Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol

MAY 14, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Christensen Ò Ní Pẹ́ Parí

Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Christensen Ò Ní Pẹ́ Parí

Ní Tuesday, May 7, 2019, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol bẹ̀rẹ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Dennis Christensen pè torí bí wọ́n ṣe rán an lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà nítorí ohun tó gbà gbọ́. Àmọ́ ohun táwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà sábà máa ń ṣe ni ilé ẹjọ́ yìí náà ṣe, wọn ò gba àwọn ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro táwọn agbẹjọ́rò wa mú wá wọlé, wọn ò sì gbé wọn yẹ̀ wò láti rí i pé Dennis kò mọwọ́mẹsẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí àwọn adájọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó ń gbọ́ ẹjọ́ yìí sọ ìpinnu wọn títí ìparí ọ̀sẹ̀ yìí.

Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló wá sí ilé ẹjọ́ yìí láti wá ṣètìlẹyìn fún Dennis lọ́jọ́ tí ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀. Bákan náà, àwọn aṣojú láti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè wá síbẹ̀ àtàwọn akọ̀ròyìn pẹ̀lú àwọn tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn. Inú yàrá kékeré kan tí kò lè gbà ju èèyàn ogún (20) sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ náà, ìyẹ̀n sì mú kí nǹkan bí àádọ́ta (50) èèyàn dúró síta. Àmọ́ ilé ẹjọ́ náà fara mọ́ àbá táwọn agbẹjọ́rò Dennis mú wá pé kí wọ́n jẹ́ kí gbogbo àwọn tó wá fún ìgbẹ́jọ́ náà lọ sí yàrá míì tó lè gba nǹkan bí ọgọ́rin (80) èèyàn. Lẹ́yìn tí wọ́n lo wákàtí mẹ́ta péré lẹ́nu ìgbẹ́jọ́ náà, ilé ẹjọ́ sún ẹjọ́ náà síwájú.

Lọ́jọ́ kejì ìgbẹ́jọ́ náà, agbẹjọ́rò Dennis béèrè pé kí ilé ejọ́ náà ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí kan tó fi hàn pé Dennis ò mọwọ́mẹsẹ̀, àmọ́ àwọn adájọ́ kọ̀. Èyí ò dáa rárá torí àwọn agbẹjọ́rò Dennis gbà pé àwọn ẹ̀rí yìí máa fi hàn pé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ dá kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Lópin ọjọ́ náà, ilé ẹjọ́ sọ pé ìgbẹ́jọ́ náà máa tẹ̀ síwájú ní Thursday, May 16 káwọn agbẹjọ́rò lè fẹnu ọ̀rọ̀ wọn jóná lọ́kọ̀ọ̀kan.

Àdúrà wa fáwọn ará wa ní Rọ́síà ni pé kí ọkàn wọn balẹ̀, kí ìgbàgbọ́ wọn má sì yẹ̀ nínú àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa gbà wọ́n pátápátá lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra wọn.—Sáàmù 12:5.