SEPTEMBER 16, 2020
RỌ́ṢÍÀ
Arákùnrin Vladimir Alushkin Ò Ní Pa Dà Sẹ́wọ̀n Mọ́
Ní September 16, 2020, Ilé Ẹjọ́ agbègbè Penza kéde ìdájọ́ lórí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn ará yìí pè, ìyẹn Arákùnrin Alushkin, Arákùnrin Kulyasov, Arákùnrin Magliv, Arákùnrin Timoshin, Arábìnrin Tatyana Alushkina àti Arábìnrin Olkhova. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dá ẹjọ́ Arákùnrin Alushkin, ilé ẹjọ́ ní kó lọ lo ọdún mẹ́fà lẹ́wọ̀n. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ní kó lọ lo ọdún mẹ́rin nílé, wọ́n á sì máa ṣọ́ ọ ní gbogbo àsìkò yẹn. Inú wa dùn pé Arákùnrin Alushkin ò ní pa dà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n mọ́. Àmọ́, iye ọdún tílé ẹjọ́ kọ́kọ́ sọ pé káwọn tó kù lò nílé ò yí pa dà.