Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Konstantin Bazhenov

OCTOBER 28, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ò Gbà Kí Wọ́n Tú Arákùnrin Bazhenov Sílẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Ò Gbà Kí Wọ́n Tú Arákùnrin Bazhenov Sílẹ̀

Ní October 28, 2020, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Dimitrovgrad tó wà lágbègbè Ulyanovsk ò gbà kí wọ́n tú Arákùnrin Konstantin Bazhenov sílẹ̀, wọn ò sì gbà kí wọ́n fi owó ìtanràn rọ́pò iye ọdún tó kù tó yẹ kó lò lẹ́wọ̀n. Ó láǹfààní láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láàárín ọjọ́ mẹ́wàá.

Lóòótọ́ ẹ̀rù ba Arákùnrin Bazhenov nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ fi sátìmọ́lé ní June 2018. Àmọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó rántí sínú ìwé. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó kọ tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500). Nígbà tó yá, wọ́n fún un ní Bíbélì, ó sì kà á tán láàárín oṣù mẹ́rin. Arákùnrin Bazhenov tún máa ń kọ lẹ́tà sáwọn èèyàn, kó lè fún wọn níṣìírí látinú Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run, léraléra ló sì máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́.

Arákùnrin Bazhenov ti lo ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogójì (340) ọjọ́ látìmọ́lé. Lẹ́yìn tí wọ́n tú u sílẹ̀ ní September 2019, tí wọ́n sì ní kó lọ lo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́wọ̀n, ṣe ló túbọ̀ ń ṣe àwọn nǹkan tá jẹ́ kí àjọṣe òun àti Jèhófà lágbára sí i. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ṣeé ṣe fún Arákùnrin Bazhenov láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, torí náà ó ń láyọ̀ bó ṣe ń fara da inúnibíni. Ẹ jẹ́ ká máa rántí Arákùnrin Bazhenov nínú àdúrà wa.