SEPTEMBER 28, 2021
RỌ́ṢÍÀ
Ilé Ẹjọ́ Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Táwọn Ará Wa Pè Lòdì Sí Bí Wọ́n Ṣe Fòfin De JW Library ní Rọ́ṣíà
Ní September 27, 2021, ilé ẹjọ́ ìlú Saint Petersburg fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn táwọn ará wa pè lòdì sí bí wọ́n ṣe fòfin de JW Library ní Rọ́ṣíà àti Crimea. Níbi ìdájọ́ tó kọ́kọ́ wáyé ní March 31, 2021, wọ́n kéde pé irin iṣẹ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn ni JW Library, wọ́n sì sọ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ lò ó mọ́ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti Crimea. Ní báyìí, àwọn agbófinró ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé ohun tílé ẹjọ́ sọ nínú ìdájọ́ àkọ́kọ́ yẹn.