Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arábìnrin Tatyana Sholner

JUNE 21, 2021
RỌ́ṢÍÀ

Arábìnrin Tatyana Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Ó sì Ń Láyọ̀ Láìka Inúnibíni Sí

Arábìnrin Tatyana Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Ó sì Ń Láyọ̀ Láìka Inúnibíni Sí

LÁÌPẸ́ YÌÍ | Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Dájọ́ Pé Kí Arábìnrin Tatyana Sholner Máa Lọ Sílé, àmọ́ Wọ́n Á Máa Ṣọ́ Ọ́ Lójú Méjèèjì

Ní June 25, 2021, ilé ẹjọ́ Birobidzhan District Court ní agbègbè Jewish Autonomous Region sọ pé kí Arábìnrin Tatyana Sholner máa lọ sílé, ìjọba á máa ṣọ́ ọ lójú méjèèjì fún ọgbọ̀n (30) oṣù bóyá ó máa ṣe ohun tó máa tako òfin àwọn. Ní báyìí ná, kò ní lọ sí ẹ̀wọ̀n.

Ìgbà Tílé Ẹjọ́ Máa Kéde Èsì Ìgbẹ́jọ́

Ilé ẹjọ́ Birobidzhan District Court ní agbègbè Jewish Autonomous Region máa tó kéde èsì ẹjọ́ Arábìnrin Tatyana Sholner. a Agbẹjọ́rò ìjọba sọ pé kí ilé ẹjọ́ rán Tatyana lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin.

Ìsọfúnni

Tatyana Sholner

  • Ọdún Tí Wọ́n Bí I: 1993 (ní Birobidzhan)

  • Ìtàn Ìgbésí Ayé: Bàbá Tanyana kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan tó wáyé nígbà tí Tanyana ṣì kéré gan-an. Àtìgbà yẹn ni ìyá rẹ̀ ti ń dá nìkan tọ́ òun àti àbúrò ẹ̀. Tatyana ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń ta oògùn òyìnbó. Ó fẹ́ràn kó máa rìn lórí yìnyín, kó máa gun kẹ̀kẹ́ àti kó máa gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá ìyẹn volleyball

    Ìgbà tó ń kọ́ṣẹ́ aṣọ rírán nílé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí i kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwà ọmọ kíláàsì ẹ̀ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wú u lórí gan-an. Ẹ̀kọ́ nípa ìrètí àjíǹde tù ú nínú nígbà tí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá (12) kú lọ́dún 2014. Ó ṣèrìbọmi lọ́dún 2017

Ìsọfúnni Nípa Ẹjọ́ Yìí

Ní February 6, 2020, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní Birobidzhan fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan àwọn Kristẹni arábìnrin mẹ́fà kan, Tatyana tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) wà lára wọn. Wọ́n fi ẹ̀sùn “agbawèrèmẹ́sìn” kan òun àtàwọn tó kù torí pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run. Àpapọ̀ ẹjọ́ mọ́kàndínlógún (19) ni wọ́n ti pè lórí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní agbègbè Jewish Autonomous Region.

Ó dá Tatyana lójú pé Jèhófà ń ran òun lọ́wọ́ bó ṣe ń kojú inúnibíni yìí. Ó sọ pé: “Nígbà tí inúnibíni bẹ̀rẹ̀, mi ò lè jọ́sìn Jèhófà bí mo ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀, àmọ́ mi ò gbà gbé láti ka Bíbélì. Mo sọ gbogbo bí nǹkan ṣe ri lára mi àtohun tó ń gbé mi lọ́kan sókè fún Jèhófà. Mo gbàdúrà pé kó fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ kí n lè fara da gbogbo ohun tí màá kojú, kí n sì jẹ́ olóòótọ́ sí i títí dé òpin. Mo tún gbàdúrà pé kó jẹ́ kí n nígboyà, kí n ṣọkàn akin, kó sì fún mi lọ́gbọ́n tí màá fi gbèjà orúkọ Rẹ̀ nílé ẹjọ́.”

Ó ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ pé: “Ti pé mo mọ̀ pé Jèhófà máa ń ti àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn, tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́, tó sì ń dáàbò bò wọ́n jẹ́ kí n máa láyọ̀. Jèhófà ń fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ tó lágbára dì mí mú. Ìyẹn ló jẹ́ kí n gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, kí n sì fara balẹ̀ bí mo ṣe ń kojú inúnibíni.”​—Àìsáyà 41:10.

Bá a ṣe ń retí èsì ìgbẹ́jọ́, ó dá wa lójú pé Tatyana á máa bá a lọ láti “fara da ìpọ́njú” pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà.—Róòmù 12:12.

a Ilé ẹjọ́ kì í sábà sọ ọjọ́ tí wọ́n máa kéde èsì ìgbẹ́jọ́.