Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 25, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ó Ti Tó Ọdún Mẹ́ta Báyìí Tí Wọ́n Ti Fi Arákùnrin Dennis Christensen Sẹ́wọ̀n Ní Rọ́ṣíà, Síbẹ̀ Ó Jẹ́ Olóòótọ́ Ó Sì Ń Láyọ̀

Ó Ti Tó Ọdún Mẹ́ta Báyìí Tí Wọ́n Ti Fi Arákùnrin Dennis Christensen Sẹ́wọ̀n Ní Rọ́ṣíà, Síbẹ̀ Ó Jẹ́ Olóòótọ́ Ó Sì Ń Láyọ̀

Bá a se ń sọ̀rọ̀ yìí, ó ti tó ọdún mẹ́ta tí wọ́n ti fi Arákùnrin Dennis Christensen sẹ́wọ̀n lọ́nà àìtọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Láti May 25, 2017 ni wọ́n ti mú Arákùnrin Christensen, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí gbogbo wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ sí i yìí ṣe ń nípa lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ohun kan náà ló ṣì fi ń dáhùn látìgbà yẹn: “Ṣe ni ìgbàgbọ́ mi ń lágbára sí i.”

Arákùnrin Christensen sọ pé: “Ohun tó wà nínú ìwé Jémíìsì orí kìíní ẹsẹ kejì sí ìkẹta ti ṣẹ sí mi lára, èyí tó sọ pé: ‘Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà.’ ”

Ó wú wa lórí láti mọ̀ pé láìka gbogbo ìṣòro àti ìjákulẹ̀ tí Arákùnrin Christensen ti kojú sí, ńṣe ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ ń lágbára sí i, tí inú rẹ̀ sì ń dùn.

Lẹ́yìn tí ìjọba mú Arákùnrin Christensen, kó tó di pé wọ́n mú un lọ sílé ẹjọ́, wọ́n fi sí àtìmọ́lé níbì kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ilé rẹ̀ ní ìlú Oryol. Kò pẹ́ sígbà yẹn, wọ́n gbà Irina ìyàwó rẹ̀ láyè láti máa wá bẹ̀ ẹ́ wò. Ó lé ní ọdún méjì tí wọ́n fi ti Arákùnrin Christensen mọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Ní February 2019, wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà fún Arákùnrin Christensen. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ wọn ò gbà á láyè. Lẹ́yìn náà wọ́n gbé e lọ sí ẹ̀wọ̀n míì tó jìnnà tó máìlì mẹ́rìnlélọ́gọ́fà [124] (200km) sí ìlú Oryol tí ìyàwó rẹ̀ wà, èyí sì mú kí ibi táwọn méjèèjì wà túbọ̀ jìnnà síra.

Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan báyìí tí Arákùnrin Christensen ti lẹ́tọ̀ọ́ láti béèrè pé kí wọ́n dá òun sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mẹta ni ìjọba ti dá a lóhùn pé kò ṣeé ṣe. Láìka gbogbo ìjákulẹ̀ yìí sí, Arákùnrin Christensen kò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run dín kù.

Arákùnrin Christensen sọ pé: “Èmi àti Irina ìyàwó mi kì í ṣe eni pípé, àmọ́ a ti kọ́ bá a ṣe lè ní ìfaradà, ká má sì jẹ́ kí ayọ̀ wa dín kù nínú ìṣòro. Ohun tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, a ti túbọ̀ sún mọ́ Bàbá wa àti Ọlọ́run wa, Jèhófà.”

A ò dáwọ́ àdúrà dúró, a sì gbà pé Jèhófà á máa báa lọ láti ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní Rọ́ṣíà, kí wọ́n lè máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń fara da inúnibíni.​—Mátíù 5:​11, 12.