NOVEMBER 17, 2020
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Táwọn Ará Wa Mẹ́ta Pè ní Rọ́ṣíà
Ní November 17, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Kamchatka fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn ará wa yìí pè, ìyẹn Arákùnrin Konstantin Bazhenov, Snezhana ìyàwó ẹ̀ àti Arábìnrin Vera Zolotova. Ọdún méjì tílé ẹjọ́ kọ́kọ́ ní kí wọ́n lò nílé ni wọ́n ṣì máa lò. Wọn ò ní lọ sẹ́wọ̀n, torí náà inú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń dùn, wọ́n sì pinnu pé àwọn á máa bá a lọ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.
Lẹ́yìn ìdájọ́ tí wọ́n ṣe ní September 25, 2020, Arákùnrin Bazhenov fìgboyà sọ fún adájọ́ pé ìdájọ́ tó ṣe ò ba òun lẹ́rù. Ó tún sọ pé inú òun dùn pé Jòhánù 15:20 ṣẹ mọ́ òun lára, níbi tí Jésù ti sọ pé àwọn èèyàn máa ṣenúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun.
Arákùnrin Bazhenov tún sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nínú Mátíù 28:19, 20, pé kí wọ́n máa wàásù. Arákùnrin Bazhenov wá béèrè ìbéèrè kan tó lágbára: Ó ní: “Ta ló tó bẹ́ẹ̀ láti fagi lé àṣẹ tí Kristi pa?” Ó wá sọ pé: “Mi ò ní dákẹ́. . . . Màá máa bá a lọ láti sọ ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì.”