Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Láti apá òsì lókè sápá ọ̀tún: Arákùnrin Andrey Tabakov, Arákùnrin Mikhail Zelenskiy, Arákùnrin àti Arábìnrin Mysin, Arákùnrin Aleksandr Ganin, àti Arákùnrin Khoren Khachikyan

OCTOBER 2, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Àwọn Arákùnrin Mẹ́rin àti Tọkọtaya Kan Sẹ́wọ̀n Ọdún Méje ní Rọ́ṣíà

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Àwọn Arákùnrin Mẹ́rin àti Tọkọtaya Kan Sẹ́wọ̀n Ọdún Méje ní Rọ́ṣíà

Ọjọ́ Tí Wọ́n Máa Ṣèdájọ́

Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Zasviyazhsky nílùú Ulyanovsk ti pinnu láti kéde ìdájọ́ lórí àwọn ará wa yìí, ìyẹn Arákùnrin Aleksandr Ganin, Arákùnrin Khoren Khachikyan, Arákùnrin Andrey Tabakov, Arákùnrin Mikhail Zelenskiy, Arákùnrin Sergey Mysin àti Nataliya ìyàwó ẹ̀ ní October 5, 2020. * Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lo ọdún mẹ́ta sí méje lẹ́wọ̀n. Bákan náà, àwọn alátakò ní kílé ẹjọ́ gbẹ́sẹ̀ lé owó àti ọkọ̀ wọn, ìyẹn ohun ìní tí àròpọ̀ iye wọn ju mílíọ̀nù méje ààbọ̀ náírà lọ.

Ìsọfúnni Ṣókí

Aleksandr Ganin

  • Wọ́n Bíi Ní: 1957 (ní Ekhabi lérékùṣù Sakhalin)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ó ti lé ní ogún ọdún tó ti ṣèrìbọmi, tó sì ti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ báyìí, ó sì fẹ́ràn kó máa tún ọgbà ṣe

Khoren Khachikyan

  • Wọ́n Bíi Ní: 1985 (ní Yerevan lórílẹ̀-èdè Armenia)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ètò ọrọ̀ ajé, ó sì gboyè jáde. Ó máa ń kópa nínú ìdíje ìjàkadì nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Àmọ́ ní báyìí, èèyàn jẹ́jẹ́ àti onínúure làwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí

  • Ó wù ú kó túbọ̀ mọ Ọlọ́run, kó sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, torí náà ó gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó mọyì báwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe bọ́gbọ́n mu, tí kò sì ta kora

Sergey Mysin

  • Wọ́n Bíi Ní: 1965 (ní Kulebaki lágbègbè Nizhny Novgorod)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ìgbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ló pàdé Nataliya ìyàwó ẹ̀. Wọ́n ṣègbéyàwó lọ́dún 1991. Ó ti lé lógún ọdún báyìí táwọn méjèèjì ti jọ ń sin Jèhófà. Wọ́n lọ́mọ méjì tó ti dàgbà. Ó fẹ́ràn láti máa ṣe eré ìdárayá, ní pàtàkì èyí tí wọ́n ń pè ní lacrosse

Nataliya Mysina

  • Wọ́n Bíi Ní: 1971 (ní Leningrad tó ti wá di Saint Petersburg báyìí)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Sójà làwọn òbí ẹ̀. Orílẹ̀-èdè Jámánì ló ń gbé tẹ́lẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ta oògùn, ó sì gboyè jáde. Ó fẹ́ràn kó máa se oúnjẹ

Andrey Tabakov

  • Wọ́n Bíi Ní: 1973 (ní Minsk lórílẹ̀-èdè Belarus)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ilé iṣẹ́ tó ń bójú tó ìsọfúnni orí kọ̀ǹpútà ló ń bá ṣiṣẹ́. Ó fẹ́ Marina lọ́dún 2006. Àwọn méjèèjì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Ó fẹ́ràn kó máa tún àwọn ẹ̀rọ kéékèèké ṣe, ní pàtàkì rédíò àti kọ̀ǹpútà

Mikhail Zelenskiy

  • Wọ́n Bíi Ní: 1960 (ní Bulaesti lórílẹ̀-èdè Moldova)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ó ti ṣiṣẹ́ awakọ̀ òkun àti awakọ̀ akẹ́rù rí. Ó fẹ́ Victoria lọ́dún 1989. Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láàárín ọdún 1990 sí 1994. Wọ́n mọyì ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì, wọ́n sì ṣèrìbọmi

Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ sí Wọn Tẹ́lẹ̀

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, àwọn ọlọ́pàá láti àjọ Federal Security Service lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́ àwọn ará wa tó wà nílùú Ulyanovsk. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọlọ́pàá yìí máa ń gbọ́ gbogbo ohun táwọn ará wa ń sọ lórí fóònù, wọ́n sì máa ń gbà á sílẹ̀, àmọ́ àwọn ará ò mọ̀. Ní February 24, 2019, àwọn ọlọ́pàá yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Arákùnrin àti Arábìnrin Mysin, Arákùnrin Khachikyan, Arákùnrin Tabakov àti Arákùnrin Zelenskiy.

Ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìyẹn, láago márùn-ún àárọ̀, àwọn ọlọ́pàá lọ tú ilé Arákùnrin Khachikyan, Arákùnrin Tabakov àti Arákùnrin Zelenskiy. Wọ́n mú àwọn arákùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé títí dìgbà tí wọ́n fi máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Láàárọ̀ ọjọ́ kan náà, ẹnì kan pe Arábìnrin Mysina lórí fóònù. Ẹni náà sọ fún un pé wọ́n ti ba mótò ẹ̀ jẹ́, pé kóun àti Sergey ọkọ ẹ̀ jáde síta. Bí Arákùnrin Mysin ṣe ṣílẹ̀kùn báyìí, ṣe làwọn ọlọ́pàá já wọlé. Wọ́n tú gbogbo ilé náà yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́, wọ́n kó àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tí wọ́n rí níbẹ̀, wọ́n sì mú tọkọtaya náà lọ.

Lọ́jọ́ kejì, Ilé Ẹjọ́ Leninsky tó wà lágbègbè Ulyanovsk ní kí wọ́n fi Arákùnrin Mysin sátìmọ́lé, títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀. Wọ́n tún ní kí Arábìnrin Mysina àtàwọn arákùnrin tó kù má ṣe kúrò nílé, káwọn agbófinró sì máa ṣọ́ wọn.

Arákùnrin Mysin lo ọjọ́ márùndínlọ́gọ́ta (55) látìmọ́lé, ó tún lo ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123) nílé, àwọn agbófinró sì ń ṣọ́ ọ ní gbogbo àsìkò yẹn. Bákan náà, àádọ́ta (50) ọjọ́ sí ọjọ́ márùndínlọ́gọ́ta (55) làwọn agbófinró fi ṣọ́ àwọn tó kù nílé, ìyẹn Arábìnrin Mysina, Arákùnrin Khachikyan, Arákùnrin Tabakov àti Arákùnrin Zelenskiy.

Láàárọ̀ May 15, 2019, àwọn ọlọ́pàá lọ tú ilé Arákùnrin Ganin, wọ́n fàṣẹ ọba mú un, wọ́n sì fi sátìmọ́lé fún ọjọ́ méjì.

Ní báyìí, ìjọba ò ká àwọn ará wa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yìí lọ́wọ́ kò mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Àmọ́, àwọn agbófinró ṣì ń ṣenúnibíni sí wọn láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì àtààbọ̀ náírà tí Arákùnrin Mysin àti Arábìnrin Mysina tọ́jú sílé ìfowópamọ́ àti nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta náírà tí Arákùnrin Tabakov tọ́jú sílé ìfowópamọ́.

Bí wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni sáwọn arákùnrin àti arábìnrin wa yìí, àdúrà wa ni pé kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ máa lágbára bí wọ́n ṣe ń ronú lórí ọ̀rọ̀ onísáàmù tó sọ pé: “Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa, ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.”​—Sáàmù 46:1.

[Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé]

^ ìpínrọ̀ 3 Ó ṣeé ṣe kó yí pa dà