Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Yevgeniy Spirin rèé níbi tí wọ́n tì í mọ́ nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀

JULY 9, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Yevgeniy Spirin Sẹ́wọ̀n Ọdún Méje ní Rọ́ṣíà

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Yevgeniy Spirin Sẹ́wọ̀n Ọdún Méje ní Rọ́ṣíà

Ó ṣeé ṣe kí ilé ẹjọ́ Furmanovsky City Court tó wà lágbègbè Ivanovo kéde ìdájọ́ ní July 14, 2020, lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Yevgeniy Spirin. Agbẹjọ́rò ìjọba ní kí ilé ẹjọ́ fi Arákùnrin Spirin sẹ́wọ̀n ọdún méje.

Ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) ni Arákùnrin Spirin, wọ́n fẹ̀sùn “agbawèrèmẹ́sìn” kàn án, wọ́n sì sọ pé ó ń lọ́wọ́ sí ìsìn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti fòfin dè. January 21, 2019 ni àwọn aláṣẹ tó ń ṣèwádìí kọ́kọ́ mú arákùnrin wa. Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà ni àwọn aláṣẹ yìí lọ tú ilé Arákùnrin Spirin àti ìyàwó ẹ̀, Natalya. Ilé ẹjọ́ Oktyabrsky District Court tó wà lágbègbè Ivanovo ní kí wọ́n fi Arákùnrin Spirin sátìmọ́lé fún oṣù méjì torí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó yá, wọ́n tún fi kún ọjọ́ tó máa lò látìmọ́lé.

Ní July 5, 2019, wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́yìn tó ti lo nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó oṣù mẹ́fà látìmọ́lé, wọ́n sì ṣòfin pé kò gbọ́dọ̀ kúrò nílé ẹ̀. Ní December 18, 2019, ilé ẹjọ́ Oktyabrsky tó wà lágbègbè Ivanovo fagi lé òfin tó ní kí Arákùnrin Spirin má kúrò nílé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó fẹ̀sùn kàn án ò fẹ́ bẹ́ẹ̀, síbẹ̀, ilé ẹjọ́ náà ò fún un láwọn ìkálọ́wọ́kò míì.

Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa tí wọ́n ń fìyà jẹ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Pétérù 4:14.