Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Sergey Ledenyov àti Anna ìyàwó ẹ̀

NOVEMBER 20, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Sergey Ledenyov Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́fà ní Rọ́ṣíà

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Sergey Ledenyov Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́fà ní Rọ́ṣíà

Ìdájọ́

Ilé Ẹjọ́ Ìlú Petropavlovsk-Kamchatskiy tó wà lágbègbè Kamchatka pinnu láti kéde ìdájọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Sergey Ledenyov ní November 24, 2020. * Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà.

Ìsọfúnni Ṣókí

Sergey Ledenyov

  • Wọ́n Bí I Ní: 1974 (nílùú Ossora lágbègbè Kamchatka)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ọmọ mẹ́fà làwọn òbí ẹ̀ bí. Ó fẹ́ràn kó máa yàwòrán, kó sì máa fi kámẹ́rà ya fọ́tò. Ó máa ń ṣe iṣẹ́ bíríkìlà, ó sì máa ń lẹ àwo tí wọ́n ń pè ní tiles. Káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó gbà pé ìwé àtijọ́ ni Bíbélì àti pé àwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀ ò bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Ó fẹ́ Anna lọ́dún 2017. Anna sọ pé, bí Sergey ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ti jẹ́ kó di èèyàn jẹ́jẹ́ àti ọkọ rere

Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ sí I Tẹ́lẹ̀

Ní December 2, 2018, àwọn agbófinró tó di ìhámọ́ra, tí wọ́n sì fi nǹkan bojú ya wọ ilé tí Arákùnrin Ledenyov ń gbé nílùú Petropavlovsk-Kamchatskiy. Wọ́n mú Arákùnrin Ledenyov, wọ́n sì fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn án. Wọ́n ní ò ṣẹ̀ sí Article 282.2, nínú ìwé òfin ìwà ọ̀daràn orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ní November 28, 2019.

Ní December 12, 2019, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Petropavlovsk-Kamchatskiy tó wà lágbègbè Kamchatka dá ẹjọ́ náà pa dà fáwọn alátakò. Àwọn adájọ́ sì sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá rí i pé ẹ̀sùn táwọn alátakò mú wá ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Àmọ́ láìka ti pé ẹ̀sùn yẹn ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, ní February 4, 2020, ilé ẹjọ́ míì tó ga ju èyí tó kọ́kọ́ gbọ́ ọ yí ìpinnu náà pa dà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tún ẹjọ́ náà gbọ́. Lọ́jọ́ míì tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ yìí, àwọn agbẹjọ́rò bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bo Arábìnrin Ledenyov àti arábìnrin kan, wọ́n fúngun mọ́ àwọn méjèèjì kí wọ́n lè jẹ́rìí lòdì sí Arákùnrin Ledenyov. Àmọ́, léraléra làwọn arábìnrin méjèèjì kọ̀ láti ṣe ohun táwọn agbẹjọ́rò náà fẹ́.

Àwọn mọ̀lẹ́bí Arákùnrin Ledenyov tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n máa ṣenúnibíni sí i nítorí pé ó gba Ọlọ́run gbọ́.

A ò dákẹ́ àdúrà lórí Arákùnrin àti Arábìnrin Ledenyov bí wọ́n ṣe ń dúró dìgbà tílé ẹjọ́ máa kéde ìdájọ́ náà. Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wọn lókun, á sì fún wọn lẹ́mìí mímọ́ rẹ̀.​—1 Pe 4:14.

^ ìpínrọ̀ 3 Ó ṣeé ṣe kó yí pa dà.