Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Sergey Klimov wà nínú àhámọ́ kótópó nílé ẹjọ́ ní May 2019

NOVEMBER 11, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Dá Ẹ̀wọ̀n Ọdún Mẹ́fà fún Arákùnrin Klimov, Ìdájọ́ Tó Burú Jù Lọ Láti Ọdún 2017

Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Dá Ẹ̀wọ̀n Ọdún Mẹ́fà fún Arákùnrin Klimov, Ìdájọ́ Tó Burú Jù Lọ Láti Ọdún 2017

Ní November 5, 2019, ilé ẹjọ́ àgbègbè Oktyabrsky nílùú Tomsk ju Arákùnrin Sergy Klimov sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà. Dennis Christensen ni arákùnrin tí wọ́n kọ́kọ́ dá ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ bẹ́ẹ̀ fún. Àmọ́, ọ̀rọ̀ arákùnrin Klimov tún wá burú sí i torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni ilé ẹjọ́ ká a lọ́wọ́ kò pé kò ní lè ṣe, èyí ló mú kí ìdájọ́ tiẹ̀ jẹ́ èyí tó le jù lọ tó tíì wáyé látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti fòfin de iṣẹ́ wa lọ́dún 2017.

Wọ́n mú arákùnrin Klimov ní June 3, 2018, nígbà táwọn agbófinró àtàwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ya wọ ilé àwọn Elẹ́rìí Jèhófà méjì. Nǹkan bí ọgbọ̀n (30) àwọn ará wa ni wọ́n mú kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Kódà wọ́n mú arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83). Wọ́n dá àwọn tó kù sílẹ̀, àfi arákùnrin Klimov. Wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn án, ilé ẹjọ́ sì pàṣẹ pé kó ṣì wà látìmọ́lé fún oṣú méjì kí wọ́n tó dá ẹjọ́ rẹ̀. Ẹ̀ẹ̀méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sún ẹjọ́ rẹ̀ síwájú, tó túmọ̀ sí pé kó tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà tí wọ́n dá fún un, ó ti lo ọdún kan àti oṣù márùn-ún ní àtìmọ́lé láìfojú kan ìyàwó àti ìdílé rẹ̀.

Àwọn agbẹjọ́rò tó ń ṣojú fún arákùnrin Klimov máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, ní August 20, 2018, wọ́n gbé ẹjọ́ nípa Klimov àti ilẹ̀ Rọ́ṣíà lọ síwájú Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù lórí bí wọ́n ṣe ń sún àsìkò tí wọ́n fẹ́ fi gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ síwájú.

Jálẹ̀ ọdún 2019, iye ilé àwọn ará wa táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà lọ fọ́ túbọ̀ pọ̀ sí i, tó fi mọ́ iye àwọn tí wọ́n mú àtàwọn tí wọ́n ń fi sí àtìmọ́lé. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ àwọn ará wa ò mì rárá. A ń rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ń bù kún àwọn ará wa bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé e, ìyẹn sì túbọ̀ ń fún wa níṣìírí.—Sáàmù 56:1-5, 9.