Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tó dìhámọ́ra pẹ̀lú òòlù onírin ńlá lọ́wọ́ fẹ́ lọ fipá wọ ọ̀kan nínú ilé mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) tí wọ́n fipá ya wọ̀ nílùú Nizhniy Novgorod ní July 2019

AUGUST 7, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Àwọn Ará Tó Ju Ẹgbẹ̀ta (600) Ni Àwọn Ọlọ́pàá Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ti Fipá Ya Wọ̀

Ilé Àwọn Ará Tó Ju Ẹgbẹ̀ta (600) Ni Àwọn Ọlọ́pàá Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ti Fipá Ya Wọ̀

Láàárín oṣù méjìdínlógún (18) tó kọjá, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mẹ́tàlá (613) ilé àwọn arákùnrin wa ni àwọn ọlọ́pàá àti ẹ̀ṣọ́ aláàbò orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ìyẹn Federal Security Service (FSB) ti lọ gbọ̀n yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Nígbà tó fi máa di January 2019, ilé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti méjìlélọ́gbọ̀n (332) ni àwọn aláṣẹ ti lọ tú, èyí sì ju àpapọ̀ ilé tí wọ́n tú ní 2018 lọ, tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún méjì àti mọ́kànlélọ́gọ́rin (281).

Ṣe ni iye ilé àwọn ará wa táwọn agbófinró ń ya wọ̀ láwọn oṣù díẹ̀ sẹ́yìn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, ilé mọ́kànléláàádọ́rin (71) ni wọ́n ya wọ̀ lóṣù June, nígbà tí ti July jẹ́ méjìdínláàádọ́rin (68), èyí sì lọ sókè gan-an ní ìfiwéra pẹ̀lú iye ilé mẹ́tàlélógún àti ẹ̀sún mẹ́rin (23.4) ní ìpíndọ́gba tí wọ́n ya wọ̀ lóṣooṣù lọ́dún 2018.

Àwọn ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń fipá wọ ilé kan ní Nizhniy Novgorod

Lọ́pọ̀ Ìgbà, ṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n dira ogun tí wọ́n sì fi nǹkan bojú máa ya wọ ilé kan ṣoṣo. Bí wọ́n bá ti rọ́nà wọlé, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn máa ń na ìbọn sí àwọn ará wa títí kan àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọmọdé bí i pé ògbólógbòó ọ̀daràn ni wọ́n wá mú. Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n fi gbà pẹ̀lú ohun tí Dókítà Derek H. Davis sọ. Òun ni ọ̀gá tẹ́lẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ J.M. Dawson Institute of Church-State Studies ní Baylor University níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Ẹ̀kọ́ Nípa Àjọṣe Tó Wà Láàárín Ìsìn àti Ìjọba, ó sọ pé: “Inúnibíni tó rorò tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń ṣe sí àwọn èèyàn alálàáfíà bí i ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jẹ́ ká rí i pé ìjọba gan-an ni ‘agbawèrèmẹ́sìn.’”

Ó ṣeni láàánú pé, bí iye ilé tàwọn aláṣẹ ń ya wọ̀ ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni iye ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n ń fi kan àwọn ará wa túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn ará wa tí iye wọn jẹ́ igba ó lé mẹ́rìnlélógójì (244) ni wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti ní ilẹ̀ Crimea báyìí. Èyí sì ju ìlọ́po méjì ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n ní December 2018 lọ, èyí tó jẹ́ àádọ́fà (110) nígbà yẹn. Nínú àwọn igba ó lé mẹ́rìnlélógójì (244) ará wa tó ń jẹ́jọ́, mọ́kàndínlógójì [39] nínú wọn ló wà ní àtìmọ́lé, wọ́n fòfin de àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáde nílé, nígbà tí wọ́n fún àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún kan (100) ni onírúurú ìkálọ́wọ́kò.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣì ń bá a lọ láti máa ṣe inúnibíni sáwọn ará wa, síbẹ̀ ‘àwọn ìpọ́njú yìí ò ní mú ká yẹsẹ̀.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìròyìn tá à ń gbọ́ nípa bí àwọn ará wa ṣe jẹ́ adúróṣinṣin tí wọ́n sì ń lo ìfaradà túbọ̀ ń fún wa níṣìírí. Torí náà, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe ń dáhùn àdúrà tá à ń gbà nítorí àwọn ará wa yìí, ó sì dá wa lójú pé á túbọ̀ máa gbọ́ àdúrà wa.​—1 Tẹsalóníkà 3:​3, 7.