Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Kirill Yevstigneev

JANUARY 13, 2022
RỌ́ṢÍÀ

Arákùnrin Yevstigneev Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Ìyẹn sì Mú Kó Jẹ́ Olóòótọ́

Arákùnrin Yevstigneev Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Ìyẹn sì Mú Kó Jẹ́ Olóòótọ́

Ilé ẹjọ́ Leninskiy District Court tó wà nílùú Nizhny Novgorod máa tó kéde ìdájọ́ wọn lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Arákùnrin Kirill Yevstigneev. Agbẹjọ́rò ìjọba ò tíì sọ ìyà tó fẹ́ kí ilé ẹjọ́ fi jẹ arákùnrin náà

Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀

  1. October 8, 2021

    Ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án. Kirill ṣàlàyé fún adájọ́ náà pé àwọn kóra jọ láti gbádùn ara àwọn ni, kì í ṣe láti jọ́sìn

  2. August 24, 2021

    Àwọn aláṣẹ sọ pé Kirill ò gbọ́dọ̀ rìnrìn àjò

  3. September 2, 2020

    Wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Kirill pé ó ń “fi owó ṣètìlẹyìn fáwọn agbawèrèmẹsìn” torí pé òun ló gba yàrá tí wọ́n lò fún ìkórajọ náà

  4. July 11, 2019

    Àwọn aláṣẹ dájú sọ Kirill torí pé òun ló buwọ́ lu ìwé àdéhùn tí wọ́n fi gba yàrá náà; wọ́n tú ilé rẹ̀ yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́

  5. June 4, 2019

    Àwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí nípa àwọn tó kóra jọ nínú yàrá náà àti ohun tí wọ́n ṣe níbẹ̀, àmọ́ wọn ò dárúkọ àwọn tí wọ́n ń wá

  6. April 2019

    Kirill àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì ní Nizhny Novgorod gba yàrá kan kí wọ́n lè kóra jọ, kí wọ́n sì gbádùn ara wọn

Ìsọfúnni Ṣókí

Bá a ṣe ń rí ìgboyà Kirill, ìyàwó ẹ̀ àti tàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ń fojú winá inúnibíni ní Rọ́ṣíà àti Crimea, ó túbọ̀ dá wa lójú pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa fún wa lókun.—Fílípì 1:13, 14.