Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 1, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ ECHR Sáré Fèsì Ìwé Tá A Kọ Lórí Ẹjọ́ Arákùnrin Tí Wọ́n Fìyà Jẹ ní Rọ́ṣíà

Ilé Ẹjọ́ ECHR Sáré Fèsì Ìwé Tá A Kọ Lórí Ẹjọ́ Arákùnrin Tí Wọ́n Fìyà Jẹ ní Rọ́ṣíà

Ní February 25, 2019 a kọ̀wé ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR), pé kí wọ́n tètè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ Arákùnrin Sergey Loginov, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin méje táwọn aláṣẹ fìyà jẹ ní ìlú Surgurt tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Sàìbéríà. Wọ́n ti tú àwọn arákùnrin mẹ́fà tó kù sílẹ̀, àmọ́ Arákùnrin Loginov ṣì wà látìmọ́lé látìgbà tí wọ́n ti mú un, bẹ́ẹ̀, wọn ò tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọn ò sì jẹ́ kó lọ tọ́jú àwọn ọgbẹ́ tó wà lára rẹ̀.

Ní February 26, ìyẹn ọjọ́ kan lẹ́yìn tá a kọ̀wé sí Ilé Ẹjọ́ ECHR, wọ́n fèsì, èsì náà sì dáa gan-an. Ilé Ẹjọ́ fọwọ́ sí ohun tá a béèrè, wọ́n sì pàṣẹ pé “ní kíá” kí ìjọba Rọ́ṣíà jẹ́ kí àwùjọ àwọn dókítà tó ń dá ṣiṣẹ́ ṣàyẹ̀wò Arákùnrin Loginov kí wọ́n lè mọ bí àkóbá tí ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ṣe pọ̀ tó “nínú àgọ́ ara rẹ̀ àti nínú ọpọlọ rẹ̀” àti bóyá ara rẹ̀ ṣì le tó láti wà látìmọ́lé. Títí di March 11, 2019, ìjọba Rọ́ṣíà ò ṣe nǹkan kan.

Ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ni Ilé Ẹjọ́ ECHR máa ń ṣe irú ìdájọ́ kíákíá yìí, ó sì máa ń jẹ́ tí ẹ̀mí ẹni tọ́rọ̀ kàn bá wà nínú ewu, tí nǹkan sì lè bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Ó dùn mọ́ni nínú pé Ilé Ẹjọ́ ECHR tètè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ yìí láàárín ọjọ́ kan péré tá a kọ̀wé sí wọn. Ilé Ẹjọ́ ECHR sì sọ pé wọ́n máa rí i dájú pé àwọn fojú sí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn ará wa.

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Ẹlẹ́rìí mọ́kàndínlógún (19) ló ń jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn wọ́n ní ìlú Surgut, mẹ́ta lára wọn sì ti wà látìmọ́lé láì tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn.

Bá a ṣe ń bá àwọn ará wa bẹ Jèhófà, ẹ jẹ́ ká máa fi ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú tí Jeremáyà sọ sọ́kàn pé: “Ìbùkún ni fún ọkùnrin tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”​—Jeremáyà 17:7.