Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Dmitriy Terebilov àti Irina ìyàwó rẹ̀

AUGUST 5, 2021
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Dmitriy Terebilov Sẹ́wọ̀n Fúngbà Àkọ́kọ́ Torí Ohun Tó Gbà Gbọ́ Lẹ́yìn Tó Ti Ṣẹ̀wọ̀n Lẹ́ẹ̀mẹ́rin

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Dmitriy Terebilov Sẹ́wọ̀n Fúngbà Àkọ́kọ́ Torí Ohun Tó Gbà Gbọ́ Lẹ́yìn Tó Ti Ṣẹ̀wọ̀n Lẹ́ẹ̀mẹ́rin

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

  1. Ní September 6, 2021, ilé ẹjọ́ agbègbè Sverdlovskiy nílùú Kostroma ní kí Arákùnrin Dmitriy Terebilov lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta. Ojú ẹsẹ̀ tí wọ́n kéde ìdájọ́ náà ni wọ́n fi sínú àhámọ́

  2. September 8, 2020

    Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Dmitriy

  3. May 25, 2020

    Wọ́n fẹ̀sùn kan Dmitriy, wọ́n sì ní kò gbọ́dọ̀ rìnrìn àjò

  4. September 19, 2019

    Wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé àkáǹtì tí Dmitriy ní sí báńkì

  5. June 13, 2019

    Wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Dmitriy, wọ́n ní ó ń fún àwọn èèyàn ní ìwé tí ìjọba ti fòfin dè àti pé ó ń kópa nínú ìpàdé àwọn èèyàn tí ìjọba ti fòfin dè

  6. July 25, 2018

    Àwọn agbófinró lọ tú ilé Dmitriy kí òun àti ìyàwó ẹ̀ tó dé láti àpéjọ àgbègbè tí wọ́n lọ ṣe lórílẹ̀-èdè Moldova. Lẹ́yìn tí wọ́n délé, àwọn ọlọ́pàá mú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò

Ìsọfúnni Ṣókí

Bí Dmitriy ṣe túbọ̀ ń ní irú ayọ̀ téèyàn máa ń ní torí pé ‘wọ́n ń gàn án nítorí orúkọ Kristi,’ ó dá wa lójú pé ‘ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, máa bà lé e.’—1 Pétérù 4:14.