríra fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ogójì ó lé méje (447) ọjọ́. Ohun míì tún ni pé Arábìnrin Barmakina máa ní láti lọ sílé ẹjọ́ nígbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ yìí, torí náà kò sẹ́ni tó máa fẹ́ gbà á síṣẹ́.

A ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé bọ́rọ̀ ṣe máa rí rèé, torí náà kò yà wá lẹ́nu pé àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń “fi agbára” ti àwọn ará wa kí wọ́n lè fi Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà á máa bá a lọ láti jẹ́ ‘ibi ààbò àti agbára’ wọn.​—Sáàmù 118:13, 14.

^ ìpínrọ̀ 3 Ó ṣeé ṣe kó yí pa dà