Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Dennis Christensen lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nígbà tí agbẹjọ́rò ẹ̀ lọ kí i ní September 2020

OCTOBER 26, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ò Tún Gbà Kí Wọ́n Tú Arákùnrin Christensen Sílẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Ò Tún Gbà Kí Wọ́n Tú Arákùnrin Christensen Sílẹ̀

Arákùnrin Dennis Christensen ti lo ohun tó ju ọdún mẹ́ta lọ lẹ́wọ̀n báyìí, àmọ́ ní October 26, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Lgov tún kọ̀ láti tú u sílẹ̀. Àmọ́, ó ṣì láǹfààní láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láàárín ọjọ́ mẹ́wàá. Wọ́n ti ṣírò iye oṣù tó fi wà látìmọ́lé mọ́ iye ọdún tí wọ́n dá fún un, torí náà May 2022 ló yẹ kó kúrò lẹ́wọ̀n. Àmọ́ lóṣù tó kọjá, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n fẹ̀sùn kàn án pé “ọ̀daràn paraku” ni, wọ́n sì sọ pé ó ń ṣe ohun tó lòdì sí òfin ọgbà ẹ̀wọ̀n. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n yọ oṣù tó lò látìmọ́lé kúrò nínú iye ọdún tó máa lò lẹ́wọ̀n, kí wọ́n má sì tú u sílẹ̀ ní May 2022 tó yẹ kó kúrò lẹ́wọ̀n.

Ọ̀pọ̀ nǹkan lojú Arákùnrin Christensen àti Irina ìyàwó ẹ̀ ti rí látìgbà tí wọ́n ti mú un ní May 25, 2017. Síbẹ̀, àwọn méjèèjì ò jẹ́ kíyẹn ba ayọ̀ wọn jẹ́, torí wọ́n ti pinnu pé àwọn máa dúró gbọin láìka ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí. A dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀yin ará kárí ayé fún àdúrà yín lórí wọn.