Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Anatoliy Tokarev pẹ̀lú Andrey ọmọkùnrin ẹ̀, Margarita ìyàwó ẹ̀ àti Yekaterina ọmọbìnrin ẹ̀

OCTOBER 8, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Anatoliy Tokarev Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́ta Àtààbọ̀ ní Rọ́ṣíà

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Anatoliy Tokarev Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́ta Àtààbọ̀ ní Rọ́ṣíà

Ọjọ́ Tí Wọ́n Máa Ṣèdájọ́

Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oktyabrsky tó wà ní Kirov ti pinnu láti kéde ìdájọ́ lórí ẹjọ́ Arákùnrin Anatoliy Tokarev ní October 23, 2020. * Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fi Arákùnrin Anatoliy sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta àtààbọ̀.

Ìsọfúnni Ṣókí

Anatoliy Tokarev

  • Wọ́n Bíi Ní: 1958 (ní Baranovskaya, lágbègbè Kirov)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ìyá ẹ̀ nìkan ló tọ́ ọ dàgbà. Onímọ̀ nípa ètò orí kọ̀ǹpútà ni, àmọ́ ó ti fẹ̀yìn tì. Ó fẹ́ràn kó máa fi kámẹ́rà yàwòrán, kó máa ta ayò chess, kó sì máa lo ohun èlò ìkọrin tí wọ́n ń pè ní accordion. Ó fẹ́ Margarita lọ́dún 1979, wọ́n sì bí ọmọ méjì

  • Àwọn nǹkan tó kọ́ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mú kó rò pé kò sí Ọlọ́run. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó pé ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27), ó sì rí i pé ẹ̀kọ́ Bíbélì ò ta ko ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì

Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ sí I Tẹ́lẹ̀

Ní May 24, 2019, àwọn agbófinró láti àjọ Center for Countering Extremism ya wọ ilé Arákùnrin Tokarev. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò ó. Wọ́n láwọn máa fìyà jẹ Arákùnrin Tokarev àti ìdílé ẹ̀ tí ò bá gbà pé “agbawèrèmẹ́sìn” lòun. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n mú un lọ sí ẹ̀ka tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ wá àwọn ọ̀daràn lẹ́nu wò.

Ní nǹkan bí oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, wọ́n dẹ́bi fún Arákùnrin Tokarev, wọ́n sì sọ pé ó ṣẹ̀ sí ohun tó wà ní àpilẹ̀kọ méjì nínú ìwé Òfin Ìwà Ọ̀daràn Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó ń fowó ṣètìlẹyìn fáwọn “agbawèrèmẹ́sìn.” Ṣáájú ìgbà yẹn làwọn alátakò ti ń dọ́gbọ́n fi ẹ̀rọ tó ń gba ohùn sílẹ̀ ṣọ́ gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ nílé Arákùnrin Tokarev. Ohùn tí wọ́n gbà sílẹ̀ yẹn ni wọ́n fi jẹ́rìí lòdì sí Arákùnrin Tokarev, wọ́n ní ó ń kó àwọn èèyàn jọ láti ka àwọn ìwé tí ìjọba kà sí ẹrù àwọn “agbawèrèmẹ́sìn.”

Gbogbo ìgbà là ń rántí Arákùnrin Tokarev àti ìdílé ẹ̀ nínú àdúrà wa. “Adúróṣinṣin” ni Jèhófà, torí náà ó dá wa lójú pé ó máa dúró tì wọ́n.​—Sáàmù 18:25.

^ ìpínrọ̀ 3 Ó ṣeé ṣe kó yí pa dà