Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Agbègbèr Oryol

MAY 17, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Dennis Christensen Máa Sọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Láti Gbèjà Ara Rẹ̀ Nílé Ẹjọ́ ní May 23

Dennis Christensen Máa Sọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Láti Gbèjà Ara Rẹ̀ Nílé Ẹjọ́ ní May 23

Ní Thursday, May 16, 2019, ìgbẹ́jọ́ Dennis Christensen tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí ilé ẹjọ ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Àwọn agbẹjọ́rò ìjọba àtàwọn tó ń gbèjà Dennis fẹnu ọ̀rọ̀ wọn jóná lọ́kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gba Dennis láyè pé kóun náà fi nǹkan bíi wákàtí kan gbèjà ara rẹ̀. Àwọn aṣojú láti ilẹ̀ òkèèrè àtàwọn akọ̀ròyìn lóríṣiríṣi wà níbẹ̀, èyí fi hàn pé bó tiẹ̀ ti pọ́dún méjì báyìí tórọ̀ Dennis ti jáde nínú ìròyìn kárí ayé pé wọ́n tì í mọ́lé, àwọn èèyàn káàkiri ayé ṣì fẹ́ mọbi tọ́rọ̀ ẹjọ́ ẹ̀ máa já sí.

Ètò tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ni pé kí wọ́n parí ìgbẹ́jọ́ náà ní Friday, May 17. Àmọ́, àwọn adájọ́ sún ẹjọ́ náà sí aago mẹ́wàá àárọ̀ Thursday, May 23. Wọ́n á fún Dennis láyè láti gbèjà ara rẹ̀ níwájú àwọn adájọ́, lẹ́yìn ìyẹn, àwọn adájọ́ náà á foríkorí kí wọ́n lè ṣèpinnu. A ò tíì lè sọ bóyá May 23 yẹn náà ni ilé ẹjọ́ máa sọ ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí àbí wọ́n máa mú ọjọ́ míì tí wọ́n á sọ ìpinnu tí ilé ẹjọ́ bá ṣe.

Bá a ṣe ń rí àwọn ará bíi Dennis Christensen àti Sergey Skrynnikov, tí wọn ò bọkàn jẹ́, tí wọ́n sì ń fi hàn pé àwọn ò ní yẹhùn, àpẹẹrẹ wọn ń fún wa nígboyà. Ńṣe lohun tá à ń rò nípa àwọn ará wa ní Rọ́síà ṣọ̀kan pẹ̀lú ohun tí àpọ́síltélì Pọ́ọ̀lù sọ nipa àwọn ará Tẹsalóníkà, ó ní: “À ń fi yín yangàn láàárín ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti àwọn ìṣòro tí ẹ̀ ń dojú kọ.”—2 Tẹsalóníkà 1:4.