Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

May 23, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Fara Mọ́ Ọn Pé Kí Dennis Christensen Lọ Sẹ́wọ̀n

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Fara Mọ́ Ọn Pé Kí Dennis Christensen Lọ Sẹ́wọ̀n

Ní May 23, 2019, àwọn adájọ́ mẹ́ta ní Ilé Ẹjọ́ Agbègbè Oryol dá Dennis Christensen lẹ́bi nínú ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó pè torí bí ilé ẹjọ́ kan ṣe rán an lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà. Nǹkan bí ọgọ́rin (80) àwọn ará ló wá síbi ìgbẹ́jọ́ náà. Àwọn aṣojú láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà àti Denmark náà wà níbẹ̀. Àwọn ilé iṣé tó ń gbéròyìn jáde kárí ayé sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí.

Oṣù February ni ilé ẹjọ́ rán Arákùnrin Christensen lẹ́wọ̀n. Lááàrín oṣù mẹ́ta tó kọjá yìí, ìgbà márùndínlọ́gọ́fà (115) làwọn aláṣẹ ya wọ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kódà iye ìgbà tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn wọ́n ti fi ìlọ́po mẹ́ta pọ̀ sí i tá a bá fi wé ti oṣù mẹ́ta tó ṣáájú.

À ń rántí Arákùnrin Christensen àtàwọn ará wa ní Rọ́ṣíà nínú àdúrà. Ó dá wa lójú pé Jèhófà “wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é,” kò sì ní yéé ran àwọn ará wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè dúró láìyẹhùn lójú inúnibíní—Sáàmù 145:18.