Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Gennady Shpakovskiy pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, Tatiana

JUNE 5, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Arákùnrin Gennady Shpakovskiy Lè Lọ Sẹ́wọ̀n Ọdún Méjé Àtààbọ̀ Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Arákùnrin Gennady Shpakovskiy Lè Lọ Sẹ́wọ̀n Ọdún Méjé Àtààbọ̀ Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Ilé ẹjọ́ ìlú Pskov máa gbé ìdájọ́ ẹ̀ kalẹ̀ ní June 8, 2020, lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Gennady Shpakovskiy, ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61). Wọ́n fẹ̀sùn agbawèrèmẹ́sìn kàn-án torí ìpàdé Kristẹni tí wọn ń ṣe nílé ẹ̀. Agbẹjọ́rò ìjọba ti sọ pé kí ilé ẹjọ́ rán Arákùnrin Shpakovskiy lọ sẹ́wọ̀n ọdún méje àtààbọ̀.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ 2018, àwọn ọ̀lọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí yọ́ kẹ́lẹ́ fi ẹ̀rọ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú ilé Shpakovskiy, wọ́n sì ń ṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù. Ní June 3, 2018, ní aago kan ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ́sàn-án, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ orílẹ̀-èdè náà, fi tipátipá ṣí ilẹ̀kùn iwájú ilé náà, níbi tí àwọn èèyàn péjọ sí láti ṣe ìpàdé ní wọ́ọ́rọ́wọ́, wọ́n sì wá gbogbo inú ilé náà fún wákàtí mẹ́fà.

Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ gbẹ́sẹ̀ lé tábílẹ́tì àti fóònù àwọn Ẹlẹ́rìí náà, wọ́n sì kó wọn lọ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Àwọn tó ń fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò bẹ̀rẹ̀ sí bú wọn, wọ́n sì ń halẹ mọ́ wọn pé wọ́n máa pàdánù iṣẹ́ wọn, wọ́n á sì lọ sẹ́wọ̀n. Ó tó aago mẹ́wàá alẹ́ kí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Arákùnrin Shpakovskiy tó parí.

Ní March 19, 2019, wọ́n fẹ̀sùn kan Arákùnrin Shpakovskiy pé ó ń ṣètò ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, wọ́n fi ẹ̀sùn míì kàn-án pé ó ń fi owó ṣe ìtìlẹ́yìn fún ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn.

Bí ìgbẹ́jọ́ náà ṣe ń sún mọ́lé, a gbàdúrà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé Jèhófà máa ran ìdílé Shpakovskiy lọ́wọ́ láti dúró gbọin, a sì mọ̀ pé èrè wà fún ìfaradà wọn.​—2 Kíróníkà 15:7.