Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Sergey Rayman àti ìyàwó rẹ̀ Valeriya

SEPTEMBER 7, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Fẹ́ Dájọ́ fún Àwọn Tọkọtaya Kan Tí Wọ́n Jẹ́ Ọ̀dọ́ ní Rọ́ṣíà

Ilé Ẹjọ́ Fẹ́ Dájọ́ fún Àwọn Tọkọtaya Kan Tí Wọ́n Jẹ́ Ọ̀dọ́ ní Rọ́ṣíà

Ọjọ́ Tí Wọ́n Máa Ṣèdájọ́ Náà

September 16, 2020 * ni Ilé ẹjọ́ Sverdlovskiy District Court ti ìlú Kostroma máa pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe fún Arákùnrin Sergey Rayman àti ìyàwó rẹ̀ Valeriya. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n ọdún méje, wọn ò ní wà nínú ẹ̀wọ̀n àmọ́ ṣe ni wọ́n á máa ṣọ́ wọn lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀.

Ìsọfúnni Nípa Wọn

Sergey Rayman

  • Wọ́n Bíi Ní: 1996 (ìlú Kineshma, lágbègbè Ivanovo)

  • Ìsọfúnni Ṣókí: Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé ní iléèwé ẹ̀kọ́ṣẹ́. Ó di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àwọn tó máa ń dárà sínú ilé. Ìyá rẹ̀ àgbà ló fi Bíbélì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì nífẹ̀ẹ́ ohun tó kọ́. Ọdún 2015 ló fẹ́ Valeriya ìyàwó rẹ̀. Ó fẹ́ràn àtimáa se oúnjẹ kó sì máa ṣeré lórí yìnyín

Valeriya Rayman

  • Wọ́n Bíi Ní: 1993 (ìlú Sharya, lágbègbè Kostroma)

  • Ìsọfúnni Ṣókí: Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni nígbà tí bàbá rẹ̀ kú. Ìyá rẹ̀ ló kọ́ ọ nípa Jèhófà. Irun ló máa ń ṣe fáwọn èèyàn, ìjọba sì fún un ní ìwé àṣẹ fún iṣẹ́ náà

Bí Ọ̀rọ̀ Ẹjọ́ Wọn Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Láàárọ̀ July 25, 2018, àwọn ọlọ́pàá gbé ìbọn wá ká wọn mọ́lé, wọ́n fi irin já ilẹ̀kùn ilé Arákùnrin àti Arábìnrin Rayman. Wọ́n mú àwọn méjèèjì, wọ́n fi Arábìnrin Rayman sí àtìmọ́lé fún ọjọ́ méjì. Arákùnrin Rayman ní tiẹ̀ lo ọjọ́ mọ́kàndínlọ́gọ́ta [59] ní àhámọ́. Ìjọba ò jẹ́ kó rọrùn fáwọn ará láti bá arákùnrin àti arábìnrin Rayman sọ̀rọ̀. Bákan náà, wọn ò gbà wọ́n láyè láti kúrò nílé wọn lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Àwọn wàhálà yìí ti ń nípa lórí ìlera àwọn tọkọtaya yìí gan-an.

Bí àwọn tọkọtaya yìí ṣe ń dúró de ìdájọ́ ilé ẹjọ́, àdúrà wa ni pé kí wọ́n jẹ́ onígboyà àti alágbára, kí wọ́n ma sì yéé gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà torí pé kò ní fi wọ́n sílẹ̀ láé.—Jóṣúà 1:9.

^ ìpínrọ̀ 3 A lè yí i pa dà tó bá yá