Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 18, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Adájọ́ Ju Arákùnrin Yevgeniy Aksenov sí Ẹ̀wọ̀n Ọdún Méjì Tó Ní Àfi Nínú

Ilé Ẹjọ́ Lórílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Dá Arákùnrin Yevgeniy Aksenov Lẹ́bi Pẹ̀lú Ẹ̀wọ̀n Ọdún Méjì Ní Ìpamọ́

Ní February 18, 2020, ilé ẹjọ́ Zheleznodorozhniy District Court tó wà ní ìlú Khabarovsk, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, dẹ́bi fún Yevgeniy, adájọ́ sì ní kí wọ́n fi sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì, kò ní lọ sí ẹ̀wọ̀n, àmọ́ wọ́n á máa sọ lójú méjèèjì. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé láàárín ọdún méjì yẹn, Yevgeniy yí ibùgbé rẹ̀ pa dà tàbí ó jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn èyíkéyìí, wọ́n máa jù ú sẹ́wọ̀n. Ní oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́, abẹ́ àyẹ̀wò ló máa wà, ó sì gbọ́dọ̀ máa lọ fara hàn ní àgọ́ ọlọ́pàá lóṣooṣù. Ní àfikún sí ìyẹn, ní gbogbo àkókò tó fi wà lábẹ́ àyẹ̀wò, kò gbọ́dọ̀ fi ìlú Khabarovsk tó ń gbé sílẹ̀ lọ sí ìlú míì, kò sì gbọ́dọ̀ jáde nínú ilé ní ìrọ̀lẹ́. Arákùnrin Yevgeniy máa pe ẹjọ́ kọ̀tẹ́milọ́rùn.