Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Andrey àti ìyàwó rẹ̀, Svetlana, níwájú ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ sọ pé kí wọ́n jẹ́ kó lómìnira láti jáde kúrò nílé

AUGUST 22, 2019
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Pàṣẹ Pé Kí Wọn Jẹ́ Kí Arákùnrin Andrey Suvorkov Lómìnira Láti Jáde Kúrò Nílé

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Pàṣẹ Pé Kí Wọn Jẹ́ Kí Arákùnrin Andrey Suvorkov Lómìnira Láti Jáde Kúrò Nílé

Tẹ́lẹ̀, ṣe láwọn aláṣẹ sọ fún Arákùnrin Andrey Suvorkov tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) pé kò gbọdọ̀ jáde nílé. Àmọ́ ní August 13, 2019, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó wà ní ìlú Kirov dájọ́ pé kí wọn jẹ́ kó lómìnira láti jáde kúrò nílé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fún Arákùnrin Suvorkov lómìnira tó pọ̀ si i, síbẹ̀ ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn án ṣì wà síbẹ̀.

Bó ṣe wà nínú ìròyìn tá a gbé jáde ṣáájú, ní October 9, 2018 àwọn ọlọ́pàá àtàwọn agbófinró tó fi nǹkan bojú ya wọ ilé mọ́kàndínlógún (19) lára ilé àwọn ará wa. Ìgbà yẹn ni wọ́n mú Arákùnrin Suvorkov, ọkọ ìyá rẹ̀ àtàwọn arákùnrin mẹ́ta míì.

Arákùnrin Suvorkov sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n wá tú ilé rẹ̀, ó ní: “Wọ́n kó púpọ̀ nínú àwọn ohun ìní wa. Àmọ́, èmi àti ìyàwó mi ò ronú nípa ìyẹn torí a ti jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, a ò sì kì í ṣàníyàn púpọ̀ nípa àwọn nǹkan tara. Ìmọ̀ràn tó wà ní Mátíù 6:21 ti ràn wá lọ́wọ́ gan-an, ó sọ pé, ‘ibi tí ìṣúra yín bá wà ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà,’ ìyẹn ni kò jẹ́ ká kọ́kàn sókè.”

Lẹ́yìn tí wọ́n tú ilé àwọn arákùnrin yìí, wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Arákùnrin Suvorkov, ọkọ ìyá rẹ̀ àtàwọn arákùnrin mẹ́ta míì. Wọ́n ní torí pé wọ́n ń kọrin ìjọba Ọlọ́run, wọ́n ń ka àwọn ìtẹ̀jáde wa àti pé wọ́n tún ní Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Rọ́ṣíà lọ́wọ́. Wọ́n fi gbogbo wọ́n sí àtìmọ́lé tó wà fún gbà díẹ̀ títí ilé ẹjọ́ á fi sọ pé kí wọn dá wọ́n sílẹ̀ tàbí kí wọ́n wà lẹ́wọ̀n títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ wọn.

Arákùnrin Suvorkov sọ ohun tójú ẹ̀ rí, ó sọ pé: “Ọjọ́ méjì ni mo lò ní àtìmọ́lé onígbà díẹ̀. Mi ò dáwọ́ àdúrà dúró láti ìbẹ̀rẹ̀, torí ó dá mi lójú pé Jèhófà á gbọ́ mi, á sì tì mí lẹ́yìn. Mò rántí àwọn orin ìjọba Ọlọ́run kan, mo sì ń kọ wọ́n. Lápapọ̀, mo rántí ohùn orin tó lé ní àádọ́ta (50) àti ọ̀rọ̀ inú wọn.”

Ilé ẹjọ́ wá sọ pé kí wọ́n fi Arákùnrin Suvorkov àti àwọn yòókù sẹ́wọ̀n títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí Arákùnrin Suvorkov lò lẹ́wọ̀n, ṣé ló gbájú mọ́ bó ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Ó sọ́ pé: “Mo pinnu láti máa dárúkọ àwọn ará wa nínú àdúrà mi, mo sì ń kọ lẹ́tà tó ń fúnni lókùn sí àwọn tí mo rántí àdírẹ́sì ilé wọn. Èyí fún mi láyọ̀ gan-an.”​—Ìṣe 20:35.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, wọ́n dá àwọn arákùnrin yìí padà sílé wọ́n, àmọ́ wọ́n pàṣẹ pé gbogbo wọn ò gbọdọ̀ jáde kúrò nílé, àfi Arákùnrin Andrey Oniszczuk nìkan ló lè jáde nílé. Arákùnrin Suvorkov ni ẹni àkọ́kọ́ nílùú Kirov lára àwọn tí wọ́n ní wọn ò gbọdọ̀ jáde nílé tí wọ́n wá pa dà fún lómìnira láti jáde nílé.

Nígbà tí Arákùnrin Suvorkov rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó sọ pé: “Inú mi dùn pé mo ní irú ìrírí tí mo ní lẹ́wọ̀n. . . . Mi ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́la, mi ò sì mọ̀ bóyá wọ́n ṣì tún máa sọ mí sẹ́wọ̀n. Àmọ́ ní báyìí, ó ti wá dá mi lójú pé Jèhófà àti ètò rẹ̀ ò ní fi mí sílẹ̀, kódà tí mo bá wà lẹ́wọ̀n. Ohun kan ni pé, àyà mi ò já pé wọ́n lè sọ mí sẹ́wọ̀n.”