Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 31, 2021
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Russia Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mẹ́rin Pè

Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Russia Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mẹ́rin Pè

Ní May 28, 2021, Ilé Ẹjọ́ Ìpínlẹ̀ Omsk fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Arákùnrin Sergey Polyakov àti ìyàwó rẹ̀, Anastasia pè àti tàwọn Arábìnrin Gaukhar Bektemirova àti Dinara Dyusekeyeva. Arákùnrin Polyakov á ṣì wà lẹ́wọ̀n, ẹjọ́ tí wọ́n dá fáwọn arabìnrin mẹ́ta yìí pé kí wọ́n lọ lo àkókò tó yẹ kí wọ́n lò lẹ́wọ̀n nílé ṣì máa wà bẹ́ẹ̀.