Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 23, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Yuriy Zalipayev Sẹ́wọ̀n Ọdún Méjì ní Rọ́ṣíà

Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Yuriy Zalipayev Sẹ́wọ̀n Ọdún Méjì ní Rọ́ṣíà

Ìdájọ́

Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Mayskiy tó wà ní Kabardino-Balkarian Republic ti pinnu láti kéde ìdájọ́ lórí ẹjọ́ Arákùnrin Yuriy Zalipayev ní October 7, 2020. * Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fi Arákùnrin Yuriy sẹ́wọ̀n ọdún méjì.

Ìsọfúnni Ṣókí

Yuriy Zalipayev

  • Wọ́n Bí I Ní: 1962 (nílùú Samara)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Ó ti ṣiṣẹ́ ajórinmọ́rin àti awakọ̀ akẹ́rù rí. Ó fẹ́ràn kó máa kọ ewì, kó sì máa gbafẹ́ lọ sáwọn òkè àtàwọn ibi tó rẹwà

  • Lọ́dún 1983, ó fẹ́ Natalia tí wọ́n jọ lọ síléèwé kan náà ní kékeré. Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún mẹ́wàá lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó. Ọmọ mẹ́ta ni wọ́n bí, gbogbo wọn ni wọ́n ń sin Jèhófà, pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn mọ̀lẹ́bí wọn

Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ sí I Tẹ́lẹ̀

Ní August 20, 2016, àwọn agbófinró ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Mayskiy, wọ́n sì fi àwọn ìwé tí ìjọba ti fòfin dè síbẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará ní fídíò ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn lọ́wọ́, síbẹ̀ ilé ẹjọ́ sọ pé wọ́n jẹ̀bi, wọ́n sì ní kí wọ́n san owó ìtanràn tó lé ní mílíọ̀nù kan náírà. Lẹ́yìn oṣù bíi mélòó kan, wọ́n sọ pé Arákùnrin Zalipayev jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn torí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn.

Àwọn alátakò sọ pé Arákùnrin Zalipayev ń pín àwọn ìwé tí Ìjọba ti fòfin dè, ó sì ń rọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì pé kí wọ́n hùwà ìkà sáwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn wọn. Ẹ̀sùn yìí wà lára ohun tí òfin kà léèwọ̀ nínú ìwé òfin nípa “àwọn agbawèrèmẹ́sìn” (Apá Kìíní Article 280 Nínú Ìwé Òfin Ìwà Ọ̀daràn Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà).

Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ náà ní June 21, 2020. Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi ń gbọ́ ẹjọ́ náà, ṣe lọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí táwọn alátakò mú wá ń ta kora tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sọ ohun tó máa fi hàn pé ẹ̀sùn wọn ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan jẹ́rìí sí i pé Arákùnrin Zalipayev ń rọ àwọn míì láti hùwà ìkà. Àmọ́ bí ìgbẹ́jọ́ ṣe ń lọ lọ́wọ́, àṣírí tú pé àwọn kan lára wọn ò tiẹ̀ sí nípàdé lọ́jọ́ tí wọ́n ló sọ bẹ́ẹ̀. Bákan náà, àwọn kan lára àwọn ẹlẹ́rìí táwọn alátakò mú wá tún jẹ́rìí sí i pé àwọn agbófinró ló fi àwọn ìwé tí ìjọba fòfin dè sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Bí Arákùnrin Zalipayev ṣe ń dúró dìgbà tí wọ́n máa kéde ìdájọ́ ẹ̀, àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fún òun àti ìdílé rẹ̀ lókun, kó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ronú lórí ohun tí Dáfídì sọ, pé: “Jèhófà ni agbára mi àti apata mi; òun ni ọkàn mi gbẹ́kẹ̀ lé. Ó ti ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì ń yọ̀.”​—Sáàmù 28:7.

^ ìpínrọ̀ 3 Ó ṣeé ṣe kó yí pa dà