Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 22, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ní Kí Arákùnrin Semyon Baybak Lọ Lo Àkókò Tó Yẹ Kó Lò Lẹ́wọ̀n Nílé

Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Ní Kí Arákùnrin Semyon Baybak Lọ Lo Àkókò Tó Yẹ Kó Lò Lẹ́wọ̀n Nílé

Ní December 21, 2020, Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Leninskiy ní Rostov-on-Don sọ pé Arákùnrin Semyon Baybak jẹ̀bi, wọ́n sì ní kó lọ lo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ nílé. Kò ní lọ sẹ́wọ̀n àmọ́ àwọn agbófinró á máa ṣọ́ ọ.

Nígbà tí Semyon ń sọ̀rọ̀ ní ilé ẹjọ́ náà, ní ọjọ́ mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, ó fa ọ̀rọ̀ gbajúgbajà kan tó máa ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nílẹ̀ Rọ́ṣíà yọ pé: “Wọ́n ní wọ́n ń ṣe inúnibíni sáwọn [Ẹlẹ́rìí Jèhófà], àmọ́ ẹ̀rín múṣẹ́ kì í wọ́n lẹ́nu wọn.” Semyon tún sọ pé: “Mi ò rẹ̀wẹ̀sì, kò sì ṣe mí bíi pé wọ́n kórìíra mi.” Ó wá ka 2 Kọ́ríńtì 4:​8, 9, pé ó ń ṣẹ sí òun lára, àtàwọn Ẹlẹ́rìí yòókù ní Rọ́ṣíà, ó ní: “Wọ́n há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, àmọ́ kò le débi tí a ò fi lè yíra; ọkàn wa dà rú, àmọ́ kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbáyọ rárá; wọ́n ṣe inúnibíni sí wa, àmọ́ a ò pa wá tì; wọ́n gbé wa ṣánlẹ̀, àmọ́ a ò pa run.”