Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arábìnrin Yelena Barmakina àti Dmitriy ọkọ ẹ̀ níwájú Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Pervorechenskiy ní Vladivostok

SEPTEMBER 29, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Adájọ́ Ní Káwọn Alátakò Pa Dà Lọ Ṣàyẹ̀wò Ẹ̀sùn Tí Wọ́n Fi Kan Arábìnrin Yelena Barmakina Torí Pé Wọn Ò Rí Ẹ̀rí Tó Pọ̀ Tó

Adájọ́ Ní Káwọn Alátakò Pa Dà Lọ Ṣàyẹ̀wò Ẹ̀sùn Tí Wọ́n Fi Kan Arábìnrin Yelena Barmakina Torí Pé Wọn Ò Rí Ẹ̀rí Tó Pọ̀ Tó

Ní September 29, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Pervorechenskiy tó wà ní Vladivostok ò dá Arábìnrin Yelena Barmakina lẹ́bi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe nilé ẹjọ́ ní káwọn alátakò pa dà lọ ṣàyẹ̀wò ẹjọ́ náà. Adájọ́ sọ pé ẹ̀sùn wọn ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, torí wọn ò rí ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti fi hàn pé agbawèrèmẹ́sìn ni Arábìnrin Barmakina lóòótọ́. Àwọn alátakò lè pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n máa sún ẹjọ́ náà síwájú dìgbà tí wọ́n fi máa rí ẹ̀rí tó pọ̀ tó.