Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 25, 2020
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Fagi Lé Ìdájọ́ Tí Ilé Ẹjọ́ Kan Ṣe Lòdì sì Arákùnrin Alushkin Àtàwọn Márùn-ún Míì. Ìgbà Àkọ́kọ́ Rèé Tírú Ẹ̀ Máa Ṣẹlẹ̀ Ní Rọ́ṣíà

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Fagi Lé Ìdájọ́ Tí Ilé Ẹjọ́ Kan Ṣe Lòdì sì Arákùnrin Alushkin Àtàwọn Márùn-ún Míì. Ìgbà Àkọ́kọ́ Rèé Tírú Ẹ̀ Máa Ṣẹlẹ̀ Ní Rọ́ṣíà

Ní March 25, 2020, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó wà nílùú Penza fagi lé ìpinnu tí ilé ẹjọ́ kan ṣe níbi ìgbẹ́jọ́ Arákùnrin Vladimir Alushkin, Vladimir Kulyasov, Andrey Magliv àti Arákùnrin Denis Timoshin pa pọ̀ pẹ̀lú Arábìnrin Tatyana Alushkina àti Galiya Olkhova. Torí náà, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn dá ẹjọ́ náà pa dà sí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ pé kí wọ́n tún ẹjọ́ náà gbọ́.

Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, ó ṣe kedere pé lọ́jọ́ mélòó kan sí i, wọ́n máa dá Arákùnrin Alushkin sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Àmọ́ títí dìgbà tí wọ́n máa tún ẹjọ́ náà gbọ́, òun àtàwọn yòókù rẹ̀ kò ní lè rìnrìn-àjò, wọ́n sì tún máa fi àwọn ẹ̀tọ́ kan dù wọ́n.