Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn adájọ mẹ́ta ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol tó fara mọ́ ọn pé kí Dennis Christensen lo sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà

JUNE 11, 2019
RỌ́ṢÍÀ

A Máa Gbé Ẹjọ́ Dennis Christensen Lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù

A Máa Gbé Ẹjọ́ Dennis Christensen Lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù

Bá a ṣe sọ nínú ìròyìn tó jáde ní May 23, 2019, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol fara mọ́ ọn pé kí Dennis Christensen lọ sẹ́wọ̀n. Torí náà, ẹjọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà tí wọ́n dá fún Arákùnrin Christensen ò tíì yí pa dà. Ó ti lo ọdún méjì látìmọ́lé kí wọ́n tó dá ẹjọ́ rẹ̀, nínú òfin orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, èyí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ọdún mẹ́ta nínú ẹ̀wọ̀n, torí náà ọ́dún mẹ́ta ló kù tí wọ́n retí pé kó lò lẹ́wọ̀n. Ní ìrọ̀lẹ́ June 6, 2019, wọ́n mú Arákùnrin Christensen lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan táwọn ẹlẹ́wọ̀n ti ń ṣiṣẹ́, kó lè lọ ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀. A máa fi ìwé tá a kọ lórí bí wọ́n ṣe rán Arákùnrin Christensen lẹ́wọ̀n láìtọ́ ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR). Ìwé tá a kọ ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ ECHR lórí bí wọ́n ṣe tì í mọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ṣì wà lọ́dọ̀ wọn.

A mọyì bí Arákùnrin Christensen ṣe ń fara dà á nìṣó láìka ìdájọ́ tí kò tọ́ tí wọ́n ṣe fún un sí. Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi í sílẹ̀, àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì (200) tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn ní lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà.​—Sáàmù 27:1.

Ka ọ̀rọ̀ tí Dennis Christensen sọ ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol ní May 16, 2019.

Ka ọ̀rọ̀ tí Dennis Christensen sọ ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol ní May 23, 2019.